35 Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí!” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbé ọkunrin náà ṣánlẹ̀ lójú gbogbo wọn, ó bá jáde kúrò lára rẹ̀, láì pa á lára.
36 Ẹnu ya gbogbo eniyan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Irú ọ̀rọ̀ wo ni èyí? Nítorí pẹlu àṣẹ ati agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì ń jáde!”
37 Òkìkí Jesu sì kàn ká gbogbo ìgbèríko ibẹ̀.
38 Nígbà tí Jesu dìde kúrò ní ilé ìpàdé, ó wọ ilé Simoni lọ. Ìyá iyawo Simoni ń ṣàìsàn akọ ibà. Wọ́n bá sọ fún Jesu.
39 Ó bá lọ dúró lẹ́bàá ibùsùn ìyá náà, ó bá ibà náà wí, ibà sì fi ìyá náà sílẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún wọn.
40 Nígbà tí oòrùn wọ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n ní oríṣìíríṣìí àrùn ni wọ́n mú wá sọ́dọ̀ Jesu. Ó bá gbé ọwọ́ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó wò wọ́n sàn.
41 Àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan, wọ́n ń kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.”Jesu ń bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé Jesu ni Mesaya.