34 Wọ́n sọ fún wọn pé, “Oluwa nílò rẹ̀ ni.”
35 Wọ́n bá fà á lọ sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n tẹ́ ẹ̀wù wọn sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n bá gbé Jesu gùn ún.
36 Bí ó ti ń lọ, wọ́n ń tẹ́ ẹ̀wù wọn sọ́nà.
37 Nígbà tí ó súnmọ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Olifi, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi ayọ̀ kígbe sókè, wọ́n ń yin Ọlọrun nítorí gbogbo ohun ńlá tí wọ́n ti rí.
38 Wọ́n ń wí pé,“Aláásìkí ni ẹni tí ó ń bọ̀ bí ọba ní orúkọ Oluwa.Alaafia ní ọ̀run! Ògo ní òkè ọ̀run!”
39 Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Farisi tí wọ́n wà láàrin àwọn eniyan sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”
40 Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Mò ń sọ fun yín pé, bí àwọn wọnyi bá dákẹ́, àwọn òkúta yóo kígbe sókè.”