Esek 48 YCE

1 WỌNYI si ni orukọ awọn ẹ̀ya na. Lati opin ariwa titi de ọwọ́ ọ̀na Hetlonu, bi a ba nlọ si Hamati, Hasaenani, leti Damasku niha ariwa, de ọwọ́ Hamati; wọnyi sa ni ihà rẹ̀ ni ila-õrun ati iwọ-õrun; ipin kan fun Dani.

2 Ati ni àgbegbe Dani, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Aṣeri.

3 Ati ni àgbegbe Aṣeri, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Naftali.

4 Ati ni àgbegbe Naftali, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Manasse.

5 Ati ni àgbegbe Manasse, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Efraimu.

6 Ati ni àgbegbe Efraimu, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Reubeni.

7 Ati ni àgbegbe Reubeni, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Juda.

8 Ati ni àgbegbe Juda, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun ni yio jẹ ọrẹ ti ẹnyin o ta, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ije ni ibú, ati ni gigùn, bi ọkan ninu awọn ipin iyokù, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun: ibi mimọ́ yio si wà lãrin rẹ̀.

9 Ọrẹ ti ẹnyin o si ta fun Oluwa yio jẹ ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbã-marun ni ibú.

10 Ati fun wọn, ani fun awọn alufa, ni ọrẹ mimọ́ yi yio jẹ; ni ihà ariwa, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-marun ni ibú, ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-marun ni ibú, ati ni ihà gusu, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn: ibi mimọ́ yio si wà lãrin rẹ̀.

11 Yio jẹ ti awọn alufa ti a yà si mimọ́, ninu awọn ọmọ Sadoku; ti nwọn ti pa ilàna mi mọ, ti nwọn kò si ṣìna ni iṣìna awọn ọmọ Israeli, bi awọn Lefi ti ṣìna.

12 Ọrẹ ilẹ ti a si ta yi, yio jẹ ohun mimọ́ julọ fun wọn li àgbegbe awọn Lefi.

13 Ati ni ikọjusi àgbegbe awọn alufa, ni awọn Lefi yio ni ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbã-marun ni ibú: gigùn gbogbo rẹ̀ yio jẹ ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, ati ibú rẹ̀, ẹgbã-marun.

14 Nwọn kì yio si tà ninu rẹ̀, nwọn kì yio si fi ṣe paṣiparọ, bẹ̃ni nwọn kì yio si fi akọ́so ilẹ na si ọwọ́ ẹlomiran, nitoripe o jẹ mimọ́ fun Oluwa.

15 Ati ẹgbẹ̃dọgbọn ti o kù ni ibú, ni ikọjusi ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun na, yio jẹ ibi aimọ́ fun ilu-nla na, fun ibugbe, ati fun àgbegbe: ilu-nla na yio si wà lãrin rẹ̀.

16 Wọnyi ni yio si jẹ iwọ̀n rẹ̀; ni ihà ariwa, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà gusu, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta.

17 Awọn àgbegbe ilu-nla na yio jẹ niha ariwa, ãdọtalerugba, ati nihà gusu, ãdọtalerugba ati nihà ila-õrun, ãdọtalerugba, ati nihà iwọ-õrun, ãdọtalerugba.

18 Ati iyokù ni gigùn, ni ikọjusi ọrẹ ti ipin mimọ́ na, yio si jẹ ẹgbã-marun nihà ila-õrun, ati ẹgbã-marun nihà iwọ-õrun: yio si wà ni ikọjusi ọrẹ ipin mimọ́ na, ati ibisi rẹ̀ yio jẹ fun onjẹ fun awọn ti nsìn ni ilu-nla na.

19 Awọn ti mba nsìn ilu-nla na yio si ma sìn i, lati inu gbogbo ẹ̀ya Israeli.

20 Gbogbo ọrẹ na yio jẹ ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, nipa ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun: ẹ o si ta ọrẹ mimọ́ na, igun mẹrẹrin lọgbọ̃gba pẹlu ini ilu-nla na.

21 Ati iyokù yio jẹ ti olori, ni ihà kan, ati nihà keji ti ọrẹ mimọ́ na, ati ti ini ibi nla na, ni ikọjusi ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, ọrẹ ti àgbegbe ila-õrun, ati nihà iwọ-õrun ni ikọjusi ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun, nihà àgbegbe iwọ-õrun, ni ikọjusi awọn ipin ti olori: yio si jẹ ọrẹ mimọ́ na; ibi mimọ́ ile na, yio si wà lãrin rẹ̀.

22 Ati lati ini awọn Lefi, ati lati ini ti ilu-nla na, lãrin eyiti iṣe ti olori, lãrin àgbegbe Juda, ati lãrin àgbegbe Benjamini, yio jẹ ti olori.

23 Ati fun awọn ẹ̀ya iyokù, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Benjamini ipin kan.

24 Ati ni àgbegbe Benjamini, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Simeoni ipin kan.

25 Ati ni àgbegbe Simeoni, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Issakari ipin kan.

26 Ati ni àgbegbe Issakari, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Sebuloni ipin kan.

27 Ati ni àgbegbe Sebuloni, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Gadi ipin kan.

28 Ati ni àgbegbe Gadi, ni ihà gusu si gusu, àgbegbe na yio jẹ lati Tamari de omi ijà ni Kadeṣi, ati si odò, titi de okun nla.

29 Eyi ni ilẹ ti ẹnyin o fi ìbo pin ni ogún fun awọn ẹ̀ya Israeli, wọnyi si ni ipin wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.

30 Wọnyi si ni ibajade ti ilu-nla na lati ìha ariwa, ẹgbã-meji, o le ẹ̃dẹgbẹta oṣùwọn.

31 Awọn bode ilu-nla na yio jẹ gẹgẹ bi orukọ awọn ẹ̀ya Israeli: bodè mẹta nihà ariwa, bodè Reubeni ọkan, bodè Juda ọkan, bodè Lefi ọkan.

32 Ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta: ati bodè mẹta; ati bode Josefu ọkan, bode Benjamini ọkan, bodè Dani ọkan.

33 Ati ni ihà gusu, ẹgbã-meji, o le ẹ̃dẹgbẹta ìwọn: ati bodè mẹta; bodè Simeoni ọkan, bodè Issakari ọkan, bodè Sebuloni ọkan.

34 Ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, pẹlu bodè mẹta wọn; bodè Gadi ọkan, bodè Aṣeri ọkan, bodè Naftali ọkan.

35 O jẹ ẹgbã-mẹsan ìwọn yika: orukọ ilu-nla na lati ijọ na lọ yio ma jẹ, Oluwa mbẹ nibẹ̀.