1 LI ọdun kẹta ijọba Belṣassari ọba, iran kan fi ara hàn fun mi, ani emi Danieli, lẹhin iran ti emi ri ni iṣaju.
2 Emi si ri loju iran, o si ṣe nigbati mo ri, ti mo si wà ni Ṣuṣani, li ãfin, ti o wà ni igberiko Elamu, mo si ri loju iran, mo si wà leti odò Ulai.
3 Mo si gbé oju mi soke, mo si ri, si kiye si i, àgbo kan ti o ni iwo meji duro lẹba odò na: iwo mejeji na si ga, ṣugbọn ekini ga jù ekeji lọ, eyiti o ga jù li o jade kẹhin.
4 Mo si ri àgbo na o nkàn siha iwọ-õrùn, ati si ariwa, ati si gusu; tobẹ ti gbogbo ẹranko kò fi le duro niwaju rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹniti o le gbani lọwọ rẹ̀: ṣugbọn o nṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀, o si nṣe ohun nlanla.
5 Bi mo si ti nwoye, kiyesi i, obukọ kan ti iha iwọ-õrùn jade wá sori gbogbo aiye, kò si fi ẹsẹ kan ilẹ: obukọ na si ni iwo nla kan lãrin oju rẹ̀.
6 O si tọ̀ àgbo ti o ni iwo meji na wá, eyi ti mo ti ri ti o duro lẹba odò na, o si fi irunu agbara sare si i.
7 Mo si ri i, o sunmọ ọdọ́-àgbo na, o si fi ikoro ibinu sare si i, o lu àgbo na bolẹ, o si ṣẹ́ iwo rẹ̀ mejeji: kò si si agbara ninu àgbo na, lati duro niwaju rẹ̀, ṣugbọn o lù u bolẹ o si tẹ̀ ẹ mọlẹ: kò si si ẹniti o le gbà àgbo na lọwọ rẹ̀.
8 Nigbana ni obukọ na nṣe ohun nla pupọpupọ, nigbati o si di alagbara tan, iwo nla na ṣẹ́; ati nipò rẹ̀ iwo mẹrin miran ti iṣe afiyesi si yọ jade si ọ̀na afẹfẹ mẹrẹrin ọrun.
9 Ati lati inu ọkan ninu wọn ni iwo kekere kan ti jade, ti o si di alagbara gidigidi, si iha gusu, ati si iha ila-õrùn, ati si iha ilẹ ogo.
10 O si di alagbara, titi de ogun ọrun, o si bì ṣubu ninu awọn ogun ọrun, ati ninu awọn irawọ si ilẹ, o si tẹ̀ wọn mọlẹ.
11 Ani o gbé ara rẹ̀ ga titi de ọdọ olori awọn ogun na pãpa, a si ti mu ẹbọ ojojumọ kuro lọdọ rẹ̀, a si wó ibujoko ìwa-mimọ́ rẹ̀ lulẹ.
12 A si fi ogun le e lọwọ pẹlu ẹbọ ojojumọ nitori irekọja, o si ja otitọ lulẹ, o si nṣe eyi, o si nri rere.
13 Mo si gbọ́ ẹni-mimọ́ ti nsọ̀rọ; ẹni-mimọ́ kan si wi fun ẹnikan ti nsọ̀rọ pe, Iran na niti ẹbọ ojojumọ, ati ti irekọja isọdahoro, ani lati fi ibi-mimọ́ ati ogun fun ni ni itẹmọlẹ yio ti pẹ to?
14 O si wi fun mi pe, titi fi di ọgbọnkanla le ọgọrun ti alẹ ti owurọ: nigbana ni a o si yà ibi-mimọ́ si mimọ́.
15 O si ṣe ti emi, ani emi Danieli si ti ri iran na, ti mo si nfẹ imọ̀ idi rẹ̀, si kiyesi i, ẹnikan duro niwaju mi, gẹgẹ bi aworan ọkunrin.
16 Emi si gbọ́ ohùn enia kan lãrin odò Ulai, ti o pè, ti o si wi pe, Gabrieli, mu ki eleyi moye iran na.
17 Bẹ̃li o si wá sibi ti mo duro: nigbati o si de, ẹ̀ru bà mi, mo si da oju mi bolẹ: ṣugbọn o wi fun mi pe, Kiyesi i, ọmọ enia: nitoripe ti akokò igba ikẹhin ni iran na iṣe.
18 Njẹ bi o ti mba mi sọ̀rọ, mo dãmu, mo si doju bolẹ: ṣugbọn o fi ọwọ kàn mi, o si gbé mi dide duro si ipò mi.
19 O si wipe, kiyesi i, emi o mu ọ mọ̀ ohun ti yio ṣe ni igba ikẹhin ibinu na: nitoripe, akokò igba ikẹhin ni eyi iṣe.
20 Agbò na ti iwọ ri ti o ni iwo meji nì, awọn ọba Media ati Persia ni nwọn.
21 Obukọ onirun nì li ọba Hellene: iwo nla ti o wà lãrin oju rẹ̀ mejeji li ọba ekini.
22 Njẹ bi eyini si ti ṣẹ́, ti iwo mẹrin miran si dide duro nipò rẹ̀, ijọba mẹrin ni yio dide ninu orilẹ-ède na, ṣugbọn kì yio ṣe ninu agbara rẹ̀.
23 Li akokò ikẹhin ijọba wọn, nigbati awọn oluṣe irekọja ba de ni kíkun, li ọba kan yio dide, ti oju rẹ̀ buru, ti o si moye ọ̀rọ arekereke.
24 Agbara rẹ̀ yio si le gidigidi, ṣugbọn kì iṣe agbara ti on tikararẹ̀: on o si ma ṣe iparun ti o yani lẹnu, yio si ma ri rere ninu iṣẹ, yio si pa awọn alagbara ati awọn enia ẹni-mimọ́ run.
25 Ati nipa arekereke rẹ̀ yio si mu ki iṣẹ ẹ̀tan ṣe dẽde lọwọ rẹ̀; on o si gbé ara rẹ̀ ga li ọkàn rẹ̀, lojiji ni yio si pa ọ̀pọlọpọ run, yio dide si olori awọn ọmọ-alade nì; ṣugbọn on o ṣẹ́ laisi ọwọ.
26 Ati iran ti alẹ ati ti owurọ ti a ti sọ, otitọ ni; sibẹ, iwọ sé iran na mọ, nitoripe fun ọjọ pipọ ni.
27 Arẹ̀ si mu emi Danieli, ara mi si ṣe alaida niwọn ọjọ melokan; lẹhin na, mo dide, mo si nṣe iṣẹ ọba; ẹ̀ru si bà mi, nitori iran na, ṣugbọn kò si ẹni ti o fi ye mi.