37 Obinrin kan báyìí wà ninu ìlú tí ó gbọ́ pé Jesu ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ìgò òróró olóòórùn dídùn lọ́wọ́,
38 ó lọ dúró lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń sunkún, omijé rẹ̀ ń dà sí ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi irun rẹ̀ nù ún, ó ń fi ẹnu kan ẹsẹ̀ Jesu, ó tún ń fi òróró kùn ún lẹ́sẹ̀.
39 Nígbà tí Farisi tí ó pe Jesu wá jẹun rí i, ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Ìbá jẹ́ pé wolii ni ọkunrin yìí, ìbá ti mọ irú ẹni tí obinrin yìí tí ó ń fọwọ́ kàn án jẹ́, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”
40 Jesu sọ fún un pé, “Simoni, mo fẹ́ bi ọ́ léèrè ọ̀rọ̀ kan.”Simoni ní, “Olùkọ́ni, máa wí.”
41 Jesu ní, “Àwọn meji kan jẹ gbèsè. Wọ́n yá owó lọ́wọ́ ẹnìkan tí í máa ń yá eniyan lówó pẹlu èlé. Ọ̀kan jẹ ẹ́ ní àpò marun-un owó fadaka, ekeji jẹ ẹ́ ní aadọta owó fadaka.
42 Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà ati san gbèsè wọn, ẹni tí ó yá wọn lówó bùn wọ́n ní owó náà. Ninu àwọn mejeeji, ta ni yóo fẹ́ràn rẹ̀ jù?”
43 Simoni dáhùn pé, “Ẹni tí ó fún ni owó pupọ ni.”Jesu wá sọ fún un pé, “O wí ire.”