1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2 Ọmọ enia, kini igi ajara fi ju igikigi lọ, tabi ju ẹka ti o wà lãrin igi igbo?
3 A ha le mu igi lara rẹ̀ ṣe iṣẹkiṣẹ? tabi enia le mu ẽkàn lara rẹ̀ lati fi ohunkohun kọ́ sori rẹ̀.
4 Kiyesi i, a jù u sinu iná bi igi, iná si jo ipẹkun rẹ̀ mejeji, ãrin rẹ̀ si jona. O ha yẹ fun iṣẹkiṣẹ bi?
5 Kiyesi i, nigbati o wà li odidi, kò yẹ fun iṣẹ kan: melomelo ni kì yio si yẹ fun iṣẹkiṣẹ, nigbati iná ba ti jo o, ti o si jona?
6 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Bi igi ajara lãrin igi igbó, ti mo ti fi fun iná bi igi, bẹ̃ni emi o fi ara Jerusalemu ṣe.
7 Emi o si doju mi kọ wọn, nwọn o jade kuro ninu iná kan, iná miran yio si jo wọn, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo ba dojukọ wọn.
8 Emi o si sọ ilẹ na di ahoro, nitori ti nwọn ti dẹṣẹ, ni Oluwa Ọlọrun wi.