Esek 5 YCE

Esekiẹli Gé Irun Rẹ̀

1 IWỌ, ọmọ enia, mu ọbẹ mimú, mu abẹ onigbajamọ̀, ki o si mu u kọja li ori rẹ, ati ni irùngbọn rẹ: si mu oṣuwọ̀n lati wọ̀n, ki o si pin irun na.

2 Iwọ o si fi iná sun idamẹta li ãrin ilu, nigbati ọjọ didotì ba pé: iwọ o si mu idamẹta, ki o si fi ọbẹ bù u kakiri: idamẹta ni iwọ o si tuka sinu ẹfũfù, emi o si yọ idà tẹle wọn.

3 Iwọ o si mu iye diẹ nibẹ, iwọ o si dì wọn si eti aṣọ rẹ.

4 Si tun mu ninu wọn, ki o si sọ wọn si ãrin iná, ki o si sun wọn ninu iná; lati inu rẹ̀ wá ni iná o ti jade wá si gbogbo ile Israeli.

5 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Eyi ni Jerusalemu: Emi ti gbe e kalẹ li ãrin awọn orilẹ-ède, ati awọn ilẹ ti o wà yi i ka kiri.

6 O si ti pa idajọ mi dà si buburu ju awọn orilẹ-ède lọ, ati ilana mi ju ilẹ ti o yi i kakiri: nitori nwọn ti kọ̀ idajọ ati ilana mi, nwọn kò rìn ninu wọn.

7 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Nitori ti ẹnyin ṣe ju awọn orilẹ-ède ti o yi nyin ka kiri lọ, ti ẹnyin kò rìn ninu ilana mi, ti ẹ kò pa idajọ mi mọ, ti ẹ kò si ṣe gẹgẹ bi idajọ awọn orilẹ-ède ti o yi nyin ka kiri.

8 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi: kiye si i, Emi, ani Emi, doju kọ ọ, emi o si ṣe idajọ li ãrin rẹ li oju awọn orilẹ-ède.

9 Emi o si ṣe ninu rẹ ohun ti emi kò ṣe ri, iru eyi ti emi kì yio si ṣe mọ, nitori gbogbo ohun irira rẹ.

10 Nitorina awọn baba yio jẹ awọn ọmọ li ãrin rẹ, ati awọn ọmọ yio si jẹ awọn baba wọn; emi o si ṣe idajọ ninu rẹ, ati gbogbo iyokù rẹ li emi o tuka si gbogbo ẹfũfù.

11 Nitorina Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà; Nitõtọ, nitori ti iwọ ti sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́ nipa ohun ẹgbin rẹ, ati pẹlu gbogbo ohun irira rẹ, nitori na li emi o ṣe dín ọ kù, oju mi kì yio dasi, bẹ̃ni emi kì yio ṣãnu fun ọ.

12 Idámẹta rẹ yio kú nipa ajakalẹ arùn, nwọn o si run li ãrin rẹ nipa iyàn, idámẹta yio si ṣubu nipa idà yi ọ ka kiri, emi o si tú idamẹta ká si gbogbo ẹfũfù, emi o si yọ idà tẹle wọn.

13 Bayi ni ibinu mi o ṣẹ, emi o si mu ibinu mi duro lori wọn, inu mi yio si tutù: nwọn o si mọ̀ pe emi Oluwa ti sọ ọ ninu itara mi, nigbati mo ba pari ibinu mi ninu wọn.

14 Emi o si fi ọ ṣòfo, emi o si sọ ọ di ẹ̀gan lãrin awọn orilẹ-ède ti o yi ọ ka kiri, li oju gbogbo awọn ti nkọja.

15 Bẹ̃ni yio si di ẹ̀gan ati ẹsín, ẹkọ́ ati iyanu si awọn orilẹ-ède ti o wà yi ọ ka kiri; nigbati emi o ṣe idajọ ninu rẹ ninu ibinu, ati ninu irunu on ibawi irunu. Emi Oluwa li o sọ ọ.

16 Nigbati emi o rán ọfà buburu iyàn si wọn, eyi ti yio jẹ fun iparun wọn, eyi ti emi o rán lati run nyin: emi o si sọ iyàn di pupọ̀ fun nyin, emi o si ṣẹ́ ọpá onjẹ nyin.

17 Bẹ̃ni emi o rán iyàn ati ẹranko buburu si nyin, nwọn o si gbà ọ li ọmọ, ajàkalẹ arùn ati ẹjẹ̀ yio si kọja lãrin rẹ, emi o si mu idà wá sori rẹ. Emi Oluwa li o ti sọ ọ.