Maku 2 BM

Jesu Wo Arọ Sàn

1 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Jesu tún lọ sí Kapanaumu, àwọn eniyan gbọ́ pé ó wà ninu ilé kan.

2 Ọ̀pọ̀ eniyan bá wá péjọ sibẹ, wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pé ati inú ilé, ati ẹnu ọ̀nà ni ó kún. Ó bá ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn.

3 Àwọn mẹrin kan ń gbé arọ kan bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

4 Nígbà tí wọn kò lè gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n dá òrùlé lu ní ọ̀kánkán ibi tí Jesu wà. Nígbà tí wọ́n ti dá a lu tán, wọ́n sọ ọkunrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ibùsùn rẹ̀.

5 Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

6 Ṣugbọn àwọn amòfin kan jókòó níbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sinu pé,

7 “Kí ló dé tí eléyìí fi ń sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bíkòṣe Ọlọrun nìkan?”

8 Ṣugbọn Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé wọ́n ń ro èrò báyìí ninu ọkàn wọn. Ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kùn sinu?

9 Èwo ni ó rọrùn jù: Láti wí fún arọ náà pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tabi láti wí pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa rìn?’

10 Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni,” ó bá wí fún arọ náà pé,

11 “Mo wí fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.”

12 Ọkunrin náà bá dìde lẹsẹkẹsẹ, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó bá jáde lọ lójú gbogbo wọn. Ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń yin Ọlọrun, wọ́n ní, “A kò rí èyí rí.”

Jesu Pe Lefi

13 Jesu tún jáde lọ sí ẹ̀bá òkun, gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá ń kọ́ wọn.

14 Bí ó ti ń lọ, ó rí Lefi ọmọ Alfeu tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Lefi bá dìde, ó sì tẹ̀lé e.

15 Bí Jesu ti jókòó ní ilé Lefi, ọpọlọpọ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun, nítorí wọ́n pọ̀ tí wọn ń tẹ̀lé e.

16 Nígbà tí àwọn amòfin ninu àwọn Farisi rí i tí ó ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ati àwọn agbowó-odè jẹun, wọ́n bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ léèrè pé, “Kí ló dé tí ó fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”

17 Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá: èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

Ìbéèrè Nípa Ààwẹ̀ Gbígbà

18 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn Farisi ń gbààwẹ̀ ní àkókò kan. Àwọn kan wá, wọ́n ń bi Jesu pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀ ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tìrẹ kì í gbààwẹ̀?”

19 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ iyawo wà lọ́dọ̀ wọn, níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà pẹlu wọn, wọ́n kò lè máa gbààwẹ̀.

20 Ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀, tí a óo gba ọkọ iyawo kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn óo gbààwẹ̀ nígbà náà.

21 “Kò sí ẹni tíí fi ìrépé asọ titun tí kò ì tíì wọ omi rí lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù. Tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, aṣọ titun náà yóo súnkì lára ẹ̀wù náà, yóo wá tún fà á ya ju ti àkọ́kọ́ lọ.

22 Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí náà yóo bẹ́ àpò náà, ati ọtí ati àpò yóo bá ṣòfò. Ṣugbọn inú àpò awọ titun ni à ń fi ọtí titun sí.”

Ìbéèrè Nípa Ọjọ́ Ìsinmi

23 Ní àkókò kan ní Ọjọ́ Ìsinmi, bí Jesu ti ń la ààrin oko ọkà kọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà jẹ bí wọn tí ń lọ lọ́nà.

24 Àwọn Farisi wí fún un pé, “Wò bí wọn ti ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi!”

25 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò ì tíì ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí kò ní oúnjẹ, tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀?

26 Bí ó ti wọ ilé Ọlọrun lọ ní àkókò Abiatari Olórí Alufaa, tí ó jẹ burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, tí kò yẹ kí ẹnikẹ́ni jẹ, àfi alufaa nìkan, tí ó tún fún àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ jẹ?”

27 Ó wá wí fún wọn pé, “Lílò eniyan ni a dá Ọjọ́ Ìsinmi fún, a kò dá eniyan fún Ọjọ́ Ìsinmi.

28 Nítorí náà, Ọmọ-Eniyan ni Oluwa ohun gbogbo ati ti Ọjọ́ Ìsinmi pẹlu.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16