19 Ó dàbí ẹyọ wóró musitadi kan, tí ẹnìkan mú, tí ó gbìn sí oko rẹ̀. Nígbà tí ó bá dàgbà, ó di igi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run wá ń ṣe ìtẹ́ wọn sí orí ẹ̀ka rẹ̀.”
20 Ó tún sọ pé, “Kí ni ǹ bá fi ìjọba Ọlọrun wé?
21 Ó dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.”
22 Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ láti ìlú dé ìlú ati láti abúlé dé abúlé, ó ń kọ́ àwọn eniyan bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu.
23 Ẹnìkan wá bi í pé, “Alàgbà, ǹjẹ́ àwọn eniyan tí yóo là kò ní kéré báyìí?”Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé,
24 “Ẹ dù láti gba ẹnu ọ̀nà tí ó há wọlé, nítorí mò ń sọ fun yín pé ọpọlọpọ ni ó ń wá ọ̀nà láti wọlé ṣugbọn wọn kò lè wọlé.
25 Nígbà tí baálé ilé bá ti dìde, tí ó bá ti ìlẹ̀kùn, ẹ óo wá dúró lóde, ẹ óo bẹ̀rẹ̀ sí kanlẹ̀kùn, ẹ óo wí pé, ‘Alàgbà, ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ṣugbọn yóo da yín lóhùn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí!’