Maku 9 BM

1 Ó tún wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, àwọn kan wà ninu àwọn tí ó dúró níhìn-ín tí wọn kò ní kú títí wọn óo fi rí ìjọba Ọlọrun tí yóo dé pẹlu agbára.”

Jesu Para Dà lórí Òkè

2 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu lọ sí orí òkè gíga kan, àwọn mẹta yìí nìkan ni ó mú lọ. Ìrísí rẹ̀ bá yipada lójú wọn.

3 Ẹ̀wù rẹ̀ ń dán, ó funfun láúláú, kò sí alágbàfọ̀ kan ní ayé tí ó lè fọ aṣọ kí ó funfun tóbẹ́ẹ̀.

4 Wọ́n rí Elija pẹlu Mose tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀.

5 Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, ó dára tí a wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pàgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.”

6 Ẹ̀rù tí ó bà wọ́n pupọ kò jẹ́ kí ó mọ ohun tí ì bá wí.

7 Ìkùukùu kan bá ṣíji bò wọ́n, ohùn kan bá wá láti inú ìkùukùu náà tí ó wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”

8 Lójijì, bí wọ́n ti wò yíká, wọn kò rí ẹnìkankan lọ́dọ̀ wọn mọ́, àfi Jesu nìkan.

9 Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, Jesu pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ròyìn ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí òun, Ọmọ-Eniyan, yóo fi jí dìde kúrò ninu òkú.

10 Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, wọ́n ń bá ara wọn jiyàn nípa ìtumọ̀ jíjí dìde kúrò ninu òkú.

11 Wọ́n bá bi í léèrè pé, “Kí ló dé tí àwọn amòfin fi sọ pé Elija ni ó níláti kọ́ dé?”

12 Ó dá wọn lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Elija ni ó níláti kọ́ dé láti mú ohun gbogbo bọ̀ sípò.” Ó wá bi wọ́n pé, “Báwo ni a ti ṣe kọ nípa Ọmọ-Eniyan pé ó níláti jìyà pupọ, kí a sì fi àbùkù kàn án?”

13 Ó sì tún wí fún wọn pé, “Elija ti dé, wọ́n ti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ nípa rẹ̀.”

Jesu Wo Ọmọ Tí Ó Ní Ẹ̀mí Èṣù Sàn

14 Nígbà tí Jesu dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí ọpọlọpọ eniyan pẹlu àwọn amòfin, wọ́n ti ń bá ara wọn jiyàn.

15 Lẹsẹkẹsẹ bí gbogbo àwọn eniyan ti rí i, ẹnu yà wọ́n, wọ́n bá sáré lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i.

16 Ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀yin ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ń jiyàn lé lórí?”

17 Ẹnìkan ninu wọn bá dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, ọmọ mi tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di odi ni mo mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ.

18 Níbikíbi tí ó bá ti dé sí i, ẹ̀mí èṣù yìí á gbé e ṣánlẹ̀, ọmọ náà yóo máa yọ ìfòòfó lẹ́nu, yóo wa eyín pọ̀, ara rẹ̀ yóo wá le gbandi. Mo sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pé kí wọn lé ẹ̀mí náà jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.”

19 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó? N óo ti fara dà á fun yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá.”

20 Wọ́n bá mú un lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.Nígbà tí ẹ̀mí burúkú yìí rí Jesu, ó mú kí gìrì ki ọmọ náà ní akọ, ó gbé e ṣánlẹ̀, ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yí nílẹ̀, ó ń yọ ìfòòfó lẹ́nu.

21 Jesu wá bi baba ọmọ náà pé, “Ó ti tó ìgbà wo tí irú èyí ti ń ṣe é?”Baba rẹ̀ dáhùn pé, “Láti kékeré ni.”

22 Ó ní, “Nígbà pupọ ẹ̀mí náà á gbé e sọ sinu iná tabi sinu omi, kí ó lè pa á. Ṣugbọn bí ìwọ bá lè ṣe ohunkohun, ṣàánú wa kí o ràn wá lọ́wọ́.”

23 Jesu wí fún un pé, “Ọ̀ràn bí èmi bá lè ṣe é kọ́ yìí, ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.”

24 Lẹ́sẹ̀ kan náà baba ọmọ náà kígbe pé, “Mo gbàgbọ́; ràn mí lọ́wọ́ níbi tí igbagbọ mi kù kí ó tó.”

25 Nígbà tí Jesu rí i pé àwọn ìjọ eniyan ń sáré bọ̀, ó bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó ní, “Ìwọ ẹ̀mí tí o jẹ́ kí ọmọ yìí ya odi, tí o sì di í létí, mo pàṣẹ fún ọ, jáde kúrò ninu rẹ̀, kí o má tún wọ inú rẹ̀ mọ́.”

26 Ẹ̀mí náà bá kígbe, ó mú kí gìrì ki ọmọ náà ní akọ, ó sì jáde. Ọmọ náà wá dàbí ẹni tí ó kú, tóbẹ́ẹ̀ tí ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan náà ń sọ pé ó ti kú.

27 Ṣugbọn Jesu fà á lọ́wọ́, ó gbé e dìde, ọmọ náà bá nàró.

28 Nígbà tí Jesu wọ inú ilé, tí ó ku òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n ń bi í pé, “Kí ló dé tí àwa kò fi lè lé ẹ̀mí náà jáde?”

29 Ó dá wọn lóhùn pé, “Irú èyí kò ṣe é lé jáde, àfi pẹlu adura [ati ààwẹ̀.”]

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀

30 Láti ibẹ̀ wọ́n jáde lọ, wọ́n ń la Galili kọjá. Jesu kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀,

31 nítorí ó ń kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń wí fún wọn pé, “A óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́, wọn yóo pa á, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá ti pa á tán, yóo jí dìde lẹ́yìn ọjọ́ mẹta.”

32 Ṣugbọn ohun tí ó ń wí kò yé wọn, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

Ta Ni Ẹni Ńlá Jùlọ?

33 Nígbà tí wọ́n dé Kapanaumu, tí wọ́n wọ inú ilé, ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀ ń bá ara yín sọ lọ́nà?”

34 Wọ́n bá dákẹ́ nítorí ní ọ̀nà, wọ́n ti ń bá ara wọn jiyàn lórí ta ni ó ṣe pataki jùlọ.

35 Lẹ́yìn tí ó ti jókòó, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ọ̀gá, ó níláti ṣe iranṣẹ fún gbogbo eniyan.”

36 Ó bá fa ọmọde kan dìde ní ààrin wọn, ó gbé e sí ọwọ́ rẹ̀, ó wí fún wọn pé,

37 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀kan ninu àwọn ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, kì í ṣe èmi ni ó gbà, ṣugbọn ó gba ẹni tí ó rán mi wá sí ayé.”

Ẹni Tí Kò Lòdì sí Wa, Tiwa ni

38 Johanu wí fún un pé, “Olùkọ́ni, a rí ẹnìkan tí ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ṣugbọn a gbìyànjú láti dá a lẹ́kun, nítorí kì í ṣe ara wa.”

39 Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Ẹ má ṣe dá a lẹ́kun, nítorí kò sí ẹni tí yóo fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóo yára sọ ọ̀rọ̀ ibi nípa mi.

40 Nítorí ẹni tí kò bá lòdì sí wa, tiwa ni.

41 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fun yín ní omi mu nítorí tèmi, nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kristi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo rí èrè rẹ̀ gbà.

Ẹ̀tàn Sí Ẹ̀ṣẹ̀

42 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́ kọsẹ̀, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á gbé e sọ sinu òkun.

43 Bí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àléébù ara, jù pé kí o ní ọwọ́ mejeeji kí o wọ iná àjóòkú, [

44 níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.]

45 Bí ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ kan kí o sì wọ inú ìyè jù pé kí o ní ẹsẹ̀ mejeeji kí á sì sọ ọ́ sinu iná, [

46 níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.]

47 Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ ìjọba Ọlọrun pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú mejeeji kí a sì sọ ọ́ sinu iná,

48 níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.

49 “Iyọ̀ níí sọ ẹbọ di mímọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó jẹ́ pé iná ni a óo fi sọ gbogbo eniyan di mímọ́.

50 “Iyọ̀ dára, ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, báwo ni yóo ṣe tún lè dùn mọ́?“Ẹ ní iyọ̀ ninu ara yín, nígbà náà ni alaafia yóo wà láàrin yín.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16