Maku 3 BM

Ọkunrin Tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ

1 Jesu tún wọ inú ilé ìpàdé lọ. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ.

2 Àwọn kan wà tí wọn ń ṣọ́ ọ bí yóo wo ọkunrin yìí sàn ní Ọjọ́ Ìsinmi, kí wọn lè fi í sùn.

3 Ó wí fún ọkunrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde dúró ní ààrin àwùjọ.”

4 Jesu bá bi wọ́n léèrè pé, “Èwo ni ó dára: láti ṣe ìrànlọ́wọ́ ni tabi láti ṣe ìbàjẹ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là ni tabi láti pa ẹ̀mí run?”Ṣugbọn wọn kò fọhùn.

5 Jesu wò yíká pẹlu ibinu, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí pé ọkàn wọn le. Ó wá wí fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ sì bọ́ sípò.

6 Lẹsẹkẹsẹ àwọn Farisi jáde lọ láti gbìmọ̀ pọ̀ pẹlu àwọn alátìlẹ́yìn Hẹrọdu lórí ọ̀nà tí wọn yóo gbà pa á.

Ọpọlọpọ Eniyan Lẹ́bàá Òkun

7 Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra lọ sí ẹ̀bá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan sì ń tẹ̀lé e. Wọ́n wá láti Galili ati Judia ati Jerusalẹmu;

8 láti Idumea ati apá ìlà oòrùn odò Jọdani ati agbègbè Tire ati ti Sidoni. Ogunlọ́gọ̀ eniyan wọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó ń ṣe.

9 Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn tọ́jú ọkọ̀ ojú omi kan sí ìtòsí nítorí àwọn eniyan, kí wọn má baà fún un pa.

10 Nítorí ó wo ọpọlọpọ sàn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn aláìsàn ń ti ara wọn, kí wọ́n lè fi ọwọ́ kàn án.

11 Nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù bá rí i, wọ́n a wolẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n a máa kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.”

12 Kíkìlọ̀ ni ó máa ń kìlọ̀ fún wọn gan-an kí wọn má ṣe fi òun hàn.

Jesu Yan Ọmọ-ẹ̀yìn Mejila

13 Lẹ́yìn náà, ó wá gun orí òkè lọ, ó pe àwọn tí ó wù ú sọ́dọ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ.

14 Ó bá yan àwọn mejila, ó pè wọ́n ní aposteli, kí wọn lè wà pẹlu rẹ̀, kí ó lè máa rán wọn lọ waasu,

15 kí wọn lè ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.

16 Àwọn mejila tí ó yàn náà nìyí: Simoni, tí ó sọ ní Peteru,

17 ati Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu àbúrò rẹ̀, ó sọ wọ́n ní Boanage, ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Àwọn ọmọ ààrá”;

18 ati Anderu, Filipi, Batolomiu, Matiu, ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, Tadiu, ati Simoni, ọmọ ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ Kenaani,

19 ati Judasi Iskariotu ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Jesu ati Beelisebulu

20 Lẹ́yìn náà, Jesu wọ inú ilé lọ, àwọn eniyan tún pé jọ tóbẹ́ẹ̀ tí òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò fi lè jẹun.

21 Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́, wọ́n jáde lọ láti fi agbára mú un nítorí àwọn eniyan ń wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.”

22 Ṣugbọn àwọn amòfin tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu sọ pé, “Ó ní ẹ̀mí Beelisebulu; ati pé nípa agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

23 Jesu wá pè wọ́n sọ́dọ̀, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Báwo ni Satani ti ṣe lè lé Satani jáde?

24 Bí ìjọba kan náà bá gbé ogun ti ara rẹ̀, ìjọba náà yóo parun.

25 Bí àwọn ará ilé kan náà bá ń bá ara wọn jà, ilé náà kò lè fi ìdí múlẹ̀.

26 Bí Satani bá gbógun ti ara rẹ̀, tí ó ń bá ara rẹ̀ jà, kò lè fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, a jẹ́ pé ó parí fún un.

27 “Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó lè wọ ilé alágbára kan lọ, kí ó kó dúkìá rẹ̀ láìjẹ́ pé ó kọ́ de alágbára náà mọ́lẹ̀, nígbà náà ni yóo tó lè kó ilé rẹ̀.

28 “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a óo dárí ji àwọn ọmọ eniyan, ati gbogbo ìsọkúsọ tí wọ́n lè máa sọ.

29 Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò lè ní ìdáríjì laelae, ṣugbọn ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ títí lae.”

30 (Jesu sọ èyí nítorí wọ́n ń wí pé ó ní ẹ̀mí Èṣù.)

Àwọn Ta ni Ẹbí Jesu?

31 Nígbà tí ó yá ìyá rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀ wá, wọ́n dúró lóde, wọ́n bá ranṣẹ pè é.

32 Àwọn eniyan jókòó yí i ká, wọ́n bá sọ fún un pé, “Gbọ́ ná, ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ ń bèèrè rẹ lóde.”

33 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi ati arakunrin mi?”

34 Nígbà tí ó wo gbogbo àwọn tí ó jókòó yí i ká lọ́tùn-ún lósì, ó ní, “Ẹ̀yin ni ìyá mi ati arakunrin mi.

35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun, òun ni arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati ìyá mi.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16