Esek 28 YCE

1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,

2 Ọmọ enia, sọ fun ọmọ-alade Tire pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti ọkàn rẹ gbe soke, ati ti iwọ si wipe, Ọlọrun li emi, emi joko ni ibujoko Ọlọrun, larin okun; ṣugbọn enia ni iwọ, iwọ kì isi ṣe Ọlọrun, bi o tilẹ gbe ọkàn rẹ soke bi ọkàn Ọlọrun.

3 Wo o, iwọ sa gbọn ju Danieli lọ; kò si si ohun ikọ̀kọ ti o le fi ara sin fun ọ.

4 Ọgbọ́n rẹ ati oye rẹ li o fi ni ọrọ̀, o si ti ni wura ati fadáka sinu iṣura rẹ:

5 Nipa ọgbọ́n rẹ nla ati nipa òwo rẹ li o ti fi sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ, ọkàn rẹ si gbe soke nitori ọrọ̀ rẹ.

6 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti o ti ṣe ọkàn rẹ bi ọkàn Ọlọrun;

7 Kiyesi i, nitorina emi o mu alejo wá ba ọ, ẹlẹ̀ru ninu awọn orilẹ-ède: nwọn o si fà idà wọn yọ si ẹwà ọgbọ́n rẹ, nwọn o si bà didán rẹ jẹ.

8 Nwọn o mu ọ sọkalẹ wá sinu ihò, iwọ o si kú ikú awọn ti a pa li ãrin okun.

9 Iwọ ha le sọ sibẹ niwaju ẹni ti npa ọ, pe, Emi li Ọlọrun? ṣugbọn enia ni iwọ, o kì yio si jẹ Ọlọrun, lọwọ ẹniti npa ọ.

10 Iwọ o kú ikú awọn alaikọlà lọwọ awọn alejo: nitori emi li o ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi.

11 Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe,

12 Ọmọ enia, pohùnréré sori ọba Tire, ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ fi edidi dí iye na, o kún fun ọgbọ́n, o si pé li ẹwà.

13 Iwọ ti wà ni Edeni ọgbà Ọlọrun; oniruru okuta iyebiye ni ibora rẹ, sardiu, topasi, ati diamondi, berili, oniki, ati jasperi, safire, emeraldi, ati karbunkili, ati wura: iṣẹ ìlu rẹ ati ti fère rẹ li a pèse ninu rẹ li ọjọ ti a dá ọ.

14 Iwọ ni kerubu ti a nà ti o si bò; emi si ti gbe ọ kalẹ: iwọ wà lori oke mimọ́ Ọlọrun; iwọ ti rìn soke rìn sodò lãrin okuta iná.

15 Iwọ pé li ọnà rẹ lati ọjọ ti a ti dá ọ, titi a fi ri aiṣedẽde ninu rẹ.

16 Nitori ọ̀pọlọpọ òwo rẹ, nwọn ti fi iwà-ipa kún ãrin rẹ, iwọ si ti ṣẹ̀: nitorina li emi o ṣe sọ ọ nù bi ohun ailọ̀wọ kuro li oke Ọlọrun: emi o si pa ọ run, iwọ kerubu ti o bò, kuro lãrin okuta iná.

17 Ọkàn rẹ gbe soke nitori ẹwà rẹ, o ti bà ọgbọ́n rẹ jẹ nitori dídan rẹ; emi o bì ọ lulẹ, emi o gbe ọ kalẹ niwaju awọn ọba, ki nwọn ba le wò ọ.

18 Iwọ ti bà ibi mimọ́ rẹ jẹ nipa ọ̀pọlọpọ aiṣedẽde rẹ, nipa aiṣedẽde òwo rẹ; nitorina emi o mu iná jade lati ãrin rẹ wá, yio jó ọ run, emi o si sọ ọ di ẽru lori ilẹ loju gbogbo awọn ti o wò ọ:

19 Gbogbo awọn ti o mọ̀ ọ lãrin awọn orilẹ-ède li ẹnu o yà si ọ: iwọ o jẹ ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́ lailai.

20 Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,

21 Ọmọ enia, gbé oju rẹ si Sidoni, ki o si sọtẹlẹ si i,

22 Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Sa wò o, Emi doju kọ ọ, iwọ Sidoni; a o si ṣe mi logo li ãrin rẹ, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o bá ti mu idajọ mi ṣẹ ninu rẹ̀, ti a o si yà mi si mimọ́ ninu rẹ̀.

23 Emi o si rán àjakálẹ àrun sinu rẹ̀, ati ẹjẹ ni igboro rẹ̀; a o si fi idà pa awọn si a ṣá li ọgbẹ li ãrin rẹ̀ lori rẹ̀ nihà gbogbo; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

24 Kì yio si si ẹgún ti ngún ni fun ile Israeli mọ́, tabi ẹgún bibani ninu jẹ́ ti gbogbo awọn ti o yi wọn ká, ti o si ṣãtá wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.

25 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Nigbati emi o bá ti kó ile Israeli jọ kuro lãrin awọn orilẹ-ède ti a tú wọn ká si, ti a o si yà mi si mimọ́ ninu wọn loju awọn keferi, nigbana ni nwọn o gbé ilẹ wọn ti mo ti fi fun Jakobu iranṣẹ mi.

26 Nwọn o si ma gbé inu rẹ̀ ni ibalẹ-aiya, nwọn o si kọ́ ile, nwọn o si gbìn ọgbà àjara; nitõtọ, nwọn o wà ni ibalẹ-aiya, nigbati emi bá ti mu idajọ mi ṣẹ si ara awọn ti ngàn wọn yi wọn kakiri, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun wọn.