20 Àwọn eniyan bá sọ fún un pé, “Ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ dúró lóde, wọ́n fẹ́ fi ojú kàn ọ́.”
21 Ṣugbọn Jesu wí fún gbogbo wọn pé, “Ìyá mi ati àwọn arakunrin mi ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń ṣe é.”
22 Ní ọjọ́ kan Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi kan, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọjá lọ sí òdìkejì òkun.” Ni wọ́n bá lọ.
23 Bí wọ́n ti ń wakọ̀ lọ, Jesu bá sùn lọ. Ìjì líle kan bá bẹ̀rẹ̀ lójú òkun, omi bẹ̀rẹ̀ sí ya wọ inú ọkọ̀; ẹ̀mí wọn sì wà ninu ewu.
24 Ni wọ́n bá lọ jí Jesu, wọ́n ní, “Ọ̀gá! Ọ̀gá! Ọkọ̀ mà ń rì lọ!”Ni Jesu bá dìde, ó bá afẹ́fẹ́ ati ìgbì omi wí, ni ìgbì bá rọlẹ̀, gbogbo nǹkan bá dákẹ́ jẹ́.
25 Ó bá bi wọ́n pé, “Igbagbọ yín dà?”Pẹlu ìbẹ̀rù ati ìyanu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ pé, “Ta nì yìí? Ó pàṣẹ fún afẹ́fẹ́ ati ìgbì omi, wọ́n sì ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu!”
26 Wọ́n gúnlẹ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Geraseni tí ó wà ní òdì keji òkun tí ó dojú kọ ilẹ̀ Galili.