Esek 8 YCE

Ìwà Ìbọ̀rìṣà Ní Jerusalẹmu

1 O si ṣe, li ọdun ẹkẹfa, li oṣù ẹkẹfa, li ọjọ karun oṣù, bi mo ti joko ni ile mi, ti awọn àgbagba Juda si joko niwaju mi, ni ọwọ́ Oluwa Ọlọrun bà le mi nibẹ.

2 Nigbana ni mo wò, si kiye si i, aworán bi irí iná: lati irí ẹgbẹ rẹ̀ ani de isalẹ, iná; ati lati ẹgbẹ́ rẹ de oke, bi irí didan bi àwọ amberi.

3 O si nà àworan ọwọ́ jade, o si mu mi ni ìdi-irun ori mi; ẹmi si gbe mi soke lagbedemeji aiye on ọrun, o si mu mi wá ni iran Ọlọrun si Jerusalemu, si ilẹkun ẹnu-ọ̀na ti inu to kọju si ariwa; nibiti ijoko ere owu wà ti nmu ni jowu.

4 Si kiyesi i, ogo Ọlọrun Israeli wà nibẹ, gẹgẹ bi iran ti mo ri ni pẹtẹlẹ.

5 Nigbana li o wi fun mi pe, Ọmọ enia, gbe oju rẹ soke nisisiyi si ọ̀na ihà ariwa. Bẹ̃ni mo gbe oju mi soke si ọ̀na ihà ariwa, si kiye si i, ere owu yi niha ariwa li ati-wọle ọ̀na pẹpẹ.

6 Pẹlupẹlu o wi fun mi pe, Ọmọ enia, iwọ ri ohun ti nwọn nṣe? ani irira nla ti ile Israeli nṣe nihinyi, ki emi ba le lọ jina kuro ni ibi mimọ́ mi? ṣugbọn si tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o jù wọnyi lọ.

7 O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na agbala; nigbati mo si wò, kiye si i iho lara ogiri.

8 Nigbana li o wi fun mi pe, Ọmọ enia, dá ogirí na lu nisisiyi: nigbati mo si ti dá ogiri na lu tan, kiye si i, ilẹkun.

9 O si wi fun mi pe, Wọ ile, ki o si wo ohun irira buburu ti nwọn nṣe nihin.

10 Bẹ̃ni mo wọle, mo si ri; si kiye si i, gbogbo aworan ohun ti nrakò, ati ẹranko irira, ati gbogbo oriṣa ile Israeli li a yá li aworan lara ogiri yika kiri.

11 Adọrin ọkunrin ninu awọn agbà ile Israeli si duro niwaju wọn, Jaasania ọmọ Ṣafani si duro lãrin wọn, olukuluku pẹlu awo turari lọwọ rẹ̀; ẹ̃fin ṣiṣu dùdu ti turari si goke lọ.

12 Nigbana li o si wi fun mi pe, Ọmọ enia iwọ ri ohun ti awọn agbà ile Israeli nṣe li okunkùn, olukuluku ninu iyará oriṣa tirẹ̀? nitori nwọn wipe, Oluwa kò ri wa; Oluwa ti kọ̀ aiye silẹ.

13 O si wi fun mi pe, Tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o tobi jù yi ti nwọn nṣe.

14 Nigbana li o mu mi wá si ilẹkun ẹnu-ọ̀na ile Oluwa, ti o wà nihà ariwa; si kiye si i, awọn obinrin joko nwọn nsọkun fun Tammusi.

15 Nigbana li o sọ fun mi pe, Iwọ ri eyi, Iwọ ọmọ enia? tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o tobi ju wọnyi lọ.

16 O si mu mi wá si inu agbala ile Oluwa, si kiye si i, li ẹnu-ọ̀na tempili Oluwa, lãrin iloro ati pẹpẹ, ni iwọ̀n ọkunrin mẹ̃dọgbọ̀n wà, ti nwọn kẹ̀hin si tẹmpili Oluwa, ti nwọn si kọju si ila-õrùn; nwọn si foribalẹ fun õrun si ila-õrun.

17 Nigbana li o wi fun mi pe, Iwọ ri eyi, ọmọ enia? ohun kekere ni fun ile Juda lati ṣe ohun irira ti nwọn nṣe nihin? nitori nwọn fi ìwa-ipa kún ilẹ na, nwọn si ti pada lati mu mi binu, si kiye si i, nwọn tẹ̀ ẹka-igi bọ imú wọn.

18 Emi pẹlu yio si fi irúnu ba wọn lò: oju mi kì yio dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: ati bi o tilẹ ṣepe nwọn fi ohùn rara kigbe li eti mi, sibẹ emi kì yio gbọ́ ti wọn.