Esek 40 YCE

1 LI ọdun kẹ̃dọgbọn oko-ẹrú wa, ni ibẹ̀rẹ ọdun na, li ọjọ ikẹwa oṣù, li ọdun ikẹrinla lẹhin igbati ilu fọ́, li ọjọ na gan, ọwọ́ Oluwa wà lara mi, o si mu mi wá sibẹ na.

2 Ninu iran Ọlọrun li o mu mi wá si ilẹ Israeli, o si gbe mi ka oke giga kan, lori eyiti kikọ ilu wà ni iha gusu.

3 O si mu mi wá sibẹ, si kiyesi i, ọkunrin kan mbẹ, ẹniti irí rẹ̀ dabi irí bàba, pẹlu okùn ọ̀gbọ li ọwọ́ rẹ̀, ati ije iwọ̀nlẹ; on si duro ni ẹnu-ọ̀na.

4 Ọkunrin na si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi oju rẹ wò, ki o si fi eti rẹ gbọ́, ki o si gbe ọkàn rẹ le ohun gbogbo ti emi o fi han ọ; nitori ka ba le fi wọn han ọ li a ṣe mu ọ wá ihinyi: sọ ohun gbogbo ti o ri fun ile Israeli.

5 Si kiye si i, ogiri kan mbẹ lode ile na yika, ije iwọ̀nlẹ kan si mbẹ lọwọ ọkunrin na, igbọnwọ mẹfa, nipa igbọnwọ ati ibú atẹlẹwọ kan: o si wọ̀n ibú ile na, ije kan; ati giga rẹ̀, ije kan.

6 Nigbana li o wá si ẹnu-ọ̀na ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si gùn oke atẹ̀gun na lọ, o si wọ̀n iloro ẹnu ọ̀na, ti o jẹ ije kan ni ibú; ati iloro miran ti ẹnu-ọ̀na na, ti o jẹ ije kan ni ibú.

7 Yará kékèké si jẹ ije kan ni gigùn, ati ije kan ni ibú; ati lãrin yará kékèké igbọnwọ marun; àtẹwọ ẹnu-ọ̀na lẹba iloro ẹnu-ọ̀na ti inu si jẹ ije kan.

8 O si wọ̀n iloro ẹnu-ọ̀na ti inu, ije kan.

9 O si wọ̀n iloro ẹnu-ọ̀na, igbọnwọ mẹjọ; ati atẹrigba rẹ̀, igbọnwọ meji-meji; iloro ti ẹnu-ọ̀na na si mbẹ ninu.

10 Ati yará kékèké ẹnu-ọ̀na ti ọ̀na ila-õrun jẹ mẹta nihà ìhin, ati mẹta nihà ọhún; awọn mẹtẹta jẹ ìwọn kanna: awọn atẹrigba na jẹ ìwọn kanna niha ìhin ati niha ọhún.

11 O si wọ̀n ibu abawọle ẹnu-ọ̀na na, igbọnwọ mẹwa; ati gigùn ẹnu-ọ̀na na, igbọnwọ mẹtala.

12 Àye ti si mbẹ niwaju awọn yará kékèké na jẹ igbọnwọ kan nihà ìhin, àye na si jẹ igbọnwọ kan nihá ọhún; awọn yará kékèké na si jẹ igbọnwọ mẹfa nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹfa niha ọhún.

13 O si wọ̀n ẹnu-ọ̀na na lati orule yará kékèké kan lọ de orule miran: ibú rẹ jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọn, ilẹkùn dojukọ ilẹkùn.

14 O si ṣe atẹrigba ọlọgọta igbọnwọ, ani titi de atẹrigba àgbalá yi ẹnu-ọ̀na na ka.

15 Lati iwaju ẹnu-ọ̀na àtẹwọ titi fi de iwaju iloro ẹnu-ọ̀na ti inu, adọta igbọnwọ.

16 Awọn ferese tõro si mbẹ lara yará kékèké na, ati lara atẹrigba wọn ninu ẹnu-ọ̀na niha gbogbo ati pẹlu yará iloro: ferese pupọ si mbẹ niha inu gbogbo: igi ọpẹ si mbẹ lara olukuluku atẹrigbà.

17 O si mu mi wá si agbala ode, si kiyesi i, ọ̀pọlọpọ yará mbẹ nibẹ, a si fi okuta tẹ́ agbala na niha gbogbo: ọgbọ̀n yará ni mbẹ lori okuta itẹlẹ na.

18 Ati okuta itẹlẹ ti iha ẹnu-ọ̀na na ti o kọju si gigun ẹnu-ọ̀na, ani okuta itẹlẹ isalẹ.

19 O si wọ̀n ibú rẹ̀ lati iwaju ẹnu-ọ̀na isalẹ titi fi de iwaju àgbala inu ti ode, ọgọrun igbọnwọ niha ila-õrun ati niha ariwa.

20 Ẹnu-ọ̀na àgbala ode ti o kọju si ariwa, o wọ̀n gigun rẹ̀, ati ibu rẹ̀.

21 Awọn yará kékèké ibẹ̀ jẹ mẹta niha ìhin, mẹta nihà ọhun; awọn atẹrigba ibẹ ati iloro ibẹ jẹ gẹgẹ bi ìwọn ẹnu-ọ̀na ekini: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n.

22 Ati fèrese wọn, ati iloro wọn, ati igi ọpẹ wọn jẹ gẹgẹ bi ìwọn ti ẹnu-ọ̀na ti o kọju si ọ̀na ila-õrun; nwọn si ba atẹgun meje gùn oke rẹ̀ lọ; awọn iloro na si mbẹ niwaju wọn.

23 Ati ẹnu-ọ̀na agbala inu ti o kọju si ẹnu-ọ̀na ti ariwa, ati ti ila-õrun; o si wọ̀n lati ẹnu-ọ̀na de ẹnu-ọ̀na, ọgọrun igbọnwọ.

24 O si mu mi lọ si ọ̀na gusù, si kiye si i, ẹnu-ọ̀na kan mbẹ li ọ̀na gusù: o si wọ̀n awọn atẹrigba wọn, ati ìloro wọn gẹgẹ bi ìwọn wọnyi.

25 Fèrese pupọ si mbẹ ninu rẹ̀ ati ninu iloro wọn yika, bi ferese wọnni: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọn.

26 Atẹ̀gun meje ni mbẹ lati bá gùn oke rẹ̀, ati awọn iloro rẹ̀ si mbẹ niwaju wọn: o si ni igi ọpẹ, ọkan nihà ìhin, ati ọkan nihà ọhún, lara awọn atẹrigbà rẹ̀.

27 Ati ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu mbẹ li ọ̀na gusu; o si wọ̀n lati ẹnu-ọ̀na de ẹnu-ọ̀na li ọ̀na gusu, ọgọrun igbọnwọ.

28 O si mu mi wá si agbalá ti inu nipa ẹnu-ọ̀na gusu: o si wọ̀n ẹnu-ọ̀na gusu na gẹgẹ bi ìwọn wọnyi;

29 Ati awọn yará kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese pupọ̀ si mbẹ nibẹ ati ni iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú.

30 Awọn iloro ti mbẹ yika jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n ni gigùn, ati igbọnwọ marun ni ibú.

31 Awọn iloro rẹ̀ mbẹ nihà agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigbà rẹ̀: abágòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ.

32 O si mu mi wá si agbalá ti inu nihà ọ̀na ila-õrun: o si wọ̀n ẹnu-ọ̀na na, gẹgẹ bi iwọn wọnyi.

33 Ati yara kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, jẹ gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese si mbẹ ninu rẹ̀ ati ninu awọn iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, ati igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú.

34 Awọn iloro rẹ̀ mbẹ nihà agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigbà rẹ̀, nihà ìhin, ati nihà ọ̀hun: abagòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ.

35 O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na ariwa, o si wọ̀n ọ gẹgẹ bi ìwọn wọnyi;

36 Awọn yará kékèké rẹ̀, atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, ati ferese rẹ̀ yika: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n.

37 Ati atẹrigba rẹ̀ mbẹ niha agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigba rẹ̀, niha ìhin, ati niha ọ̀hun: abagòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ.

38 Ati yàra ati abáwọle rẹ̀ wà nihà atẹrigbà ẹnu-ọ̀na na, nibiti nwọn ima wẹ̀ ọrẹ ẹbọ sisun.

39 Ati ni iloro ẹnu-ọ̀na na tabili meji mbẹ nihà ìhin, ati tabili meji nihà ọ̀hun, lati ma pa ẹran ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja lori wọn.

40 Ati ni ihà ode, bi a ba nlọ si àbáwọle ẹnu-ọ̀na ariwa, ni tabili meji mbẹ; ati nihà miran, ti iṣe iloro ẹnu-ọ̀na, ni tabili meji mbẹ.

41 Tabili mẹrin mbẹ nihà ìhin, tabili mẹrin si mbẹ nihà ọ̀hun, nihà ẹnu-ọ̀na; tabili mẹjọ, lori eyiti nwọn a ma pa ẹran ẹbọ wọn.

42 Tabili mẹrin na si jẹ ti okuta gbigbẹ́ fun ọrẹ ẹbọ sisun, igbọnwọ kan on ãbọ ni gigùn, ati igbọnwọ kan on ãbọ ni ibú, ati igbọnwọ kan ni giga: lori eyiti nwọn a si ma kó ohun-elò wọn le, ti nwọn ifi pa ọrẹ ẹbọ sisun ati ẹran ẹbọ.

43 Ati ninu ni ìwọ ẹlẹnu meji, oníbu atẹlẹwọ kan, ti a kàn mọ ọ yika: ati lori awọn tabili na ni ẹran ọrẹ gbe wà.

44 Ati lode ẹnu-ọ̀na ti inu ni yará awọn akọrin gbe wà, ninu agbala ti inu, ti mbẹ ni ihà ẹnu-ọ̀na ariwa; oju wọn si wà li ọ̀na gusu: ọkan ni iha ẹnu-ọ̀na ila-õrun, oju eyiti mbẹ li ọ̀na ariwa.

45 O si wi fun mi pe, Yàrá yi, ti oju rẹ̀ mbẹ li ọ̀na gusu, ni fun awọn alufa, awọn olutọjú iṣọ ile na.

46 Yará ti oju rẹ̀ mbẹ li ọ̀na ariwa, ni fun awọn alufa, awọn olutọjú iṣọ pẹpẹ na; awọn wọnyi li awọn ọmọ Sadoku ninu awọn ọmọ Lefi, ti nwọn ima sunmọ Oluwa lati ṣe iranṣẹ fun u.

47 O si wọ̀n agbalá na, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn, ọgọrun igbọnwọ ni ibú, igun mẹrin lọgbọgba; ati pẹpẹ ti mbẹ niwaju ile na.

48 O si mu mi wá si iloro ile na, o si wọ̀n opo iloro na, igbọnwọ marun nihà ìhin, ati igbọnwọ marun nihà ọ̀hun: ibu ẹnu-ọ̀na na si jẹ igbọnwọ mẹta nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹta nihà ọ̀hun.

49 Gigùn iloro na jẹ ogún igbọnwọ, ibú rẹ̀ igbọnwọ mọkànla; o si mu mi wá si atẹ̀gun ti nwọn ifi ba gokè rẹ̀: ọwọ̀n pupọ̀ si mbẹ nihà ibi atẹrigbà, ọkan nihin, ati ọkan lọhun.