Dan 1 YCE

Àwọn Ọdọmọkunrin kan ní Ààfin Nebukadnessari

1 LI ọdun kẹta ijọba Jehoiakimu, ọba Juda ni Nebukadnessari, ọba Babeli, wá si Jerusalemu, o si do tì i.

2 Oluwa si fi Jehoiakimu, ọba Juda le e lọwọ, pẹlu apakan ohun-elo ile Ọlọrun, ti o kó lọ si ilẹ Ṣinari, si ile oriṣa rẹ̀: o si kó ohun-elo na wá sinu ile-iṣura oriṣa rẹ̀.

3 Ọba si wi fun Aṣpenasi, olori awọn iwẹfa rẹ̀, pe, ki o mu awọn kan wá ninu awọn ọmọ Israeli, ninu iru-ọmọ ọba, ati ti awọn ijoye;

4 Awọn ọmọ ti kò lẹgan lara, ṣugbọn awọn ti o ṣe arẹwa, ti o si ni ìmọ ninu ọgbọ́n gbogbo, ti o mọ̀ oye, ti o si ni iyè ninu, ati iru awọn ti o yẹ lati duro li ãfin ọba ati awọn ti a ba ma kọ́ ni iwe ati ede awọn ara Kaldea.

5 Ọba si pese onjẹ wọn ojojumọ ninu adidùn ọba ati ninu ọti-waini ti o nmu: ki a bọ wọn bẹ̃ li ọdun mẹta, pe, li opin rẹ̀, ki nwọn ki o le duro niwaju ọba.

6 Njẹ ninu awọn wọnyi ni Danieli, Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, lati inu awọn ọmọ Juda:

7 Awọn ẹniti olori awọn iwẹfa si fi orukọ fun: bẹ̃li o pè Danieli ni Belteṣassari, ati Hananiah ni Ṣadraki; ati Miṣaeli ni Méṣaki; ati Asariah ni Abednego.

8 Ṣugbọn Danieli pinnu rẹ̀ li ọkàn rẹ̀ pe, on kì yio fi onjẹ adidùn ọba, ati ọti-waini ti o nmu ba ara on jẹ: nitorina o bẹ̀ olori awọn iwẹfa pe, ki on má ba ba ara on jẹ.

9 Ọlọrun sa ti mu Danieli ba ojurere ati iyọ́nu pade lọdọ olori awọn iwẹfa.

10 Olori awọn iwẹfa si wi fun Danieli pe, Mo bẹ̀ru ọba, oluwa mi, ẹniti o yàn onjẹ nyin ati ohun mimu nyin: nitori bawo li on o ṣe ri oju nyin ki o faro jù ti awọn ọmọkunrin ẹgbẹ nyin kanna lọ? nigbana li ẹnyin o ṣe ki emi ki o fi ori mi wewu lọdọ ọba.

11 Nigbana ni Danieli wi fun olutọju ti olori awọn iwẹfa fi ṣe oluṣọ Danieli, Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah pe,

12 Dán awọn ọmọ-ọdọ rẹ wò, emi bẹ̀ ọ, ni ijọ mẹwa; ki o si jẹ ki nwọn ki o ma fi ẹ̀wa fun wa lati jẹ, ati omi lati mu.

13 Nigbana ni ki a wò oju wa niwaju rẹ, ati oju awọn ọmọ ti njẹ onjẹ adidùn ọba: bi iwọ ba si ti ri i si, bẹ̃ni ki o ṣe si awọn ọmọ-ọdọ rẹ.

14 Bẹ̃li o gbà fun wọn li ọ̀ran yi, o si dan wọn wò ni ijọ mẹwa.

15 Li opin ọjọ mẹwa, a ri oju wọn lẹwa, nwọn si sanra jù gbogbo awọn ti njẹ onjẹ adidùn ọba lọ.

16 Bẹ̃ni olutọju mu onjẹ adidùn wọn kuro, ati ọti-waini ti nwọn iba mu, o si fun wọn li ẹ̀wa.

17 Bi o ṣe ti awọn ọmọ mẹrẹrin wọnyi ni, Ọlọrun fun wọn ni ìmọ ati oye ni gbogbo iwe ati ọgbọ́n: Danieli si li oye ni gbogbo iran ati alá.

18 Nigbati o si di opin ọjọ ti ọba ti da pe ki a mu wọn wá, nigbana ni olori awọn iwẹfa mu wọn wá siwaju Nebukadnessari.

19 Ọba si ba wọn sọ̀rọ: ninu gbogbo wọn, kò si si ẹniti o dabi Danieli, Hananiah, Miṣaeli ati Asariah: nitorina ni nwọn fi nduro niwaju ọba.

20 Ati ninu gbogbo ọ̀ran ọgbọ́n ati oye, ti ọba mbère lọwọ wọn, o ri pe ni iwọn igba mẹwa, nwọn sàn jù gbogbo awọn amoye ati ọlọgbọ́n ti o wà ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀ lọ.

21 Danieli si wà sibẹ titi di ọdun ikini ti Kirusi, ọba.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12