36 Àwọn tí ó mọ̀ bí ara ọkunrin náà ti ṣe dá ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn.
37 Gbogbo àwọn eniyan agbègbè Geraseni bá bẹ Jesu pé kí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Ó bá tún wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó pada sí ibi tí ó ti wá.
38 Ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀ bẹ Jesu pé kí ó jẹ́ kí òun máa wà lọ́dọ̀ rẹ̀.Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó ní,
39 “Pada lọ sí ilé rẹ, kí o lọ ròyìn ohun tí Ọlọrun ṣe fún ọ.”Ni ọkunrin náà bá ń káàkiri gbogbo ìlú, ó ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un.
40 Nígbà tí Jesu pada dé, àwọn eniyan fi tayọ̀tayọ̀ gbà á, nítorí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀.
41 Ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Jairu, tí ó jẹ́ alákòóso ilé ìpàdé, wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá òun kálọ sí ilé,
42 nítorí ọmọdebinrin rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó ní ń kú lọ. Ọmọ yìí tó ọmọ ọdún mejila.Bí Jesu ti ń lọ àwọn eniyan ń bì lù ú níhìn-ín lọ́hùn-ún.