1 Àwọn Farisi ati àwọn amòfin kan tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu péjọ sí ọ̀dọ̀ Jesu.
2 Wọ́n rí ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí ni pé, wọn kò wẹ ọwọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin.
3 (Nítorí pé àwọn Farisi ati gbogbo àwọn Juu yòókù kò jẹ́ jẹun láì wẹ ọwọ́ ní ọ̀nà tí òfin là sílẹ̀; wọ́n ń tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn.
4 Bí wọn bá ti ọjà dé, wọ́n kò jẹ́ jẹun láìjẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ wẹ̀. Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni ó ti di àṣà wọn, gẹ́gẹ́ bíi fífọ àwo ìmumi, ìkòkò ìpọnmi ati àwọn àwo kòtò onídẹ.)
5 Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀, tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?”
6 Jesu wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni Aisaya sọ ní àtijọ́ nípa ẹ̀yin àgàbàgebè, tí ó sì kọ ọ́ báyìí pé,‘Ọlọrun wí pé: Ẹnu ni àwọn eniyan wọnyi fi ń yẹ́ mi sí,ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi,
7 asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí,ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́nibí òfin Ọlọrun.’
8 “Ẹ fi àṣẹ Ọlọrun sílẹ̀, ẹ wá dìmọ́ àṣà eniyan.”
9 Jesu tún wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni pé ẹ pa àṣẹ Ọlọrun tì, kí ẹ lè mú àṣẹ ìbílẹ̀ yín ṣẹ.
10 Nítorí Mose wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ’ ati pé, ‘Kí á pa ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí baba tabi ìyá rẹ̀.’
11 Ṣugbọn ẹ̀yin wí pé, ‘Bí eniyan bá wí fún baba tabi ìyá rẹ̀ pé ohunkohun tí n bá fun yín, Kobani ni,’ (èyí ni pé ẹ̀bùn fún Ọlọrun ni),
12 ẹ ti gbà pé ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ohunkohun í ṣe fún baba tabi ìyá rẹ̀ mọ́.
13 Ẹ fi àṣà ìbílẹ̀ yín yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ọpọlọpọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ tún ń ṣe.”
14 Ó tún pe àwọn eniyan, ó ń wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ fi etí sílẹ̀, kí ọ̀rọ̀ mi ye yín.
15 Kò sí ohun kan láti òde wá tí ó wọ inú eniyan lọ tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́. Ṣugbọn àwọn ohun tí ó ń jáde láti inú eniyan ni ó ń sọ ọ́ di aláìmọ́. [
16 Ẹni tí ó bá ní etí láti gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”]
17 Nígbà tí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, tí ó wọ inú ilé lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í ní ìtumọ̀ òwe yìí.
18 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin náà kò ní òye? Kò ye yín pé kì í ṣe nǹkan tí ó bá wọ inú eniyan lọ níí sọ eniyan di aláìmọ́?
19 Nítorí kì í wọ inú ọkàn lọ, bíkòṣe inú ikùn, a sì tún jáde.” (Báyìí ni ó pe gbogbo oúnjẹ ní mímọ́.)
20 Ó tún fi kún un pé, “Àwọn nǹkan tí ń jáde láti inú eniyan ni ó ń sọ ọ́ di aláìmọ́.
21 Nítorí láti inú ọkàn eniyan ni ète burúkú ti ń jáde: ìṣekúṣe, olè jíjà, ìpànìyàn,
22 àgbèrè, ojúkòkòrò, ìwà ìkà, ẹ̀tàn, ìwà wọ̀bìà, owú jíjẹ, ọ̀rọ̀ ìṣáátá, ìwà ìgbéraga, ìwà òmùgọ̀.
23 Láti inú ni gbogbo àwọn nǹkan ibi wọnyi ti ń wá, àwọn ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.”
24 Láti ibẹ̀ Jesu gbéra, ó lọ sí agbègbè ìlú Tire, ó sì wọ̀ sí ilé kan. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀, ṣugbọn kò lè fi ara pamọ́.
25 Obinrin kan tí ọdọmọbinrin rẹ̀ ní ẹ̀mí èṣù gbọ́ nípa rẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó wá kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀.
26 Ọmọ ìbílẹ̀ Giriki ni obinrin yìí, a bí i ní Fonike ní Siria. Ó ń bẹ̀ ẹ́ kí ó lé ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò ninu ọdọmọbinrin òun.
27 Jesu wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ rí oúnjẹ jẹ yó ná, nítorí kò dára kí á mú oúnjẹ ọmọ kí á sọ ọ́ fún ajá.”
28 Ṣugbọn obinrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, alàgbà, ṣugbọn àwọn ajá a máa jẹ ẹ̀rúnrún oúnjẹ àwọn ọmọ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili.”
29 Jesu dá a lóhùn pé, “Nítorí gbolohun rẹ yìí, máa lọ sí ilé rẹ, ẹ̀mí èṣù náà ti jáde kúrò ninu ọmọ rẹ.”
30 Ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀, ó rí ọmọde náà tí ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn, tí ẹ̀mí burúkú náà ti jáde kúrò lára rẹ̀.
31 Ó tún jáde kúrò ní agbègbè ìlú Tire, ó la ìlú Sidoni kọjá lọ sí òkun Galili ní ọ̀nà ààrin Ìlú Mẹ́wàá.
32 Wọ́n wá gbé adití kan tí ń kólòlò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ lé e.
33 Ó bá mú un bọ́ sí apá kan, kúrò láàrin àwọn ọ̀pọ̀ eniyan, ó ti ìka rẹ̀ bọ ọkunrin náà létí, ó tutọ́, ó fi kan ahọ́n rẹ̀.
34 Ó gbé ojú sí òkè ọ̀run, ó kẹ́dùn, ó bá ní, “Efata,” ìtumọ̀ èyí tí i ṣe, “Ìwọ, ṣí.”
35 Etí ọkunrin náà bá ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ tú, ó bá ń sọ̀rọ̀ gaara.
36 Jesu kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má wí fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn bí ó ti ń kìlọ̀ fún wọn tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ròyìn rẹ̀ tó.