1 PẸLUPẸLU o wi fun mi pe, Ọmọ enia, jẹ ohun ti iwọ ri, jẹ iká-iwé yi, si lọ ba ile Israeli sọrọ.
2 Mo si ya ẹnu mi, o si mu mi jẹ iká-iwé na.
3 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, mu ki ikùn rẹ jẹ, ki o si fi iká-iwé yi ti emi fi fun ọ kún inu rẹ. Nigbana ni mo jẹ ẹ, o si dabi oyin li ẹnu ni didùn.
4 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, Lọ, tọ̀ ile Israeli lọ ki o si fi ọ̀rọ mi ba wọn sọrọ.
5 Nitori a kò ran ọ si enia ède ajeji ati sisọrọ, ṣugbọn si ile Israeli.
6 Ki iṣe si ọ̀pọlọpọ enia ède ajeji, ati ède sisọrọ, ọ̀rọ ẹniti iwọ kò le gbọ́. Nitotọ emi iba rán ọ si wọn, nwọn iba gbọ́ tirẹ.
7 Ṣugbọn ile Israeli kò ni gbọ́ tirẹ; nitori ti nwọn kò fẹ gbọ́ ti emi: nitori alafojudi ati ọlọkàn lile ni gbogbo ile Israeli.
8 Kiyesi i, mo ti sọ oju rẹ di lile si oju wọn, ati iwaju rẹ di lile si iwaju wọn.
9 Bi okuta diamondi ti o le ju okuta ibọn ni mo ṣe iwaju rẹ: máṣe bẹ̀ru wọn, bẹ̃ni ki o máṣe fòya oju wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọ̀tẹ ile.
10 Pẹlupẹlu o wi fun mi pe, Ọmọ enia, gba gbogbo ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ si ọkàn rẹ, si fi eti rẹ gbọ́ wọn.
11 Si lọ, tọ̀ awọn ti igbekùn lọ, awọn ọmọ enia rẹ, si ba wọn sọ̀rọ, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; bi nwọn o gbọ́, tabi bi nwọn o kọ̀.
12 Ẹmi si gbe mi soke, mo si gbọ́ ohùn iró nla lẹhin mi, nwipe, Ibukun ni fun ogo Oluwa lati ipò rẹ̀ wá.
13 Mo si gbọ́ ariwo iyẹ́ awọn ẹ̀da alãye, ti o kàn ara wọn, ati ariwo awọn kẹkẹ́ ti o wà pẹlu wọn, ati ariwo iró nla.
14 Bẹ̃ni ẹmi na gbe mi soke, o si mu mi kuro, mo si lọ ni ibinujẹ, ati ninu gbigbona ọkàn mi; ṣugbọn ọwọ́ Oluwa le lara mi.
15 Nigbana ni mo tọ̀ awọn ti igbekùn ti Telabibi lọ, ti nwọn ngbe ẹba odò Kebari, mo si joko nibiti nwọn joko, ẹnu si yà mi bi mo ti wà lãrin wọn ni ijọ meje.
16 O si di igbati o ṣe li opin ijọ meje, ọ̀rọ Oluwa wá sọdọ mi, wipe:
17 Ọmọ enia, mo ti fi iwọ ṣe oluṣọ́ fun ile Israeli, nitorina gbọ́ ọ̀rọ li ẹnu mi, si kilọ fun wọn lati ọdọ mi wá.
18 Nigbati emi wi fun enia buburu pe, Iwọ o kú nitõtọ; ti iwọ kò si kilọ̀ fun u, ti iwọ kò sọ̀rọ lati kilọ fun enia buburu, lati kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, lati gba ẹmi rẹ̀ là; enia buburu na yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀; ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ.
19 Ṣugbọn bi iwọ ba kilọ̀ fun enia buburu, ti kò si kuro ninu buburu rẹ̀, ti ko yipada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ṣugbọn ọrun rẹ mọ́.
20 Ẹ̀wẹ, nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si da ẹ̀ṣẹ, ti mo si fi ohun idigbolu siwaju rẹ, yio kú; nitoriti iwọ kò kilọ fun u, yio kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, a ki yio ranti ododo rẹ̀ ti o ti ṣe; ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ.
21 Ṣugbọn bi iwọ ba kilọ fun olododo, ki olododo ki o má dẹ̀ṣẹ, ti on kò si ṣẹ̀, yio yè nitotọ, nitori ti a kilọ fun u, ọrùn rẹ si mọ́.
22 Ọwọ́ Oluwa si wà lara mi nibẹ; o si wi fun mi pe, Dide, lọ si pẹtẹlẹ, emi o si ba ọ sọ̀rọ nibẹ.
23 Mo si dide, mo si lọ si pẹtẹlẹ, si kiyesi i ogo Oluwa duro nibẹ, bi ogo ti mo ri lẹba odò Kebari: mo si doju mi bolẹ.
24 Ẹmi si wọ̀ inu mi lọ, o si gbe mi duro li ẹsẹ mi, o si ba mi sọ̀rọ, o si sọ fun mi pe, Lọ, há ara rẹ mọ ile rẹ.
25 Ṣugbọn iwọ, ọmọ enia, kiyesi i, nwọn o si fi idè le ọ, nwọn o si fi dè ọ, iwọ ki yio si jade larin wọn.
26 Emi o si mu ahọn rẹ lẹ mọ oke ẹnu rẹ, iwọ o si yadi, iwọ ki yio jẹ abaniwi si wọn; nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn.
27 Ṣugbọn nigbati mo ba bá ọ sọ̀rọ, emi o ya ẹnu rẹ, iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹniti o gbọ́, jẹ ki o gbọ́; ẹniti o kọ̀, jẹ ki o kọ̀ nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn.