1 Jesu tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan lẹ́bàá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi níláti bọ́ sin ọkọ̀ ojú omi kan, ó bá jókòó níbẹ̀ lójú omi. Gbogbo àwọn eniyan wà ní èbúté, wọ́n jókòó lórí iyanrìn.
2 Ó bá ń fi òwe kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan. Ó wí fún wọn ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé:
3 “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ọkunrin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn.
4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn lọ, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ.
5 Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí òkúta tí erùpẹ̀ díẹ̀ bò lórí. Láìpẹ́, wọ́n yọ sókè nítorí erùpẹ̀ ibẹ̀ kò jinlẹ̀.
6 Nígbà tí oòrùn mú, ó jó wọn pa, nítorí wọn kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; wọ́n bá kú.
7 Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí ẹ̀gún dàgbà, ó fún wọn pa, nítorí náà wọn kò so èso.
8 Irúgbìn mìíràn bọ́ sí ilẹ̀ tí ó dára, wọ́n yọ sókè, wọ́n ń dàgbà, wọ́n sì ń so èso, òmíràn ọgbọ̀n, òmíràn ọgọta, òmíràn ọgọrun-un.”
9 Lẹ́yìn náà Jesu ní, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”
10 Nígbà tí ó ku òun nìkan, àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila bèèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó fi ń sọ̀rọ̀.
11 Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn bí òwe bí òwe ni fún àwọn ẹlòmíràn tí ó wà lóde.
12 Kí wọn baà lè la ojú sílẹ̀ṣugbọn kí wọn má ríran;kí wọn gbọ́ títíṣugbọn kí òye má yé wọn;kí wọn má baà ronupiwada,kí á má baà dáríjì wọ́n.”
13 Ó wá wí fún wọn pé, “Nígbà tí òwe yìí kò ye yín, báwo ni ẹ óo ti ṣe mọ gbogbo àwọn òwe ìyókù?
14 Afunrugbin fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ ìròyìn ayọ̀.
15 Àwọn wọnyi ni ti ẹ̀bá ọ̀nà, níbi tí a fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà sí: àwọn tí ó jẹ́ pé, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, Satani wá, ó mú ọ̀rọ̀ tí a ti fún sinu ọkàn wọn lọ.
16 Bákan náà ni àwọn ẹlòmíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí òkúta, nígbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọn á fi inú dídùn gbà á.
17 Ṣugbọn nítorí tí wọn kò ní gbòǹgbò ninu ara wọn, àkókò díẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà gbé ninu wọn. Nígbà tí ìyọnu tabi inúnibíni bá dé nítorí ọ̀rọ̀ náà lẹsẹkẹsẹ wọn á kùnà.
18 Àwọn mìíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún, wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà,
19 ṣugbọn ayé, ati ìtànjẹ ọrọ̀, ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mìíràn gba ọkàn wọn, ó sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso.
20 Àwọn mìíràn dàbí irúgbìn tí a fún sórí ilẹ̀ rere. Àwọn yìí ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n gbà á, tí wọ́n sì so èso, òmíràn ọgbọọgbọn, òmíràn ọgọọgọta, òmíran ọgọọgọrun-un.”
21 Jesu bi wọ́n pé, “Eniyan a máa gbé fìtílà wọlé kí ó fi igbá bò ó, tabi kí ó gbé e sí abẹ́ ibùsùn? Mo ṣebí lórí ọ̀pá fìtílà ni à ń gbé e kà.
22 Nítorí kò sí ohun tí a fi pamọ́ tí a kò ní gbé jáde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ kan tí a kò ní yọ sí gbangba.
23 Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”
24 Ó tún wí fún wọn pé, “Ẹ fi ara balẹ̀ ro ohun tí ẹ bá gbọ́. Irú òfin tí ẹ bá fi ń ṣe ìdájọ́ fún eniyan ni a óo fi ṣe ìdájọ́ fún ẹ̀yin náà pẹlu èlé.
25 Nítorí ẹni tí ó bá ní, a óo tún fi fún un sí i; ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀.”
26 Ó tún wí pé, “Bí ìjọba Ọlọrun ti rí nìyí: ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn sí oko;
27 ó ń sùn lálẹ́, ó ń jí ní òwúrọ̀, irúgbìn ń hù, ó ń dàgbà ní ọ̀nà tí ọkunrin náà kò mọ̀.
28 Ilẹ̀ fúnra ara rẹ̀ ni ó ń mú kí ohun ọ̀gbìn so èso: yóo kọ́ rú ewé, lẹ́yìn náà èso rẹ̀ yóo gbó.
29 Nígbà tí ó bá gbó tán, lẹsẹkẹsẹ ọkunrin náà yóo yọ dòjé jáde nítorí pé àkókò ìkórè ti dé.”
30 Ó tún bèèrè pé, “Báwo ni à bá ṣe ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun, tabi òwe wo ni à bá fi ṣe àkàwé rẹ̀?”
31 Ó ní, “Ó dàbí wóró musitadi kan tí a gbìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn,
32 ṣugbọn nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbà, ó wá tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ, ó ní ẹ̀ka ńláńlá, àwọn ẹyẹ wá ń tẹ́ ìtẹ́ wọn sábẹ́ òjìji rẹ̀.”
33 Pẹlu ọpọlọpọ irú òwe bẹ́ẹ̀ ni Jesu fi ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn, gẹ́gẹ́ bí òye wọn ti mọ láti lè gbọ́.
34 Kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láì lo òwe. Ṣugbọn nígbà tí ó bá ku òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, a máa túmọ̀ gbogbo rẹ̀ fún wọn.
35 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí èbúté ní òdìkejì òkun.”
36 Wọ́n bá fi àwọn eniyan sílẹ̀, wọ́n mú un lọ pẹlu wọn ninu ọkọ̀ tí ó wà. Àwọn ọkọ̀ mìíràn wà níbẹ̀ pẹlu.
37 Ìjì líle kan bá dé, omi òkun bẹ̀rẹ̀ sí bì lu ọkọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí omi fi kún inú rẹ̀.
38 Jesu wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀, ó fi ìrọ̀rí kan rọrí, ó bá sùn lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ jí i, wọ́n ní, “Olùkọ́ni, o kò tilẹ̀ bìkítà bí a bá ṣègbé sinu omi!”
39 Ó bá dìde lójú oorun, ó bá afẹ́fẹ́ wí, ó wí fún òkun pé, “Pa rọ́rọ́.” Afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Ìdákẹ́rọ́rọ́ bá dé.
40 Ó bá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ṣe lójo bẹ́ẹ̀? Ẹ kò ì tíì ní igbagbọ sibẹ?”
41 Ẹ̀rù ńlá bà wọ́n. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn pé, “Ta ni èyí, tí afẹ́fẹ́ ati òkun ń gbọ́ràn sí lẹ́nu!”