Esek 38 YCE

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe,

2 Ọmọ enia, kọ oju rẹ si Gogu, ilẹ Magogu, olori Roṣi, Meṣeki, ati Tubali, si sọtẹlẹ si i,

3 Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi dojukọ ọ, iwọ Gogu, olori Roṣi, Meṣeki, ati Tubali:

4 Emi o si dá ọ padà, emi o si fi ìwọ kọ́ ọ li ẹ̀rẹkẹ́, emi o si mu ọ jade wá, ati gbogbo ogun rẹ, ẹṣin ati ẹlẹṣin, gbogbo wọn li a wọ̀ laṣọ daradara, ani ẹgbẹ́ nla pẹlu apata on asà, gbogbo wọn dì idà mu:

5 Persia, Etiopia, ati Libia pẹlu wọn; gbogbo wọn pẹlu asà on akoro:

6 Gomeri, ati gbogbo ogun rẹ̀; ile Togarma ti ihà ariwa, ati gbogbo ogun rẹ̀: enia pupọ̀ pẹlu rẹ̀.

7 Iwọ mura silẹ, si mura fun ara rẹ, iwọ, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ ti a gbajọ fun ọ, ki iwọ jẹ alãbo fun wọn.

8 Lẹhìn ọjọ pupọ̀ li a o bẹ̀ ọ wò: li ọdun ikẹhìn, iwọ o wá si ilẹ ti a gbà padà lọwọ idà, ti a si kojọ pọ̀ kuro lọdọ enia pupọ̀, lori oke-nla Israeli, ti iti ma di ahoro: ṣugbọn a mu u jade kuro ninu awọn orilẹ-ède, nwọn o si ma gbe li ailewu, gbogbo wọn.

9 Iwọ o goke wá, iwọ o si de bi ijì, iwọ o dabi awọsanma lati bò ilẹ, iwọ, ati gbogbo awọn ogun rẹ, ati ọ̀pọlọpọ enia pẹlu rẹ.

10 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; yio si ṣe pe nigbakanna ni nkan yio sọ si ọ̀kàn rẹ, iwọ o si rò èro ibi kan.

11 Iwọ o si wipe, emi o goke lọ si ilẹ ileto ti kò ni odi: emi o tọ̀ awọn ti o wà ni isimi lọ, ti nwọn ngbe laibẹ̀ru, ti gbogbo wọn ngbe laisi odi, ti nwọn kò si ni agbarà-irin tabi ẹnu-odi,

12 Lati lọ kó ikogun, ati lati lọ mu ohun ọdẹ; lati yi ọwọ́ rẹ si ibi ahoro wọnni ti a tẹ̀do nisisiyi, ati si enia ti a kojọ lati inu awọn orilẹ-ède wá, awọn ti o ti ni ohun-ọ̀sin ati ẹrù, ti ngbe oke ilẹ na.

13 Ṣeba, ati Dedani, ati awọn oniṣòwo Tarṣiṣi, pẹlu gbogbo awọn ọmọ kiniun wọn, yio si wi fun ọ pe, Ikogun ni iwọ wá kó? lati wá mu ohun ọdẹ li o ṣe gbá awọn ẹgbẹ́ rẹ jọ? lati wá rù fadaka ati wura lọ, lati wá rù ohun-ọsìn ati ẹrù, lati wá kó ikogun nla?

14 Nitorina, sọtẹlẹ, ọmọ enia, si wi fun Gogu pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ni ijọ na nigbati awọn enia mi Israeli ba ngbe laibẹ̀ru, iwọ kì yio mọ̀?

15 Iwọ o si ti ipò rẹ wá lati iha ariwa, iwọ, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ, gbogbo wọn li o ngùn ẹṣin, ẹgbẹ nla, ati ọ̀pọlọpọ ogun alagbara:

16 Iwọ o si goke wá si awọn enia mi Israeli, bi awọsanma lati bò ilẹ; yio si ṣe nikẹhin ọjọ, emi o si mu ọ dojukọ ilẹ mi, ki awọn orilẹ-ède ki o le mọ̀ mi, nigbati a o yà mi si mimọ́ ninu rẹ, niwaju wọn, iwọ Gogu.

17 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ li ẹniti mo ti sọ̀rọ rẹ̀ nigba atijọ lati ọwọ́ awọn iranṣẹ mi awọn woli Israeli, ti nwọn sọtẹlẹ li ọjọ wọnni li ọdun pupọ pe, emi o mu ọ wá dojukọ wọn?

18 Yio si ṣe nigbakanna li ákoko ti Gogu yio wá dojukọ ilẹ Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi, ti irúnu mi yio yọ li oju mi.

19 Nitori ni ijowu mi ati ni iná ibinu mi ni mo ti sọ̀rọ, Nitõtọ li ọjọ na mimì nla kan yio wà ni ilẹ Israeli;

20 Awọn ẹja inu okun, ati awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati awọn ẹranko inu igbó, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, ati gbogbo enia ti mbẹ loju ilẹ, yio si mì niwaju mi, a o si bì òke-nla ṣubu, ati gbogbo ibi giga yio ṣubu, olukuluku ogiri yio ṣubu lulẹ.

21 Emi o si pè idà si i lori gbogbo oke mi, ni Oluwa Ọlọrun wi: idà olukuluku yio si dojukọ arakunrin rẹ̀.

22 Emi o si fi ajàkalẹ arùn ati ẹjẹ ba a wijọ; emi o si rọ̀ ojò pupọ̀, ati yìnyin nla, iná ati imi-ọjọ, si i lori, ati sori áwọn ẹgbẹ rẹ̀, ati sori ọ̀pọlọpọ enia ti o wà pẹlu rẹ̀.

23 Emi o si gbe ara mi lèke, emi o si ya ara mi si mimọ́; emi o si di mimọ̀ loju ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.