Esek 20 YCE

1 O si ṣe ni ọdun keje ni oṣu karun, ni ọjọ kẹwa oṣu, ti awọn kan ninu awọn àgba Israeli wá ibere lọwọ Oluwa, nwọn si joko niwaju mi.

2 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

3 Ọmọ enia, sọ fun awọn àgba Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Lati bere lọwọ mi ni ẹ ṣe wá? Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere.

4 Iwọ o ha dá wọn lẹjọ bi, ọmọ enia, iwọ o ha da wọn lẹjọ? jẹ ki wọn mọ̀ ohun-irira baba wọn.

5 Si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ni ọjọ na nigbati mo yàn Israeli, ti mo si gbe ọwọ́ mi soke si iru-ọmọ ile Jakobu, ti mo si sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn ni ilẹ Egipti, nigbati mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, wipe, Emi ni Oluwa Ọlọrun nyin:

6 Ni ọjọ ti mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti si ilẹ ti mo ti wò silẹ fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ.

7 Mo si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ninu nyin gbe irira oju rẹ̀ junù, ẹ má si ṣe fi oriṣa Egipti sọ ara nyin di aimọ́: emi ni Oluwa Ọlọrun nyin.

8 Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si mi, nwọn kò si fẹ fi eti si mi: olukuluku wọn kò gbe ohun-irira oju wọn junù, bẹ̃ni nwọn kò kọ oriṣa Egipti silẹ: nigbana ni mo wipe, emi o da irúnu mi si wọn lori, lati pari ibinu mi si wọn lãrin ilẹ Egipti.

9 Ṣugbọn mo ṣiṣẹ nitori orukọ mi; ki o má bà bajẹ niwaju awọn keferi, lãrin ẹniti nwọn wà, loju ẹniti mo sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn, ni mimu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti.

10 Mo si jẹ ki wọn lọ kuro ni ilẹ Egipti, mo si mu wọn wá si aginju.

11 Mo si fi aṣẹ mi fun wọn, mo si fi idajọ mi hàn wọn, eyiti bi enia kan ba ṣe, yio tilẹ yè ninu wọn.

12 Pẹlupẹlu mo si fun wọn ni ọjọ isimi mi, lati ṣe àmi lãrin t'emi ti wọn, ki nwọn ki o le mọ̀ pe emi ni Oluwa ti o yà wọn si mimọ́.

13 Ṣugbọn ile Israeli ṣọ̀tẹ si mi ni aginjù: nwọn kò rìn ni aṣẹ mi, nwọn si gàn idajọ mi, eyiti bi enia kan ba ṣe, on o tilẹ yè ninu wọn; ati ọjọ isimi mi ni wọn tilẹ bajẹ gidigidi: nigbana ni mo wipe, emi o dà irúnu mi si wọn lori li aginju, lati pa wọn run.

14 Ṣugbọn mo ṣiṣẹ nitori orukọ mi, ki o má ba di ibajẹ niwaju awọn keferi, loju ẹniti mo mu wọn jade.

15 Pẹlupẹlu mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn ni aginju pe emi kò ni mu wọn de ilẹ ti mo ti fi fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ;

16 Nitoriti nwọn gàn idajọ mi, nwọn kò si rìn ninu aṣẹ mi, ṣugbọn nwọn bà ọjọ isimi mi jẹ: nitoripe ọkàn wọn tẹ̀le oriṣa wọn.

17 Ṣugbọn oju mi dá wọn si ki emi má ba pa wọn, bẹ̃ni emi kò ṣe wọn li aṣetan ni aginju.

18 Ṣugbọn mo sọ fun awọn ọmọ wọn li aginju pe, Ẹ máṣe rìn ninu aṣẹ baba nyin, ẹ má si ṣe kiyesi idajọ wọn, ẹ má si fi oriṣa wọn sọ ara nyin di aimọ́:

19 Emi ni Oluwa Ọlọrun nyin: ẹ rìn ninu aṣẹ mi, ẹ si pa idajọ mi mọ, ẹ si ṣe wọn;

20 Ẹ si bọ̀wọ fun ọjọ isimi mi; nwọn o si jẹ àmi lãrin t'emi ti nyin, ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi ni Oluwa Ọlọrun nyin.

21 Ṣugbọn awọn ọmọ na ṣọ̀tẹ si mi: nwọn kò rìn ninu aṣẹ mi, bẹ̃ni nwọn kò pa idajọ mi mọ lati ṣe wọn, eyiti bi enia kan ba ṣe, yio tilẹ yè ninu wọn; nwọn bà ọjọ isimi mi jẹ: mo si wipe, Emi o da irúnu mi sori wọn, lati pari ibinu mi sori wọn li aginju.

22 Ṣugbọn mo fà ọwọ́ mi sẹhìn, mo si ṣiṣẹ nitori orukọ mi, ki o má bà di ibajẹ li oju awọn keferi, loju ẹniti mo mu wọn jade.

23 Mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn pẹlu li aginju, lati tú wọn ka lãrin awọn keferi, ati lati fọ́n wọn ká ilẹ gbogbo;

24 Nitoripe nwọn kò mu idajọ mi ṣẹ, ṣugbọn nwọn kẹgàn aṣẹ mi, nwọn si ti bà ọjọ isimi mi jẹ, oju wọn si wà lara oriṣa baba wọn.

25 Nitorina mo fun wọn ni aṣẹ pẹlu ti kò dara, ati idajọ nipa eyiti wọn kì yio fi le yè;

26 Emi si bà wọn jẹ́ ninu ẹ̀bun ara wọn, nitipe nwọn mu gbogbo awọn akọbi kọja lãrin iná, ki emi ba le sọ wọn di ahoro, ki nwọn le bà mọ̀ pe emi ni Oluwa.

27 Nitorina, ọmọ enia, sọ fun ile Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ninu eyi pẹlu baba nyin ti sọ̀rọ odi si mi, nitipe nwọn ti dẹṣẹ si mi.

28 Nitori nigbati mo ti mu wọn de ilẹ, niti eyiti mo gbé ọwọ́ mi soke lati fi i fun wọn, nigbana ni nwọn ri olukuluku oke giga, ati gbogbo igi bibò, nwọn si ru ẹbọ wọn nibẹ, nwọn si gbe imunibinu ọrẹ wọn kalẹ nibẹ: nibẹ pẹlu ni nwọn ṣe õrun didùn wọn, nwọn si ta ohun-ọrẹ mimu silẹ nibẹ.

29 Nigbana ni mo wi fun wọn pe, Kini ibi giga ti ẹnyin nlọ na? Orukọ rẹ̀ ni a si npe ni Bama titi o fi di oni oloni.

30 Si wi fun ile Israeli pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; A bà nyin jẹ́ gẹgẹ bi baba nyin? ẹnyin si ṣe agbère gẹgẹ bi ohun-irira wọn?

31 Nitori nigbati ẹnyin nta ọrẹ nyin, nigbati ẹnyin mu ọmọ nyin kọja lãrin iná, ẹnyin fi oriṣa nyin bà ara nyin jẹ́, ani titi o fi di oni oloni: ẹnyin o ha si bere lọwọ mi, Iwọ ile Israeli? Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere.

32 Eyiti o si wá si iye nyin kì yio wà rara; ti ẹnyin wipe, Awa o wà bi awọn keferi, gẹgẹ bi idile awọn orilẹ-ède lati bọ igi ati okuta.

33 Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, nitõtọ nipa agbara ọwọ́, ati ninà apa, pẹlu irúnu ti a dà jade li emi o fi jọba lori nyin:

34 Emi o si mu nyin jade kuro lãrin awọn enia, emi o si ṣà nyin jọ lati ilẹ ti a ti tú nyin ka si, pẹlu ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ati pẹlu irúnu ti a dà jade.

35 Emi o si mu nyin wá si aginju awọn enia, nibẹ ni emi o si bá nyin rojọ lojukoju.

36 Gẹgẹ bi mo ti dá awọn baba nyin lẹjọ li aginju ilẹ Egipti, bẹ̃ni emi o bá nyin rojọ, ni Oluwa Ọlọrun wi.

37 Emi o si mu nyin kọja labẹ ọpá, emi o si mu nyin wá si ìde majẹmu:

38 Emi o si ṣà awọn ọlọ̀tẹ kuro lãrin nyin, ati awọn olurekọja, emi o mu wọn jade kuro ni ilẹ ti wọn gbe ṣe atipo, nwọn kì yio si wọ ilẹ Israeli: ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa.

39 Bi o ṣe ti nyin, ile Israeli, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi, Ẹ lọ, olukuluku sìn oriṣa rẹ̀, ati lẹhin eyi pẹlu, bi ẹnyin kì yio ba fi eti si mi: ṣugbọn ẹ máṣe fi ẹ̀bun nyin ati oriṣa nyin bà orukọ mimọ́ mi jẹ́ mọ.

40 Nitori lori oke mimọ́ mi, lori oke giga Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi, nibẹ ni gbogbo ile Israeli, gbogbo wọn ni ilẹ na, yio sìn mi: nibẹ ni emi o gbà wọn, nibẹ ni emi o si bere ẹbọ nyin, ati ọrẹ akọso nyin, pẹlu ohun mimọ́ nyin.

41 Emi o gbà nyin pẹlu õrùn didùn nyin, nigbati mo mu nyin jade kuro lãrin awọn enia, ti mo si ko nyin jọ lati ilẹ gbogbo nibiti a gbe ti tú nyin ká si; a o si yà mi si mimọ́ ninu nyin niwaju awọn keferi.

42 Ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa, nigbati emi o mu nyin de ilẹ Israeli, si ilẹ niti eyiti o gbe ọwọ́ mi soke lati fi fun awọn baba nyin.

43 Nibẹ li ẹnyin o ranti ọ̀na nyin, ati gbogbo iṣe nyin, ninu eyiti a ti bà nyin jẹ; ẹ o si sú ara nyin loju ara nyin nitori gbogbo buburu ti ẹnyin ti ṣe.

44 Ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa, nigbati emi ti ṣiṣẹ pẹlu nyin nitori orukọ mi, ki iṣe gẹgẹ bi ọ̀na buburu nyin, tabi gẹgẹ bi iṣe bibajẹ nyin, ẹnyin ile Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi.

45 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

46 Ọmọ enia, kọju rẹ siha gusù, si sọ ọ̀rọ rẹ siha gusù, si sọtẹlẹ si igbó oko gusù;

47 Si wi fun igbó gusù pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa; bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o da iná kan ninu rẹ, yio si jo olukuluku igi tutù ninu rẹ, ati olukuluku igi gbigbẹ: jijo ọwọ́ iná na ni a kì yio pa, ati gbogbo oju lati gusu de ariwa ni a o sun ninu rẹ̀.

48 Gbogbo ẹran-ara ni yio si ri i pe emi Oluwa li o ti da a, a kì yio pa a.

49 Nigbana ni mo wipe, A! Oluwa Ọlọrun, nwọn wi niti emi pe, Owe ki o npa yi?