1 ẸMI si gbe mi soke, o si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na ile Oluwa ti ilà õrun ti o kọju siha ilà-õrùn, si kiyesi i, ọkunrin mẹdọgbọn wà nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na; ninu awọn ẹniti mo ri Jaasania ọmọ Assuri, ati Pelatia ọmọ Benaia, awọn ijoyè awọn enia.
2 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, awọn ọkunrin ti npete ikà ni wọnyi, ti nsi gbimọ̀ buburu ni ilu yi:
3 Awọn ti o wipe, Kò sunmọ tosi; ẹ jẹ ki a kọ ile: ilu yi ni ìgba, awa si ni ẹran.
4 Nitorina sọtẹlẹ si wọn, Ọmọ enia, sọtẹlẹ.
5 Ẹmi Oluwa si bà le mi, o si wi fun mi pe, Sọ̀rọ; Bayi li Oluwa wi; Bayi li ẹnyin ti wi, Ile Israeli, nitoriti mo mọ̀ olukuluku ohun ti o wá si inu nyin.
6 Ẹnyin ti sọ okú nyin di pupọ̀ ni ilu yi, ẹnyin si ti fi okú kún igboro rẹ̀,
7 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Awọn okú nyin ti ẹnyin ti tẹ́ si ãrin rẹ̀, awọn ni ẹran, ilu yi si ni ìgba; ṣugbọn emi o mu nyin jade kuro lãrin rẹ̀.
8 Oluwa Ọlọrun wipe, Ẹnyin ti bẹ̀ru idà, emi o si mu idà wa sori nyin.
9 Emi o si mu nyin kuro lãrin rẹ̀, emi o si fi nyin le awọn alejo lọwọ, emi o si mu idajọ ṣẹ si nyin lara.
10 Nipa idà li ẹnyin o ṣubu; emi o ṣe idajọ nyin li agbegbe Israeli; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
11 Ilu yi ki yio ṣe ìgba fun nyin, bẹ̃ni ẹnyin kì yio jẹ ẹran lãrin rẹ̀; ṣugbọn emi o ṣe idajọ nyin li agbegbe Israeli.
12 Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa: nitoriti ẹnyin kò rìn ninu aṣẹ mi, bẹ̃ni ẹnyin kò mu idajọ mi ṣẹ, ṣugbọn ẹnyin ti hu ìwa awọn keferi ti o wà yi nyin ka.
13 O si ṣe, nigbati mo sọtẹlẹ, Pelatia ọmọ Benaiah kú. Mo si dojubolẹ, mo si fi ohùn rara kigbe, mo si wipe, A! Oluwa Ọlọrun, iwọ o ha ṣe aṣetan iyokù Israeli bi?
14 Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
15 Ọmọ enia, awọn ará rẹ, ani awọn ará rẹ, awọn ọkunrin ninu ibatan rẹ, ati gbogbo ile Israeli patapata, ni awọn ti awọn ara Jerusalemu ti wi fun pe, Ẹ jina si Oluwa; awa ni a fi ilẹ yi fun ni ini.
16 Nitorina wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Bi mo tilẹ ti tá wọn nù réré lãrin awọn keferi; bi mo si ti tú wọn ka lãrin ilẹ pupọ, sibẹ emi o jẹ ibi mimọ́ kekere fun wọn ni ilẹ ti wọn o de.
17 Nitorina wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, Emi tilẹ kó nyin kuro lọdọ awọn orilẹ-ède; emi o si kó nyin jọ lati ilẹ ti a ti tú nyin ká si, emi o si fun nyin ni ilẹ Israeli.
18 Nwọn o si wá sibẹ, nwọn o si mu gbogbo ohun irira rẹ̀ ati gbogbo ohun ẽri rẹ̀ kuro nibẹ.
19 Emi o si fun wọn li ọkàn kan, emi o si fi ẹmi titun sinu nyin; emi o si mu ọkàn okuta kuro lara wọn, emi o si fun wọn li ọkàn ẹran:
20 Ki wọn le rìn ninu aṣẹ mi, ki wọn si le pa ilana mi mọ, ki nwọn si ṣe wọn: nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.
21 Ṣugbọn bi o ṣe ti awọn ti ọkàn wọn nrìn nipa ọkàn ohun irira ati ohun ẽri wọn, Emi o sẹsan ọ̀na wọn sori ara wọn, li Oluwa Ọlọrun wi.
22 Awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke, pelu awọn kẹkẹ́ lẹgbẹ wọn, ogo Ọlọrun Israeli si wà lori wọn loke.
23 Ogo Oluwa si goke lọ kuro lãrin ilu na; o si duro lori oke-nla, ti o wà nihà ila-õrùn ilu na.
24 Lẹhin na ẹmi gbe mi soke, o si mu mi wá si Kaldea li ojuran, nipa Ẹmi Ọlọrun sọdọ awọn ti igbekun. Bẹ̃ni iran ti mo ti ri lọ kuro lọdọ mi.
25 Mo si sọ gbogbo ohun ti Oluwa ti fi hàn mi fun awọn ti igbekùn.