Esek 46 YCE

1 BAYI li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹnu-ọ̀na agbala ti inu ti o kọju si ila-õrun yio wà ni titì ni ọjọ mẹfa ti a fi iṣiṣẹ; ṣugbọn ni ọjọ isimi li a o ṣi i silẹ, ati li ọjọ oṣù titun li a o si ṣi i silẹ.

2 Olori na yio si ba ẹnu-ọ̀na iloro ti ẹnu-ọ̀na ode wọle, yio si duro nibi opó ẹnu-ọ̀na, awọn alufa yio si pèse ọrẹ ẹbọ sisun rẹ̀ ati ọrẹ ẹbọ idupẹ rẹ̀, on o si ma sìn ni iloro ẹnu-ọ̀na: yio si jade wá; a kì yio si tì ẹnu-ọ̀na titi di aṣalẹ.

3 Enia ilẹ na yio si ma sìn ni ilẹkùn ẹnu-ọ̀na yi niwaju Oluwa ni ọjọ isimi, ati ni oṣù titun.

4 Ọrẹ-ẹbọ sisun ti olori na yio rú si Oluwa ni ọjọ isimi, yio jẹ ọdọ-agutan mẹfa alailabawọn, ati agbò kan alailabàwọn.

5 Ati ọrẹ ẹbọ jijẹ yio jẹ efà kan fun agbò kan, ati ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan.

6 Ati li ọjọ oṣù titun, ẹgbọ̀rọ malũ kan ailabawọn, ati ọdọ-agutan mẹfa, ati agbò kan: nwọn o wà lailabàwọn.

7 Yio si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ, efa fun ẹgbọ̀rọ akọ malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan gẹgẹ bi ọwọ́ rẹ̀ ba ti to, ati hini ororo kan fun efa kan.

8 Nigbati olori na yio ba si wọle, ọ̀na iloro ẹnu-ọ̀na ni yio ba wọle, yio si ba ọ̀na rẹ̀ jade.

9 Nigbati enia ilẹ na yio ba si wá siwaju Oluwa ni awọn apejọ ọ̀wọ, ẹniti o ba ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa wọle lati sìn, yio ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na gusu jade; ẹniti o ba si ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na gusu wọle yio si ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa jade; kì yio ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ti o ba wọle jade, ṣugbọn yio jade lodi keji.

10 Ati olori ti o wà lãrin wọn, nigbati nwọn ba wọle, yio wọle; nigbati nwọn ba si jade, yio jade.

11 Ati ninu awọn asè ati ninu awọn ajọ, ọrẹ-ẹbọ jijẹ yio jẹ efa kan fun ẹgbọ̀rọ akọ-malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan.

12 Nigbati olori na yio ba si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun atinuwá, tabi ọrẹ-ẹbọ idupẹ atinuwá fun Oluwa, ẹnikan yio si ṣi ilẹkun ti o kọjusi ila-õrun fun u, yio si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ idupẹ rẹ̀, bi o ti ṣe li ọjọ-isimi: yio si jade; ati lẹhin ijadelọ rẹ̀ ẹnikan yio tì ilẹkun.

13 Li ojojumọ ni iwọ o pèse ọdọ agutan kan alailabawọn ọlọdun kan fun ọrẹ-ẹbọ sisun fun Oluwa: iwọ o ma pèse rẹ̀ lorowurọ̀.

14 Iwọ o si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun u lorowurọ̀, idamẹfa efa, ati idamẹfa hini ororo kan, lati fi pò iyẹfun daradara na; ọrẹ-ẹbọ jijẹ nigbagbogbo nipa aṣẹ lailai fun Oluwa.

15 Bayi ni nwọn o pèse ọdọ-agutan na, ati ọrẹ-ẹbọ jijẹ na, ati ororo na, lojojumọ fun ọrẹ-ẹbọ sisun nigbagbogbo.

16 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi olori na ba fi ẹbùn fun ẹnikẹni ninu awọn ọmọ rẹ̀, ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀; yio jẹ ini wọn nipa ijogun.

17 Bi o ba si fi ẹbùn ninu ini rẹ̀ fun ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, nigbana yio jẹ tirẹ̀ titi di ọdun omnira; yio si tun pada di ti olori na: ṣugbọn ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀ fun wọn.

18 Olori na kì yio si fi ipá mu ninu ogún awọn enia lati le wọn jade kuro ninu ini wọn, yio fi ogún fun awọn ọmọ rẹ̀ lara ini ti ontikalarẹ̀: ki awọn enia mi ki o má ba tuká, olukuluku kuro ni ini rẹ̀.

19 O si mu mi kọja li abawọ̀, ti o wà lẹba ẹnu-ọ̀na, si awọn yará mimọ́ ti awọn alufa, ti o kọjusi ariwa: si kiyesi i, ibi kan wà nibẹ̀ ni ihà mejeji iwọ-õrun.

20 O si wi fun mi pe, Eyi ni ibiti awọn alufa yio ma sè ọrẹ irekọja ati ọrẹ ẹ̀ṣẹ, nibiti nwọn o ma yan ọrẹ jijẹ; ki nwọn má ba gbe wọn jade si agbalá ode, lati sọ awọn enia di mimọ́.

21 O si mu mi jade wá si agbalá ode, o si mu mi kọja ni igun mẹrẹrin agbalá na; si kiyesi i, ni olukuluku igun agbalá na ni agbala kan gbe wà.

22 Ni igun mẹrẹrin agbalá na, ni agbalá ti a kànpọ ologoji igbọnwọ ni gigùn, ati ọgbọ̀n ni ibú: awọn igun mẹrẹrin wọnyi jẹ iwọ̀n kanna.

23 Ọwọ́ ile kan si wà yika ninu wọn, yika awọn mẹrẹrin, a si ṣe ibudaná si abẹ ọwọ́ na yika.

24 O si wi fun mi pe, Wọnyi ni ibi awọn ti nsè, nibiti awọn iranṣẹ ile na yio ma se ẹbọ awọn enia.