16 Ó wá dé Nasarẹti, ìlú tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí ilé ìpàdé. Ó bá dìde láti ka Ìwé Mímọ́.
17 Wọ́n fún un ní ìwé wolii Aisaya. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé,
18 “Ẹ̀mí Oluwa wà pẹlu minítorí ó ti fi òróró yàn míláti waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.Ó rán mi láti waasu ìtúsílẹ̀fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn,ati láti mú kí àwọn afọ́jú ríran;láti jẹ́ kí àwọn tí a ni lára lọ ní alaafia,
19 ati láti waasu ọdún tí Oluwa yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là.”
20 Ó bá pa ìwé náà dé, ó fi í fún olùtọ́jú ilé ìpàdé, ó bá jókòó. Gbogbo àwọn eniyan tí ó wà ninu ilé ìpàdé tẹjú mọ́ ọn;
21 ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé, “Lónìí ni àkọsílẹ̀ yìí ṣẹ ní ojú yín.”
22 Gbogbo wọn ni wọ́n gbà fún un, ẹnu sì yà wọ́n fún ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ó ń sọ jáde, wọ́n wá ń sọ pé, “Àbí ọmọ Josẹfu kọ́ nìyí ni?”