Dan 7 YCE

Àlá Daniẹli Nípa Àwọn Ẹranko Mẹrin

1 LI ọdun kini Belṣassari, ọba Babeli, ni Danieli lá alá, ati iran ori rẹ̀ lori akete rẹ̀: nigbana ni o kọwe alá na, o si sọ gbogbo ọ̀rọ na.

2 Danieli dahùn, o si wipe, Mo ri ni iran mi li oru, si kiyesi i, afẹfẹ mẹrẹrin ọrun njà loju okun nla.

3 Ẹranko mẹrin nla si ti inu okun jade soke, nwọn si yatọ si ara wọn.

4 Ẹranko kini dabi kiniun, o si ni iyẹ-apa idì: mo si wò titi a fi fà iyẹ-apa rẹ̀ wọnni tu, a si gbé e soke kuro ni ilẹ, a mu ki o fi ẹsẹ duro bi enia, a si fi aiya enia fun u.

5 Sa si kiyesi, ẹranko miran, ekeji, ti o dabi ẹranko beari, o si gbé ara rẹ̀ soke li apakan, o si ni egungun-ìha mẹta lẹnu rẹ̀ larin ehin rẹ̀: nwọn si wi fun u bayi pe, Dide ki o si jẹ ẹran pipọ.

6 Lẹhin eyi, mo ri, si kiyesi i, ẹranko miran, gẹgẹ bi ẹkùn, ti o ni iyẹ-apa ẹiyẹ mẹrin li ẹhin rẹ̀; ẹranko na ni ori mẹrin pẹlu; a si fi agbara ijọba fun u.

7 Lẹhin eyi, mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹranko kẹrin ti o burujù, ti o si lẹrù, ti o si lagbara gidigidi; o si ni ehin irin nla: o njẹ o si nfọ tũtu, o si fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ: o si yatọ si gbogbo awọn ẹranko ti o ṣiwaju rẹ̀; o si ni iwo mẹwa.

8 Mo si kiyesi awọn iwo na, si wò o, iwo kekere miran kan si jade larin wọn, niwaju eyiti a fa mẹta tu ninu awọn iwo iṣaju: si kiyesi i, oju gẹgẹ bi oju enia wà lara iwo yi, ati ẹnu ti nsọ ohun nlanlà.

Ìran Nípa Ẹni Ayérayé tó Jókòó lórí Ìtẹ́

9 Mo si wò titi a fi sọ̀ itẹ́ wọnni kalẹ titi Ẹni-àgba ọjọ na fi joko, aṣọ ẹniti o fún gẹgẹ bi ẹ̀gbọn owu, irun ori rẹ̀ si dabi irun agutan ti o mọ́: itẹ rẹ̀ jẹ ọwọ iná, ayika-kẹkẹ rẹ̀ si jẹ jijo iná.

10 Iṣàn iná nṣẹyọ, o si ntu jade lati iwaju rẹ̀ wá; awọn ẹgbẹ̃gbẹrun nṣe iranṣẹ fun u, ati awọn ẹgbẹgbarun nigba ẹgbarun duro niwaju rẹ̀: awọn onidajọ joko, a si ṣi iwe wọnni silẹ.

11 Nigbana ni mo wò nitori ohùn ọ̀rọ nla ti iwo na nsọ: mo si wò titi a fi pa ẹranko na, a si pa ara rẹ̀ run, a si sọ ọ sinu ọwọ iná ti njo.

12 Bi o ṣe ti awọn ẹranko iyokù ni, a ti gba agbara wọn kuro: nitori a ti yàn akokò ati ìgba fun wọn bi olukulùku yio ti pẹ tó.

13 Mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹnikan bi Ọmọ enia wá pẹlu awọsanma ọrun, o si wá sọdọ Ẹni-Àgba ọjọ na, nwọn si mu u sunmọ iwaju rẹ̀.

14 A si fi agbara ijọba fun u, ati ogo, ati ijọba, ki gbogbo enia, ati orilẹ, ati ède, ki o le ma sìn i; agbara ijọba rẹ̀ si jẹ agbara ijọba ainipẹkun, eyiti a kì yio rekọja, ati ijọba rẹ̀, eyiti a kì yio le parun.

A Túmọ̀ Ìran náà fún Daniẹli

15 Ẹmi emi Danieli si rẹwẹsi ninu ara mi, iran ori mi si mu mi dãmu.

16 Mo sunmọ ọkan ninu awọn ti o duro lapakan, mo si bi i lere otitọ gbogbo nkan wọnyi. Bẹ̃li o sọ fun mi, o si fi itumọ nkan wọnyi hàn fun mi.

17 Awọn ẹranko nla wọnyi, ti o jẹ mẹrin, li awọn ọba mẹrin ti yio dide li aiye.

18 Ṣugbọn awọn enia-mimọ́ ti Ọga-ogo julọ yio gbà ijọba, nwọn o si jogun ijọba na lai, ani titi lailai.

19 Nigbana ni mo si nfẹ imọ̀ otitọ ti ẹranko kẹrin, eyiti o yatọ si gbogbo awọn iyokù, ti o lẹrù gidigidi, eyi ti ehin rẹ̀ jẹ irin, ti ẽkanna rẹ̀ jẹ idẹ, ti njẹ, ti nfọ tũtu, ti o si nfi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ.

20 Ati niti iwo mẹwa ti o wà li ori rẹ̀, ati omiran na ti o yọ soke, niwaju eyiti mẹta si ṣubu; ani iwo na ti o ni oju, ati ẹnu ti nsọ̀rọ ohun nlanla, eyi ti oju rẹ̀ si koro jù ti awọn ẹgbẹ rẹ̀ lọ.

21 Mo ri iwo kanna si mba awọn enia-mimọ́ jagun, o si bori wọn.

22 Titi Ẹni-àgba ọjọ nì fi de, ti a si fi idalare fun awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo; titi akokò si fi de ti awọn enia-mimọ́ jogun ijọba na.

23 Bẹ̃li o wipe, Ẹranko kẹrin nì yio ṣe ijọba kẹrin li aiye, eyiti yio yàtọ si gbogbo ijọba miran, yio pa gbogbo aiye rẹ́, yio si tẹ̀ ẹ molẹ, yio si fọ ọ tũtu.

24 Ati iwo mẹwa, lati inu ijọba na wá ni ọba mẹwa yio dide: omiran kan yio si dide lẹhin wọn, on o si yàtọ si gbogbo awọn ti iṣaju, on o si bori ọba mẹta.

25 On o si ma sọ̀rọ nla si Ọga-ogo, yio si da awọn enia-mimọ́ ti Ọga-ogo lagara, yio si rò lati yi akokò ati ofin pada; a o si fi wọn le e lọwọ titi fi di igba akokò kan, ati awọn akokò, ati idaji akokò.

26 Ṣugbọn awọn onidajọ yio joko, nwọn o si gbà agbara ijọba rẹ̀ lọwọ rẹ̀ lati fi ṣòfo, ati lati pa a run de opin.

27 Ati ijọba, ati agbara ijọba ati ipa gbogbo ijọba ni gbogbo abẹ-ọrun, li a o si fi fun enia awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo, ijọba ẹniti iṣe ijọba ainipẹkun, ati gbogbo awọn alakoso ni yio ma sìn, ti nwọn o si ma tẹriba fun u.

28 Titi de ihinyi li opin ọ̀ran na. Bi o ṣe ti emi Danieli ni, igbero inu mi dãmu mi gidigidi, oju mi si yipada lori mi: ṣugbọn mo pa ọran na mọ́ li ọkàn mi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12