1 Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ẹ máa gbadura fún wa, pé kí ọ̀rọ̀ Oluwa lè máa gbilẹ̀, kí ògo rẹ̀ máa tàn sí i, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láàrin yín.
2 Kí ẹ tún máa gbadura pé kí Ọlọrun gbà wá lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn ìkà, nítorí kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó gbàgbọ́.
3 Ṣugbọn olódodo ni Oluwa, òun ni yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóo sì pa yín mọ́ kúrò ninu ibi gbogbo.
4 A ní ìdánilójú ninu Oluwa nípa yín pé àwọn ohun tí a ti sọ, tí ẹ sì ń ṣe, ni ẹ óo máa ṣe.
5 Oluwa yóo tọ́ ọkàn yín láti mọ ìfẹ́ Ọlọrun ati ohun tí Kristi faradà nítorí yín.
6 Ẹ̀yin ará, à ń pàṣẹ fun yín ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí ẹ yẹra fún àwọn onigbagbọ tí wọn bá ń rìn ségesège, tí wọn kò tẹ̀lé ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ wa.
7 Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ bí ó ti yẹ kí ẹ ṣe àfarawé wa, nítorí a kò rìn ségesège nígbà tí a wà láàrin yín.