9 Ọlọrun sa ti mu Danieli ba ojurere ati iyọ́nu pade lọdọ olori awọn iwẹfa.
10 Olori awọn iwẹfa si wi fun Danieli pe, Mo bẹ̀ru ọba, oluwa mi, ẹniti o yàn onjẹ nyin ati ohun mimu nyin: nitori bawo li on o ṣe ri oju nyin ki o faro jù ti awọn ọmọkunrin ẹgbẹ nyin kanna lọ? nigbana li ẹnyin o ṣe ki emi ki o fi ori mi wewu lọdọ ọba.
11 Nigbana ni Danieli wi fun olutọju ti olori awọn iwẹfa fi ṣe oluṣọ Danieli, Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah pe,
12 Dán awọn ọmọ-ọdọ rẹ wò, emi bẹ̀ ọ, ni ijọ mẹwa; ki o si jẹ ki nwọn ki o ma fi ẹ̀wa fun wa lati jẹ, ati omi lati mu.
13 Nigbana ni ki a wò oju wa niwaju rẹ, ati oju awọn ọmọ ti njẹ onjẹ adidùn ọba: bi iwọ ba si ti ri i si, bẹ̃ni ki o ṣe si awọn ọmọ-ọdọ rẹ.
14 Bẹ̃li o gbà fun wọn li ọ̀ran yi, o si dan wọn wò ni ijọ mẹwa.
15 Li opin ọjọ mẹwa, a ri oju wọn lẹwa, nwọn si sanra jù gbogbo awọn ti njẹ onjẹ adidùn ọba lọ.