Esek 41 YCE

1 O si mu mi wá si tempili, o si wọ̀n awọn atẹrigbà, igbọnwọ mẹfa ni gbigborò li apakan, igbọnwọ mẹfa ni gbigborò li apakeji, ibú agọ na.

2 Ati ibú ilẹkùn na jẹ igbọnwọ mẹwa; ihà ilẹkùn na si jẹ igbọnwọ marun li apakan, ati igbọnwọ marun li apakeji; o si wọ̀n gigùn rẹ̀, ogoji igbọnwọ; ati ibú rẹ̀, ogún igbọnwọ.

3 O si wá si inu rẹ̀, o si wọ̀n atẹrigbà ilẹkùn na, igbọnwọ meji; ati ilẹkùn na, igbọnwọ mẹfa; ibú ilẹkùn na si jẹ igbọnwọ meje.

4 Bẹ̃ li o si wọ̀n gigùn rẹ̀, ogún igbọnwọ; ati ibú rẹ̀, ogún igbọnwọ, niwaju tempili: o si wi fun mi pe, Eyi ni ibi mimọ́ julọ.

5 O si wọ̀n ogiri ile na, igbọnwọ mẹfa; ati ibú yàrá-ihà gbogbo igbọnwọ mẹrin, yi ile na ka nihà gbogbo.

6 Ati awọn yará-ihà, ọkan lori ekeji jẹ mẹta, nigba ọgbọ̀n: nwọn si wọ̀ inu ogiri ti ile awọn yará-ihà na yika, ki nwọn ba le di ara wọn mu, nitori kò si idimú ninu ogiri ile na.

7 A si ṣe e gborò, o si lọ yika loke awọn yará ihà: nitori ogiri ile na lọ loke-loke yi ile na ka: nitorina ibú ile na wà loke, bẹ̃ni iyará isalẹ yọ si toke lãrin.

8 Emi si ri giga ile na yika: ipilẹ awọn yará-ẹ̀gbẹ́ na si jẹ ije kikun kan ti igbọnwọ mẹfa ni gigun.

9 Ibú ogiri na, ti yará-ẹ̀gbẹ́ lode, jẹ igbọnwọ marun: ati eyi ti o kù ni ibi yará-ẹ̀gbẹ́ ti mbẹ ninu.

10 Ati lãrin yará na, ogún igbọnwọ ni gbigborò, yi ile na ka ni ihà gbogbo.

11 Ati ilẹkùn awọn yará-ẹ̀gbẹ́ na mbẹ li ọ̀na ibi ti o kù, ilẹkùn kan li ọ̀na ariwa, ati ilẹkùn kan ni gusu: ati ibú ibẹ̀ na ti o kù, jẹ igbọnwọ marun yika.

12 Ati ile ti o wà niwaju eyiti a yà sọtọ̀ ni igun ọ̀na iwọ-õrun, jẹ ãdọrin igbọnwọ ni gbigborò; ogiri ile na si jẹ igbọnwọ marun ni ibú yika, ati gigùn rẹ̀, ãdọrun igbọnwọ.

13 O si wọ̀n ile na, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn; ati ibi ti a yà sọtọ̀, ati ile na, pẹlu ogiri wọn, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn.

14 Ati ibú oju ile na, ati ti ibi ti a yà sọtọ̀ nihà ila-õrun ọgọrun igbọnwọ.

15 O si wọ̀n gigun ile na ti o kọju si ibiti a yà sọtọ̀ ti mbẹ lẹhin rẹ̀, ati ibujoko-oke ni ihà kan ati nihà miran, ọgọrún igbọnwọ, pẹlu tempeli inu, ati iloro agbalá na;

16 Awọn iloro, ati ferese toro, ati ibujoko oke yika lori ile olorule mẹta wọn, ti o wà niwaju iloro na, li a fi igi tẹ́ yika, ati lati ilẹ de oke ferese, a si bò awọn ferese na;

17 Si ti oke ilẹkun ani titi de ile ti inu, ati ti ode, ati lara ogiri niha gbogbo tinu tode ni wiwọ̀n.

18 Kerubu ati igi ọpẹ li a si fi ṣe e, igi ọpẹ kan si mbẹ lãrin kerubu ati kerubu: kerubu kọkan si ni oju meji;

19 Oju enia kan si wà nihà ibi igi ọpe li apa kan, ati oju ẹgbọ̀rọ kiniun kan si wà nihà ibi igi ọpẹ li apa keji: a ṣe e yi ile na ka niha gbogbo.

20 Lati ilẹ titi fi de okè ilẹkùn, ni a ṣe kerubu ati igi ọpẹ si, ati lara ogiri tempili na.

21 Awọn opó ilẹkùn tempili na jẹ igun mẹrin lọgbọgba: ati iwaju ibi mimọ́ irí ọkan bi irí ekeji.

22 Pẹpẹ igi na jẹ igbọnwọ mẹta ni giga, gigùn rẹ̀ igbọnwọ meji; ati igun rẹ̀, ati gigùn rẹ̀, ati awọn ogiri rẹ̀ jẹ ti igi: o si wi fun mi pe, Eyi ni tabili ti mbẹ niwaju Oluwa.

23 Ati tempili na, ati ibi mimọ́ na, ni ilẹkùn meji.

24 Awọn ilẹkùn mejeji na ni awẹ, awẹ meji ti nyi; awẹ meji fun ilẹkùn kan, ati awẹ meji fun ilẹkùn keji.

25 Kerubu, ati igi ọpẹ li a ṣe si ara wọn, sara ilẹkùn tempili, gẹgẹ bi eyiti a ṣe sara ogiri; igi ibori wà loju iloro lode.

26 Ferese toro ati igi ọpẹ mbẹ nihà ihin ati nihà ọhun nihà iloro, ati ni yará-iha ile na, ati ni igi ibori.