1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe.
2 Ọmọ enia, kọju rẹ sihà Jerusalemu, si sọ ọ̀rọ si ibi mimọ́ wọnni, si sọtẹlẹ si ilẹ Israeli.
3 Si wi fun ilẹ Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, mo dojukọ ọ, emi o si fa idà mi yọ kuro li akọ̀ rẹ̀, emi o si ke olododo ati enia buburu kuro lãrin rẹ.
4 Njẹ bi o ti ṣe pe emi o ke olododo ati enia buburu kuro lãrin rẹ, nitorina ni idà mi o ṣe jade lọ lati inu àkọ rẹ̀, si gbogbo ẹran-ara, lati gusù de ariwa:
5 Ki gbogbo ẹran-ara le mọ̀ pe emi Oluwa ti fà idà mi yọ kuro li àkọ rẹ̀: kì yio pada mọ lai.
6 Nitorina kerora, iwọ ọmọ enia, pẹlu ṣiṣẹ́ ẹgbẹ́ rẹ, ati pẹlu ikerora kikoro niwaju wọn.
7 Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi fun ọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nkerora? iwọ o dahùn wipe, Nitori ihìn na; nitoripe o de: olukuluku ọkàn ni yio yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yio si ṣe ailokun, olukuluku ẹmi yio si dakú, gbogbo ẽkún ni yio ṣe ailagbara bi omi: kiyesi i, o de, a o si mu u ṣẹ, ni Oluwa Ọlọrun wi.
8 Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe,
9 Ọmọ enia, sọtẹlẹ, si wipe, Bayi li Oluwa wi; Wipe, Idà, idà ti a pọ́n, ti a si dán pẹlu:
10 A pọ́n ọ lati pa enia pupọ; a dán a lati ma kọ màna: awa o ha ma ṣe ariyá? ọgọ ọmọ mi, o gàn gbogbo igi.
11 On si ti fi i le ni lọwọ lati dán, ki a ba le lò o; idà yi li a pọ́n, ti a si dán, lati fi i le ọwọ́ apani.
12 Kigbe, ki o si wu, ọmọ enia: nitori yio wá sori awọn enia mi, yio wá sori gbogbo ọmọ-alade Israeli: ìbẹru nla yio wá sori awọn enia mi nitori idà na: nitorina lu itan rẹ.
13 Nitoripe idanwo ni, ki si ni bi idà na gàn ọgọ na? kì yio si mọ́, ni Oluwa Ọlọrun wi.
14 Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ, si fi ọwọ́ lu ọwọ́ pọ̀, si jẹ ki idà ki o ṣẹ́po nigba kẹta, idà awọn ti a pa: idà awọn enia nla ti a pa ni, ti o wọ inu yara ikọ̀kọ wọn lọ.
15 Mo ti nà ṣonṣo idà si gbogbo bode wọn: ki aiya wọn le dakú, ati ki ahoro wọn le di pupọ: ã! a ti ṣe e dán, a ti pọ́n ọ mú silẹ fun pipa.
16 Iwọ gba ọ̀na kan tabi ọ̀na keji lọ, si apa ọtún tabi si òsi, nibikibi ti iwọ dojukọ.
17 Emi o si fi ọwọ́ lu ọwọ́ pọ̀, emi o si jẹ ki irúnu mi ki o simi: emi Oluwa li o ti wi bẹ̃.
18 Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
19 Iwọ pẹlu, ọmọ enia, yan ọ̀na meji fun ara rẹ, ki idà ọba Babiloni ki o le wá: awọn mejeji yio jade lati ilẹ kanna wá: si yan ibi kan, yàn a ni ikorita ti o lọ si ilu-nla.
20 Yàn ọ̀na kan, ki idà na le wá si Rabba ti awọn ara Ammoni, ati si Juda ni Jerusalemu ti o li odi.
21 Nitori ọba Babiloni duro ni iyàna, lori ọ̀na meji, lati ma lo afọṣẹ: o mì ọfà rẹ̀, o da òriṣa, o wo ẹ̀dọ.
22 Li ọwọ́ ọtún rẹ̀ ni afọṣẹ Jerusalemu wà, lati yan õlù, lati ya ẹnu rẹ̀ ni pipa, lati gbohùn soke pẹlu ariwo, lati yan õlù si bode, lati mọ odi, ati lati kọ ile iṣọ́.
23 Afọ̀ṣẹ na yio si dabi eké fun wọn, loju awọn ti o ti bura fun wọn: ṣugbọn on o mu aiṣedẽde wá si iranti, ki a ba le mu wọn.
24 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe ẹnyin jẹ ki a ranti aiṣedẽde nyin, niti pe a ri irekọja nyin, tobẹ̃ ti ẹ̀ṣẹ nyin hàn, ni gbogbo iṣe nyin: nitoripe ẹnyin wá si iranti, ọwọ́ li a o fi mu nyin.
25 Ati iwọ, alailọ̀wọ ẹni-buburu ọmọ-alade Israeli, ẹniti ọjọ rẹ̀ de, nigba aiṣedẽde ikẹhìn.
26 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Mu fila ọba kuro, si ṣi ade kuro; eyi kò ni jẹ ọkanna: gbe ẹniti o rẹlẹ ga, si rẹ̀ ẹniti o ga silẹ.
27 Emi o bì ṣubu, emi o bì ṣubu, emi o bì i subu, kì yio si si mọ, titi igbati ẹniti o ni i ba de; emi o si fi fun u.
28 Ati iwọ, ọmọ enia, sọtẹlẹ, si wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi niti awọn ara Ammoni, ati niti ẹgàn wọn; ani ki iwọ wipe, Idà na, idà na ti a fà yọ, a ti dán a fun pipa, lati parun lati kọ màna.
29 Nigbati nwọn ri ohun asan si ọ, nigbati nwọn fọ̀ àfọṣẹ eke si ọ, lati mu ọ wá si ọrùn awọn ti a pa, ti ẹni-buburu, ẹniti ọjọ rẹ̀ de, nigbati aiṣedẽde pin.
30 Tun mu ki o pada sinu àkọ rẹ̀! Emi o ṣe idajọ rẹ nibi ti a gbe ṣe ẹdá rẹ, ni ilẹ ibi rẹ.
31 Emi o dà ibinujẹ mi le ọ lori, ninu iná irúnu mi li emi o fẹ si ọ, emi o si fi ọ le awọn eniakenia lọwọ, ti nwọn ni ọgbọn lati parun.
32 Iwọ o jẹ́ igi fun iná; ẹjẹ rẹ yio wà lãrin ilẹ na; a kì yio ranti rẹ mọ: nitori emi Oluwa li o ti wi i.