13 Nítorí àwọn tí wọn bá ṣe iṣẹ́ diakoni dáradára ti ṣí ọ̀nà ipò gíga fún ara wọn. Wọ́n lè sọ̀rọ̀ pẹlu ọpọlọpọ ìgboyà nípa igbagbọ tí ó wà ninu Kristi Jesu.
14 Mo ní ìrètí láti wá sọ́dọ̀ rẹ láìpẹ́, ṣugbọn mò ń kọ ìwé yìí,
15 nítorí bí mo bá pẹ́ kí n tó wá, kí o lè mọ̀ bí ó ti yẹ láti darí ètò ilé Ọlọrun, èyí tíí ṣe ìjọ Ọlọrun alààyè, òpó ati ààbò òtítọ́.
16 Kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé àṣírí ẹ̀sìn wa jinlẹ̀ pupọ:Ẹni tí ó farahàn ninu ẹran-ara,tí a dá láre ninu ẹ̀mí,tí àwọn angẹli fi ojú rí,tí à ń waasu rẹ̀ láàrin àwọn alaigbagbọ,tí a gbàgbọ́ ninu ayé,tí a gbé lọ sinu ògo.