Maku 10 BM

Ẹ̀kọ́ Nípa Ipò Ọkọ ati Aya sí Ara Wọn

1 Nígbà tí Jesu dìde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Judia, ó rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Ọpọlọpọ àwọn eniyan tún lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó tún ń kọ́ wọn.

2 Àwọn Farisi bá jáde wá, wọ́n ń bi í bí ó bá tọ́ kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀. Wọ́n fi ìbéèrè yìí dán an wò ni.

3 Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ni Mose pa láṣẹ fun yín?”

4 Wọ́n dáhùn pé, “Mose yọ̀ǹda pé kí ọkọ kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún iyawo rẹ̀, kí ó sì kọ̀ ọ́.”

5 Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Nítorí oríkunkun yín ni Mose fi kọ òfin yìí.

6 Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, takọ-tabo ni Ọlọrun dá wọn.

7 Nítorí èyí ni ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóo wá fi ara mọ́ iyawo rẹ̀;

8 àwọn mejeeji yóo wá di ọ̀kan. Wọn kì í tún ṣe ẹni meji mọ́ bíkòṣe ọ̀kan.

9 Nítorí náà ohun tí Ọlọrun bá ti so pọ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà á.”

10 Nígbà tí wọ́n pada wọ inú ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í nípa ọ̀rọ̀ náà.

11 Ó bá wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀, tí ó gbé ẹlòmíràn ní iyawo, ó ṣe àgbèrè sí iyawo rẹ̀ àkọ́kọ́.

12 Bí ó bá sì jẹ́ pé obinrin ni ó kọ ọkọ rẹ̀, tí ó fẹ́ ọkọ mìíràn, òun náà ṣe àgbèrè.”

Jesu Bukun Àwọn Ọmọde

13 Àwọn kan gbé àwọn ọmọ kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí.

14 Nígbà tí Jesu rí i inú bí i: ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí ti irú wọn ni ìjọba Ọlọrun.

15 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ọmọde, kò ní wọ ìjọba ọ̀run.”

16 Nígbà náà ni Jesu gbé àwọn ọmọde náà lọ́wọ́, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì súre fún wọn.

Ọkunrin Ọlọrọ̀ kan

17 Nígbà tí Jesu jáde, bí ó ti ń lọ lọ́nà, ọkunrin kan sáré tọ̀ ọ́ lọ, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bi í pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”

18 Ṣugbọn Jesu wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan, àfi Ọlọrun nìkan.

19 Ṣé o mọ àwọn òfin: má paniyan, má ṣe àgbèrè, má jalè, má jẹ́rìí èké, má rẹ́nijẹ, bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ?”

20 Ọkunrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin ni mo ti ń pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́.”

21 Jesu wá tẹjú mọ́ ọn, ó fi tìfẹ́tìfẹ́ wò ó, ó wí fún un pé, “Nǹkankan ló kù kí o ṣe: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn aláìní, o óo wá ní ọrọ̀ ní ọ̀run; lẹ́yìn náà wá, kí o máa tẹ̀lé mi.”

22 Ṣugbọn ojú ọkunrin náà fàro nígbà tí ó gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó bá jáde lọ pẹlu ìbànújẹ́, nítorí pé ọrọ̀ tí ó ní pọ̀.

23 Jesu bá wo ọ̀tún, ó wo òsì, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Yóo ṣòro pupọ fún àwọn ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun!”

24 Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nítorí gbolohun yìí. Ṣugbọn Jesu tún wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọde, yóo ṣòro pupọ láti wọ ìjọba Ọlọrun!

25 Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun!”

26 Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pupọ. Wọ́n ń bá ara wọn sọ pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni yóo là?”

27 Jesu tẹjú mọ́ wọn, ó wí pé, “Kò ṣeéṣe fún eniyan, ṣugbọn ti Ọlọrun kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé, kò sí ohun tí Ọlọrun kò lè ṣe.”

28 Peteru bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé, “Wò ó ná, a ti fi ohun gbogbo sílẹ̀ láti tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!”

29 Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kò sí ẹnìkan tí ó fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, tabi ìyá, tabi baba, tabi ọmọ, tabi ilẹ̀, sílẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere,

30 tí kò ní rí ilé, arakunrin ati arabinrin, ìyá ati ọmọ, ati ilẹ̀ gbà ní ọgọrun-un ìlọ́po ní ìgbà ìsinsìnyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé pẹlu inúnibíni ni, yóo sì tún rí ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀.

31 Ṣugbọn ọpọlọpọ tí ó jẹ́ ẹni iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn, àwọn èrò ẹ̀yìn yóo wá di ẹni iwájú.”

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ Lẹẹkẹta

32 Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, tí wọn ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, Jesu ṣáájú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e. Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹ̀rù sì ba àwọn eniyan tí wọ́n tẹ̀lé e. Ó bá tún pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sí apá kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun fún wọn.

33 Ó ní, “Lílọ ni à ń lọ sí Jerusalẹmu yìí, a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin lọ́wọ́. Wọn yóo dá a lẹ́bi ikú, wọn yóo sì fi lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́.

34 Wọn yóo fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n yóo tutọ́ sí i lára, wọn yóo nà án, wọn yóo sì pa á. Ṣugbọn lẹ́yìn ọjọ́ mẹta yóo jí dìde.”

Jakọbu ati Johanu Bèèrè Ipò Ọlá

35 Nígbà náà ni Jakọbu ati Johanu, àwọn ọmọ Sebede, wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí fún un pé, “Olùkọ́ni, a fẹ́ kí o ṣe ohunkohun tí a bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ fún wa.”

36 Jesu bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín?”

37 Wọ́n ní, “Gbà fún wa pé, nígbà tí ó bá di ìgbà ìgúnwà rẹ, kí ọ̀kan ninu wa jókòó ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ, kí ẹnìkejì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ.”

38 Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀ ń bèèrè. Ṣé ẹ lè mu ninu ife ìrora tí èmi yóo mu, tabi kí ojú yín rí irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí?”

39 Wọ́n wí fún un pé, “Àwa lè ṣe é.”Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ninu irú ife ìrora tí n óo mu ẹ̀yin náà yóo mu, irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí, tiyín náà yóo sì rí i.

40 Ṣugbọn ní ti jíjókòó ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ẹ̀gbẹ́ òsì mi, kì í ṣe tèmi láti fún ẹnikẹ́ni, ipò wọnyi wà fún àwọn tí Ọlọrun ti pèsè wọn sílẹ̀ fún.”

41 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá yòókù gbọ́, inú bẹ̀rẹ̀ sí bí wọn sí Jakọbu ati Johanu.

42 Ni Jesu bá pè wọ́n, ó wí fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá ninu wọn a sì máa lo agbára lórí wọn,

43 ṣugbọn tiyín kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ pataki láàrin yín níláti jẹ́ iranṣẹ yín;

44 ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ aṣaaju ninu yín níláti máa ṣe ẹrú gbogbo yín.

45 Nítorí Ọmọ-Eniyan pàápàá kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un, ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.”

Jesu Wo Batimiu Afọ́jú Sàn

46 Wọn dé Jẹriko. Bí Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ogunlọ́gọ̀ eniyan ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, Batimiu afọ́jú, ọmọ Timiu, jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń ṣagbe.

47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ará Nasarẹti ni ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Jesu! Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi!”

48 Ọpọlọpọ eniyan ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn sibẹ ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi.”

49 Jesu bá dúró, ó ní, “Ẹ pè é wá.”Wọ́n wá wí fún afọ́jú náà pé, “Ṣe ara gírí, dìde, ó ń pè ọ́.”

50 Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà bọ́ aṣọ rẹ̀ sọ sí apá kan, ó fò sókè, ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu.

51 Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?”Afọ́jú náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ tún ríran ni.”

52 Jesu bá wí fún un pé, “Máa lọ, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.”Lójú kan náà, afọ́jú náà bá ríran, ó bá ń bá Jesu lọ ní ọ̀nà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16