Maku 8 BM

1 Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ọpọlọpọ eniyan tún wà lọ́dọ̀ Jesu, tí wọn kò rí nǹkan jẹ, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé,

2 “Àánú àwọn eniyan wọnyi ń ṣe mí, nítorí ó di ọjọ́ mẹta tí wọ́n ti wà pẹlu mi, wọn kò ní ohun tí wọn yóo jẹ mọ́.

3 Bí mo bá ní kí wọn túká lọ sí ilé wọn ní ebi, yóo rẹ̀ wọ́n lọ́nà, nítorí àwọn mìíràn ninu wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.”

4 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Níbo ni a óo ti rí ohun tí a óo fún gbogbo àwọn wọnyi jẹ ní aṣálẹ̀ yìí?”

5 Jesu bi wọ́n pé, “Burẹdi mélòó ni ẹ ní?”Wọ́n ní, “Meje.”

6 Ó bá pàṣẹ kí àwọn eniyan jókòó ní ilẹ̀. Ó mú burẹdi meje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù ú fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.

7 Wọ́n tún ní àwọn ẹja kéékèèké díẹ̀. Ó gbadura sí i, ó ní kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pín in fún àwọn eniyan.

8-9 Àwọn eniyan jẹ, wọ́n yó. Wọ́n bá kó ẹ̀rúnrún àjẹkù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ ńlá meje. Àwọn eniyan tí wọn jẹun tó bí ẹgbaaji (4,000). Lẹ́yìn náà Jesu ní kí wọn túká.

10 Lẹsẹkẹsẹ ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá lọ sí agbègbè Dalimanuta.

Àwọn Farisi ń fẹ́ Àmì

11 Àwọn Farisi jáde lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò nípa fífi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run hàn wọ́n.

12 Inú rẹ̀ bàjẹ́, ó ní, “Nítorí kí ni àwọn eniyan ṣe ń wá àmì lóde òní? Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé a kò ní fún wọn ní àmì kan.”

13 Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó tún wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó lọ sí òdìkejì òkun.

Ìwúkàrà Àwọn Farisi ati Ti Hẹrọdu

14 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu gbàgbé láti mú burẹdi lọ́wọ́ àfi ọ̀kan ṣoṣo tí wọn ní ninu ọkọ̀ ojú omi.

15 Jesu bá kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára kí ẹ sì ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati ìwúkàrà Hẹrọdu.”

16 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Nítorí a kò ní burẹdi ni.”

17 Nígbà tí Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sọ láàrin ara yín pé nítorí ẹ kò ní burẹdi lọ́wọ́ ni? Ẹ kò ì tíì mọ̀ sibẹ, tabi òye kò ì tíì ye yín? Àṣé ọkàn yín le tóbẹ́ẹ̀?

18 Ẹ ní ojú lásán ni, ẹ kò ríran? Ẹ ní etí lásán ni, ẹ kò fi gbọ́ràn?

19 Ẹ kò ranti nígbà tí mo bu burẹdi marun-un fún ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan, agbọ̀n mélòó ni àjẹkù tí ẹ kó jọ?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Mejila.”

20 Ó tún bi wọ́n pé, “Nígbà tí mo fi burẹdi meje bọ́ àwọn ẹgbaaji (4,000) eniyan, agbọ̀n ńlá mélòó ni àjẹkù tí ẹ kó jọ?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Meje.”

21 Ó tún bi wọ́n pé, “Kò ì tíì ye yín sibẹ?”

Jesu Wo Afọ́jú kan Sàn ní Bẹtisaida

22 Wọ́n dé Bẹtisaida. Àwọn ẹnìkan mú afọ́jú kan wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó fọwọ́ kàn án.

23 Ó bá fa afọ́jú náà lọ́wọ́ jáde lọ sí ẹ̀yìn abúlé, ó tutọ́ sí i lójú. Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ o rí ohunkohun?”

24 Ọkunrin náà ríran bàìbàì, ó ní, “Mo rí àwọn eniyan tí ń rìn, ṣugbọn bí igi ni wọ́n rí lójú mi.”

25 Lẹ́yìn náà Jesu tún fi ọwọ́ kàn án lójú. Ọkunrin náà tẹjú mọ́ àwọn nǹkan tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ojú rẹ̀ sì bọ̀ sípò, ó wá rí gbogbo nǹkan kedere, títí kan ohun tí ó jìnnà.

26 Jesu wí fún un pé, kí ó máa lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má ṣe wọ inú abúlé lọ.

Peteru Jẹ́wọ́ Ẹni Tí Jesu Í Ṣe

27 Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí àwọn abúlé tí ó wà lẹ́bàá ìlú Kesaria ti Filipi. Bí wọ́n ti ń lọ ní ọ̀nà, ó bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn eniyan ń pè mí?”

28 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ń pè ọ́ ní Johanu Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn ní Elija ni ọ́, àwọn mìíràn tún ní ọ̀kan ninu àwọn wolii ni ọ́.”

29 Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́, ta ni ẹ̀yin ń pè mí?”Peteru dá a lóhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà.”

30 Ó bá kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀

31 Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn pé, “Ọmọ-Eniyan níláti jìyà pupọ. Àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin yóo ta á nù, wọn yóo sì pa á, ṣugbọn lẹ́yìn ọjọ́ mẹta yóo jí dìde.”

32 Ó ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn kedere. Nígbà náà ni Peteru mú un, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí.

33 Ṣugbọn Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá Peteru wí. Ó ní, “Kó ara rẹ kúrò níwájú mi, ìwọ Satani. Ìwọ kò kó ohun ti Ọlọrun lékàn àfi ti ayé.”

34 Ó pe àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti gbàgbé ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó wá máa tẹ̀lé mi.

35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere, yóo gba ẹ̀mí rẹ̀ là.

36 Nítorí anfaani kí ni ó jẹ́ fún eniyan kí ó jèrè gbogbo dúkìá ayé yìí, ṣugbọn kí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀?

37 Kí ni eniyan lè fi ṣe pàṣípààrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀?

38 Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú èmi ati ọ̀rọ̀ mi ní àkókò burúkú yìí, tí àwọn eniyan kò ka nǹkan Ọlọrun sí, Ọmọ-Eniyan yóo tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu àwọn angẹli mímọ́.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16