5 Ṣugbọn ẹni tí ó bá jẹ́ opó nítòótọ́, tí kò ní ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, Ọlọrun nìkan ni ó ń wò, tí ó ń bẹ̀, tí ó ń gbadura sí tọ̀sán-tòru.
6 Ṣugbọn opó tí ó bá ń gbádùn ara rẹ̀ káàkiri ti kú sáyé.
7 Àwọn ohun tí o óo máa pa láṣẹ nìyí, kí wọ́n lè jẹ́ aláìlẹ́gàn.
8 Bí ẹnìkan kò bá pèsè fún àwọn ẹbí rẹ̀, pataki jùlọ fún àwọn ìdílé rẹ̀, olúwarẹ̀ ti lòdì sí ẹ̀sìn igbagbọ wa, ó sì burú ju alaigbagbọ lọ.
9 Má kọ orúkọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ bí opó àfi ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá dín ní ọgọta ọdún, tí ó sì jẹ́ aya ọkọ kan,
10 tí a jẹ́rìí sí iṣẹ́ rere rẹ̀, tí ó tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára, tí ó máa ń ṣe eniyan lálejò, tí kò sí iṣẹ́ tí ó kéré jù tí kò lè ṣe fún àwọn onigbagbọ, tí ó ti ran àwọn tí ó wà ninu ìyọnu lọ́wọ́. Ní kúkúrú, kí ó jẹ́ ẹni tí ń ṣe iṣẹ́ rere nígbà gbogbo.
11 Ṣọ́ra nípa kíkọ orúkọ àwọn opó tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ sílẹ̀, nítorí nígbà tí ara wọn bá gbóná, wọn yóo kọ ètò ti Kristi sílẹ̀, wọn yóo fẹ́ tún lọ́kọ.