1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
2 Nisisiyi, iwọ ọmọ enia, pohunrere ẹkun fun Tire;
3 Ki o si wi fun Tire pe, Iwọ ti a tẹ̀do si ẹnu-ọ̀na okun, oniṣòwo awọn orilẹ-ède fun ọ̀pọlọpọ erekùṣu, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ Tire, iwọ ti wipe, emi pé li ẹwà.
4 Àlà rẹ wà li ãrin okun, awọn ọ̀mọle rẹ ti mu ẹwà rẹ pé.
5 Nwọn ti fi apako firi ti Seniri kàn gbogbo ọkọ̀ rẹ, nwọn ti mu kedari ti Lebanoni wá lati fi ṣe opó ọkọ̀ fun ọ.
6 Ninu igi oaku ti Baṣani ni nwọn ti fi gbẹ́ àjẹ rẹ; ijoko rẹ ni nwọn fi ehin-erin ṣe pelu igi boksi lati erekuṣu Kittimu wá.
7 Ọ̀gbọ daradara iṣẹ-ọnà lati Egipti wá li eyiti iwọ ta fi ṣe igbokun rẹ; aṣọ aláro ati purpili lati erekusu Eliṣa wá li eyiti a fi bò ọ.
8 Awọn ara ilu Sidoni ati Arfadi ni awọn ara ọkọ̀ rẹ̀: awọn ọlọgbọn rẹ, Iwọ Tire, ti o wà ninu rẹ, li awọn atọkọ̀ rẹ.
9 Awọn àgba Gebali, ati awọn ọlọgbọn ibẹ̀, wà ninu rẹ bi adikọ̀ rẹ: gbogbo ọkọ̀ òkun pẹlu awọn ara ọkọ̀ wọn wà ninu rẹ lati ma ṣòwo rẹ.
10 Awọn ti Persia, ati ti Ludi, ati ti Futi, wà ninu ogun rẹ, awọn ologun rẹ: nwọn fi apata ati ìbori-ogun kọ́ ninu rẹ; nwọn fi ẹwà rẹ hàn.
11 Awọn enia Arfadi, pẹlu awọn ogun rẹ, wà lori odi rẹ yika, ati awọn akọ-jamã wà ni ile-iṣọ rẹ: nwọn fi apata kọ́ sara odi rẹ yika; nwọn ti ṣe ẹwà rẹ pé.
12 Tarṣiṣi ni oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ; pẹlu fadakà, irin, tánganran, ati ojé, nwọn ti ṣòwo li ọja rẹ.
13 Jafani, Tubali, ati Meṣeki, awọn li awọn oniṣòwo rẹ: nwọn ti fi ẹrú ati ohun-elò idẹ ṣòwo li ọjà rẹ.
14 Awọn ti ile Togarma fi ẹṣin, ati ẹlẹṣin ati ibaka ṣòwo li ọjà rẹ.
15 Awọn enia Dedani li awọn oniṣòwo rẹ; ọ̀pọlọpọ erekuṣu ni mba ọ ṣòwo, nwọn mu ehin-erin ati igi eboni wá fun ọ lati rà.
16 Siria li oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ iṣẹ ọwọ́ rẹ: nwọn ntà emeraldi li ọjà rẹ, pẹlu purpili, ati iṣẹ oniṣẹ-ọnà, ati ọ̀gbọ daradara, ati iyùn, ati agate.
17 Juda, ati ilẹ Israeli, awọn li awọn oniṣòwo rẹ, alikama ti Minniti, ati Pannagi, ati oyin, ati ororo, ati balmu, ni nwọn fi ná ọjà rẹ.
18 Damasku li oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ ohun ọjà ti o ṣe, nitori ọ̀pọlọpọ ọrọ̀; ni ọti-waini ti Helboni, ati irun agutan funfun.
19 Dani pẹlu ati Jafani lati Usali ngbé ọjà rẹ: irin didán, kassia, ati kalamu wà li ọjà rẹ.
20 Dedani ni oniṣòwo rẹ ni aṣọ ibori fun kẹkẹ́.
21 Arabia, ati gbogbo awọn ọmọ-alade Kedari, awọn ni awọn oniṣòwo rẹ, ni ọdọ-agutan, ati agbò, ati ewurẹ; ninu wọnyi ni nwọn ṣe oniṣòwo rẹ.
22 Awọn oniṣòwo Ṣeba ati Rama, awọn li awọn oniṣòwo rẹ: nwọn tà onirũru turari daradara li ọjà rẹ, ati pẹlu onirũru okuta oniyebiye, ati wura.
23 Harani, ati Kanneh, ati Edeni, awọn oniṣòwo Ṣeba, Assuru, ati Kilmadi, ni awọn oniṣòwo rẹ.
24 Wọnyi li awọn oniṣòwo rẹ li onirũru nkan, ni aṣọ alaro, ati oniṣẹ-ọnà, ati apoti aṣọ oniyebiye, ti a fi okùn dì, ti a si fi igi kedari ṣe, ninu awọn oniṣòwo rẹ.
25 Awọn ọkọ Tarṣiṣi ni èro li ọjà rẹ: a ti mu ọ rẹ̀ si i, a si ti ṣe ọ logo li ãrin okun.
26 Awọn atukọ̀ rẹ ti mu ọ wá sinu omi nla: ẹfũfu ilà-õrun ti fọ́ ọ li ãrin okun.
27 Ọrọ̀ rẹ ati ọjà rẹ, ọjà tità rẹ, awọn atukọ̀ rẹ, ati atọ́kọ̀ rẹ, adikọ̀ rẹ, ati awọn alábarà rẹ, ati gbogbo awọn ologun rẹ, ti o wà ninu rẹ, ati ninu gbogbo ẹgbẹ́ rẹ, ti o wà li ãrin rẹ, yio ṣubu li ãrin okun li ọjọ iparun rẹ.
28 Awọn ilẹ àgbègbe yio mì nitori iró igbe awọn atọkọ̀ rẹ.
29 Gbogbo awọn alajẹ̀, awọn atukọ̀, ati awọn atọ́kọ̀ okun yio sọkalẹ kuro ninu ọkọ̀ wọn, nwọn o duro lori ilẹ.
30 Nwọn o si jẹ ki a gbọ́ ohùn wọn si ọ, nwọn o si kigbe kikoro, nwọn o si kù ekuru sori ara wọn, nwọn o si yi ara wọn ninu ẽru:
31 Nwọn o si fari wọn patapata fun ọ, nwọn o si fi aṣọ-àpo di ara wọn, nwọn o si sọkun fun ọ ni ikorò aiya, pẹlu ohùnrére ẹkun kikorò.
32 Ati ninu arò wọn ni nwọn o si pohùnrére ẹkún fun ọ, nwọn o si pohùnrére ẹkún sori rẹ, wipe, Ta li o dabi Tire, eyiti a parun li ãrin okun?
33 Nigbati ọjà-tità rẹ ti okun jade wá, iwọ tẹ́ orilẹ-ède pupọ lọrun; iwọ fi ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ rẹ, ati ọjà rẹ, sọ awọn ọba aiye di ọlọrọ̀.
34 Nisisiyi ti okun fọ́ ọ bajẹ̀ ninu ibú omi, nitorina òwo rẹ, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ li ãrin rẹ, li o ṣubu.
35 Ẹnu yio yà gbogbo awọn olugbe erekuṣu wọnni si ọ, awọn ọba wọn yio si dijì, iyọnu yio yọ li oju wọn.
36 Awọn oniṣòwo lãrin awọn orilẹ-ède yio dún bi ejò si ọ; iwọ o si jẹ ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́ lailai.