42 nítorí ọmọdebinrin rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó ní ń kú lọ. Ọmọ yìí tó ọmọ ọdún mejila.Bí Jesu ti ń lọ àwọn eniyan ń bì lù ú níhìn-ín lọ́hùn-ún.
43 Obinrin kan wà tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀, tí kò dá fún ọdún mejila. Ó ti ná gbogbo ohun tí ó ní fún àwọn oníṣègùn ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè wò ó sàn.
44 Ó bá gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù Jesu, lẹsẹkẹsẹ ìsun ẹ̀jẹ̀ náà bá dá lára rẹ̀.
45 Jesu ní, “Ta ni fọwọ́ kàn mí?”Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́, Peteru ní, “Ọ̀gá, mélòó-mélòó ni àwọn eniyan tí wọn ń fún ọ, tí wọn ń tì ọ́?”
46 Ṣugbọn Jesu tún tẹnu mọ́ ọn pé, “Ẹnìkan fọwọ́ kàn mí sẹ́ẹ̀, nítorí mo mọ̀ pé agbára ti ara mi jáde.”
47 Nígbà tí obinrin náà rí i pé kò ṣe é fi pamọ́, ó bá jáde, ó ń gbọ̀n. Ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó bá sọ ìdí tí òun ṣe fọwọ́ kàn án lójú gbogbo eniyan ati bí òun ṣe rí ìwòsàn lẹsẹkẹsẹ.
48 Jesu wá wí fún un pé, “Ọmọbinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá, máa lọ ní alaafia.”