1 Ni gbogbo àwùjọ bá dìde, wọ́n fa Jesu lọ sọ́dọ̀ Pilatu.
2 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án pé, “A rí i pé ńṣe ni ọkunrin yìí ń ba ìlú jẹ́. Ó ní kí àwọn eniyan má san owó-orí. Ó tún pe ara rẹ̀ ní Mesaya, Ọba.”
3 Pilatu bá bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?”Ó dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí i.”
4 Pilatu wá sọ fún àwọn olórí alufaa ati àwọn eniyan pé, “Èmi kò rí àìdára kan tí ọkunrin yìí ṣe.”
5 Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ tẹnu mọ́ ẹ̀sùn wọn pé, “Ó ń fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ da àwọn eniyan rú; Galili ni ó ti kọ́ bẹ̀rẹ̀, ó ti dé gbogbo Judia níhìn-ín nisinsinyii.”
6 Nígbà tí Pilatu gbọ́ èyí, ó bèèrè bí ará Galili bá ni Jesu.