8 Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn wa fà sọ́dọ̀ yín; kì í ṣe ìyìn rere nìkan ni a fẹ́ fun yín, ṣugbọn ó dàbí ẹni pé kí á gbé gbogbo ara wa fun yín, nítorí ẹ ṣọ̀wọ́n fún wa.
9 Ará, ẹ ranti ìṣòro ati làálàá wa, pé tọ̀sán-tòru ni à ń ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara wa, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára nígbà tí à ń waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín.
10 Ẹ̀yin gan-an lè jẹ́rìí, Ọlọrun náà sì tó ẹlẹ́rìí wa pé, pẹlu ìwà mímọ́ ati òdodo ati àìlẹ́gàn ni a fi wà láàrin ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́;
11 gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ pé bí baba ti rí sí àwọn ọmọ rẹ̀ ni a rí sí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín;
12 tí à ń gbà yín níyànjú, tí à ń rọ̀ yín, tí à ń kìlọ̀ fun yín nípa bí ó ti yẹ kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín bí ẹni tí Ọlọrun pè sinu ìjọba ati ògo rẹ̀.
13 Nítorí náà, àwa náà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo, nítorí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ẹ gbọ́ lẹ́nu wa, ẹ gbà á bí ó ti rí gan-an ni. Bí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ẹ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ eniyan. Ọ̀rọ̀ náà sì ń ṣiṣẹ́ ninu ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́.
14 Nítorí, ẹ ti di aláfarawé àwọn ìjọ Ọlọrun tí ó wà ninu Kristi Jesu ní ilẹ̀ Judia, nítorí irú ìyà tí wọ́n jẹ lọ́wọ́ àwọn Juu ni ẹ̀yin náà jẹ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà tiyín.