Esek 9 YCE

Wọ́n Jẹ Jerusalẹmu Níyà

1 O si fi ohùn rara kigbe li eti mi wipe, Mu gbogbo awọn alaṣẹ ilu sunmọ itosi, olukuluku ton ti ohun ija iparun li ọwọ́ rẹ̀.

2 Si kiyesi i, ọkunrin mẹfa jade lati ẹnu ilẹkun oke wá, ti o wà niha ariwa, olukuluku ton ti ohun-ijà ipani li ọwọ́ rẹ̀: ọkunrin kan ninu wọn si wọ aṣọ ọgbọ̀, pẹlu ìwo-tàdawa akọwe li ẹgbẹ́ rẹ̀: nwọn si wọ inu ile, nwọn si duro lẹba pẹpẹ idẹ.

3 Ogo Ọlọrun Israeli si ti goke kuro lori kerubu, eyi ti o ti wà, si iloro ile. O si pe ọkunrin na ti o wọ aṣọ ọgbọ̀, ti o ni ìwo-tàdawa akọwe li ẹgbẹ́ rẹ̀:

4 Oluwa si wi fun u pe, La ãrin ilu já, li ãrin Jerusalemu, ki o si sami si iwaju awọn ọkunrin ti nkẹdùn, ti nwọn si nkigbe nitori ohun irira ti nwọn nṣe lãrin rẹ̀.

5 O si sọ fun awọn iyokù li eti mi, pe, Ẹ tẹ̀ le e la ilu lọ, ẹ si ma kọlù: ẹ má jẹ ki oju nyin dasi, bẹ̃ni ẹ máṣe ṣãnu.

6 Ẹ pa arugbo ati ọmọde patapata, awọn wundia ati ọmọ kekeke ati obinrin; ṣugbọn ẹ máṣe sunmọ ẹnikan lara ẹniti àmi na wà; ẹ si bẹrẹ lati ibi mimọ́ mi. Bẹ̃ni nwọn bẹrẹ lati ọdọ awọn agbà ti o wà niwaju ile.

7 O si wi fun wọn pe, ẹ sọ ile na di aimọ́, ẹ si fi okú kún agbala na: ẹ jade lọ. Nwọn si jade lọ, nwọn si pa enia ni ilu.

8 O si ṣe, nigbati nwọn npa wọn, ti a si fi emi silẹ, mo da oju mi bo ilẹ, mo si kigbe, mo si wipe, Oluwa Ọlọrun, iwọ o ha pa gbogbo awọn iyokù Israeli run, nipa dida irúnu rẹ jade sori Jerusalemu?

9 O si wi fun mi pe, Aiṣedede ile Israeli ati ti Juda pọ̀ gidigidi, ilẹ na si kún fun ẹjẹ, ilu si kún fun iyi-ẹjọ-po, nitori nwọn wipe, Oluwa ti kọ aiye silẹ, Oluwa kò riran.

10 Bi o si ṣe ti emi ni, oju mi kì o dasi, bẹ̃li emi kì o ṣanu, ṣugbọn emi o sán ọ̀na wọn pada si ori wọn.

11 Si kiye si i, ọkunrin ti o wọ aṣọ ọ̀gbọ, ti o ni ìwo-tadawa li ẹgbẹ́ rẹ̀ rohìn, wipe, mo ti ṣe gẹgẹ bi o ti paṣẹ fun mi.