1 O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣu ikini, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
2 Ọmọ enia, nitoriti Tire ti sọ̀rọ si Jerusalemu, pe, Aha, a fọ́ eyiti iṣe bode awọn orilẹ-ède: a yi i pada si mi, emi o di kikún, on di ahoro:
3 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, mo doju kọ ọ, iwọ Tire, emi o si jẹ ki orilẹ-ède pupọ dide si ọ, gẹgẹ bi okun ti igbé ríru rẹ̀ soke.
4 Nwọn o si wó odi Tire lulẹ, nwọn o si wó ile iṣọ́ rẹ̀ lulẹ; emi o si há erùpẹ rẹ̀ kuro lara rẹ̀, emi o si ṣe e bi ori apata.
5 Yio jẹ ibi ninà awọ̀n si lãrin okun: nitori mo ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi: yio si di ikogun fun awọn orilẹ-ède.
6 Ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ ti o wà li oko, li a o fi idà pa; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
7 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu Nebukadnessari ọba Babiloni, ọba awọn ọba, wá si Tire, lati ariwa, pẹlu ẹṣin, ati kẹkẹ́ ogun, ati ẹlẹṣin, ati ẹgbẹ́, ati enia pupọ.
8 Yio fi idà pa awọn ọmọbinrin rẹ li oko: yio si kọ kũkũ tì ọ, yio si mọ odi tì ọ, yio si gbe apata soke si ọ.
9 Yio si gbe ohun-ẹrọ ogun tì odi rẹ, yio si fi ãke rẹ̀ wó ile-iṣọ́ rẹ lulẹ.
10 Nitori ọ̀pọ awọn ẹṣin rẹ̀ ẽkuru wọn yio bò ọ: odi rẹ yio mì nipa ariwo awọn ẹlẹṣin, ati kẹkẹ́, ati kẹkẹ́ ogun, nigbati yio wọ̀ inu odi rẹ lọ, gẹgẹ bi enia ti wọ̀ inu ilu ti a fọ́.
11 Pátakò ẹṣin rẹ̀ ni yio fi tẹ̀ gbogbo ìta rẹ mọlẹ: on o fi idà pa awọn enia rẹ, ati ọwọ̀n lile rẹ yio wó lulẹ.
12 Nwọn o si fi ọrọ̀ rẹ ṣe ikogun, ati òwo rẹ ṣe ijẹ ogun; nwọn o si wo odi rẹ lulẹ, nwọn o si bà ile rẹ daradara jẹ: nwọn o si ko okuta rẹ, ati ìti igi-ìkọle rẹ, ati erùpẹ rẹ, dà si ãrin omi.
13 Emi o si mu ariwo orin rẹ dakẹ; ati iró dùru rẹ li a kì yio gbọ́ mọ.
14 Emi o si ṣe ọ bi ori apáta; iwọ o si jẹ ibi lati nà awọ̀n le lori; a kì yio kọ́ ọ mọ: nitori emi Oluwa li o ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi.
15 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi si Tire; awọn erekùṣu kì yio ha mì-titi nipa iró iṣubu rẹ, nigbati awọn ti o gbọgbẹ́ kigbe, nigbati a ṣe ipani li ãrin rẹ?
16 Nigbana li awọn ọmọ-alade okun yio sọ̀kalẹ kuro lori itẹ́ wọn, nwọn o si pa aṣọ igunwà wọn tì, nwọn o si bọ́ ẹ̀wu oniṣẹ-ọnà wọn: nwọn o fi ìwariri bò ara wọn; nwọn o joko lori ilẹ, nwọn o si warìri nigba-gbogbo, ẹnu o si yà wọn si ọ.
17 Nwọn o si pohunrere-ẹkun fun ọ, nwọn o si wi fun ọ pe, Bawo li ati pa ọ run, iwọ ti awọn èro okun ti ngbe inu rẹ̀, ilu olokikí, ti o lagbara li okun, on ati awọn ti o gbe inu rẹ̀, ẹniti o mu ẹ̀ru wọn wá sara gbogbo awọn ti o pàra ninu rẹ!
18 Nisisiyi ni awọn erekùṣu yio warìri li ọjọ iṣubu rẹ; nitõtọ, awọn erekùṣu ti o wà ninu okun li a o yọ lẹnu nigba atilọ rẹ.
19 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nigbati emi o sọ ọ di ahoro ilu, gẹgẹ bi ilu wọnni ti a kò gbe inu wọn; nigbati emi o si mu ibú wá sori rẹ, ati omi nla yio si bò ọ.
20 Nigbati emi o bá mu ọ walẹ pẹlu awọn ti o sọkalẹ sinu ihò, pẹlu awọn enia igbãni, ti emi o si gbe ọ kà ibi isalẹ ilẹ aiye, ni ibi ahoro igbãni, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò, ki a máṣe gbe inu rẹ mọ́: emi o si gbe ogo kalẹ ni ilẹ awọn alãye;
21 Emi o si ṣe ọ ni ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́: bi a tilẹ wá ọ, sibẹ a kì yio tun ri ọ mọ́, li Oluwa Ọlọrun wi.