Esek 31 YCE

1 O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣù kẹta, li ọjọ ekini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

2 Ọmọ enia, sọ fun Farao ọba Egipti, ati fun ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ pe, Tani iwọ jọ ni titobi rẹ?

3 Kiyesi i, awọn ara Assiria ni igi kedari ni Lebanoni ti o li ẹ̀ka daradara, ti o si ṣiji boni, ti o si ga, ṣonṣo ori rẹ̀ si wà lãrin awọn ẹ̀ka bibò.

4 Omi sọ ọ di nla, ibú gbé e ga soke, o fi awọn odò nla rẹ̀ yi oko rẹ̀ ka, o si rán awọn odo kékèké rẹ̀ si gbogbo igbẹ́.

5 Nitorina a gbe giga rẹ̀ soke jù gbogbo igi igbẹ́ lọ, ẹ̀ka rẹ̀ si di pupọ̀, awọn ẹ̀ka rẹ̀ si di gigùn nitori ọ̀pọlọpọ omi, nigbati o yọ wọn jade.

6 Gbogbo ẹiyẹ oju ọrun kọ́ itẹ́ wọn ninu ẹ̀ka rẹ̀, ati labẹ ẹ̀ka rẹ̀ ni gbogbo ẹranko igbẹ́ bi ọmọ wọn si, ati labẹ ojiji rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ède nla ngbe.

7 Bayi li o ni ẹwà ninu titobi rẹ̀, ninu gigùn ẹ̀ka rẹ̀: nitori ti egbò rẹ̀ wà li ẹbá omi nla.

8 Awọn igi kedari inu ọgbà Ọlọrun kò le bò o mọlẹ: awọn igi firi kò dabi ẹ̀ka rẹ̀, awọn igi kẹsnuti kò si dabi ẹ̀ka rẹ̀; bẹ̃ni kò si igikigi ninu ọgbà Ọlọrun ti o dabi rẹ̀ li ẹwà rẹ̀.

9 Emi ti ṣe e ni ẹwà nipa ọ̀pọlọpọ ẹ̀ka rẹ̀: tobẹ̃ ti gbogbo igi Edeni, ti o wà ninu ọgbà Ọlọrun, ṣe ilara rẹ̀.

10 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti on gbe ara rẹ̀ soke ni giga, o si ti yọ ṣonṣo rẹ̀ soke lãrin awọn ẹ̀ka didí, ọkàn rẹ̀ si gbe soke nitori giga rẹ̀;

11 Nitorina li emi ti ṣe fi i le alagbara awọn keferi lọwọ; on o bá a ṣe dajudaju: Emi ti lé e jade nitori buburu rẹ̀.

12 Ati awọn alejo, ẹlérù awọn orilẹ-ède, ti ké e kuro, nwọn si ti tú u ká; ẹka rẹ̀ ṣubu sori awọn oke, ati ninu gbogbo afonifoji, ẹka rẹ̀ si ṣẹ́ lẹba gbogbo odò ilẹ na; gbogbo awọn orilẹ-ède aiye si jade lọ kuro labẹ òjiji rẹ̀, nwọn si fi i silẹ.

13 Gbogbo awọn ẹiyẹ oju ọrun yio ma gbe ori ahoro rẹ̀, ati lori ẹ̀ka rẹ̀ ni gbogbo ẹranko igbẹ́ yio wà.

14 Nitori ki igikigi ti o wà lẹba omi ki o má ba gbe ara wọn ga nitori giga wọn, tabi ki nwọn yọ ṣonṣo wọn lãrin ẹ̀ka dídi; tabi ki igi wọn duro ni giga wọn, gbogbo awọn ti o mu omi: nitori ti a fi gbogbo wọn le ikú lọwọ, si isalẹ aiye, li ãrin awọn ọmọ enia, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.

15 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; pe, Li ọjọ ti o sọkalẹ lọ si ibojì mo jẹ ki ọ̀fọ ki o wà, mo fi ibú bò o mọlẹ, mo si se awọn iṣàn omi, awọn omi nla ni mo si dá duro: emi si jẹ ki Lebanoni ki o ṣọ̀fọ fun u, gbogbo igi igbẹ́ si dakú nitori rẹ̀.

16 Emi mu awọn orilẹ̀-èdè mì nipa iró iṣubu rẹ̀, nigbati mo sọ ọ sinu ipòokú, pẹlu awọn ti o sọkalẹ sinu ihò, ati gbogbo igi Edeni, awọn àṣayan ati awọn ti o dara jù ti Lebanoni, gbogbo awọn ti o mu omi, li a o tù ninu ni ìsalẹ aiye.

17 Awọn pẹlu sọkalẹ lọ sinu ipò-okú pẹlu rẹ̀ sọdọ awọn ti a fi idà pa; awọn ti o si jẹ apá rẹ̀, ti ngbe abẹ òjiji rẹ̀ li ãrin awọn keferi.

18 Tani iwọ jọ li ogo ati ni titobi lãrin awọn igi Edeni? sibẹ a o mu ọ wá ilẹ pẹlu awọn igi Edeni si ìsalẹ aiye, iwọ o dubulẹ li ãrin awọn alaikọlà, pẹlu awọn ti a fi idà pa. Eyi ni Farao ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.