39 Ẹ̀mí kan a máa gbé e. Lójijì yóo kígbe tòò, ara rẹ̀ óo le gbandi. Yóo bá máa yọ ìfòòfó lẹ́nu, ni ẹ̀mí yìí yóo bá gbé e ṣánlẹ̀; kò sì ní tètè fi í sílẹ̀.
40 Mo bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pé kí wọ́n lé e jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.”
41 Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran oníbàjẹ́ ati alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó! N óo ti fara dà á fun yín tó! Mú ọmọ rẹ wá síhìn-ín.”
42 Bí ó ti ń mú un bọ̀, ẹ̀mí èṣù yìí bá gbé e ṣánlẹ̀, wárápá bá mú un. Jesu bá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó wo ọmọ náà sàn, ó bá fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́.
43 Ẹnu ya gbogbo eniyan sí iṣẹ́ ńlá Ọlọrun.Bí ẹnu ti ń ya gbogbo eniyan sí gbogbo ohun tí Jesu ń ṣe, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,
44 “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi wọ̀ yín létí. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò tí a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́.”
45 Ṣugbọn gbolohun yìí kò yé wọn, nítorí a ti fi ìtumọ̀ rẹ̀ pamọ́ fún wọn, kí ó má baà yé wọn. Ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí.