3 ati Joana iyawo Kusa, ọmọ-ọ̀dọ̀ Hẹrọdu, ati Susana ati ọpọlọpọ àwọn mìíràn. Àwọn yìí ni wọ́n ń fi ohun ìní wọn bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ bùkátà wọn.
4 Ọpọlọpọ eniyan ń wọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn láti ìlú dé ìlú. Ó wá fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé:
5 “Afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, irúgbìn díẹ̀ bọ̀ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ.
6 Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí àpáta. Nígbà tí ó hù, ó bá gbẹ nítorí kò sí omi.
7 Irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin ẹ̀gún. Nígbà tí òun ati ẹ̀gún jọ dàgbà, ń ṣe ni ẹ̀gún fún un pa.
8 Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ dáradára, ó dàgbà, ó sì so èso. Irúgbìn kọ̀ọ̀kan so ọgọọgọrun-un.”Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó wá tún sọ pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”
9 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í ní ìtumọ̀ òwe yìí.