Esek 4 YCE

Esekiẹli Gbé Òfin Jáde lórí Ìwà Ìbàjẹ́ ní Jerusalẹmu

1 IWỌ, ọmọ enia, mu awo kan, ki o si fi si iwaju rẹ, ki o si ṣe aworan ilu Jerusalemu sinu rẹ̀.

2 Ki o si dótì i, ki o si mọ ile iṣọ tì i, ki o si mọ odi tì i, ki o si gbe ogun si i, ki o si to õlù yi i ka.

3 Mu awo irin kan, ki o si gbe e duro bi odi irin lãrin rẹ ati ilu na: ki o si kọju si i, a o si dótì i, iwọ o si dótì i. Eyi o jẹ àmi si ile Israeli.

4 Fi iha osì rẹ dubulẹ, ki o si fi ẹ̀ṣẹ ile Israeli sori rẹ̀: gẹgẹ bi iye ọjọ ti iwọ o dubulẹ sori rẹ̀ ni iwọ o ru ẹ̀ṣẹ wọn.

5 Nitori mo ti fi ọdun ẹ̀ṣẹ wọn le ọ lori, gẹgẹ bi iye ọjọ na, ẹwa-di-ni-irinwo ọjọ: bẹ̃ni iwọ o ru ẹ̀ṣẹ ile Israeli.

6 Nigbati iwọ ba si pari wọn, tun fi ẹgbẹ́ rẹ ọtún dubulẹ, iwọ o si ru ẹ̀ṣẹ ile Juda li ogoji ọjọ: mo ti yàn ọjọ kan fun ọdun kan fun ọ.

7 Nitorina iwọ o kọju si didótì Jerusalemu, iwọ ki yio si bo apá rẹ, iwọ o si sọ asọtẹlẹ si i.

8 Si kiyesi i, emi o fi idè le ara rẹ, iwọ ki yio si yipada lati ihà kan de ekeji, titi iwọ o fi pari gbogbo ọjọ didotì rẹ.

9 Si mu alikama, ati ọka bàba, erẽ ati lentile ati milleti, ati ẹwẹ, fi wọn sinu ikoko kan, ki o si fi wọn ṣe akara, gẹgẹ bi iye ọjọ ti iwọ o dubulẹ li ẹgbẹ́ rẹ, ẹwa-di-ni-irinwo ọjọ ni iwọ o jẹ ninu rẹ̀.

10 Iwọ o si jẹ onjẹ rẹ nipa ìwọn, ogún ìwọn ṣekeli li ọjọ kan, lati akoko de akoko ni iwọ o jẹ ẹ.

11 Iwọ o si mu omi nipa ìwọn, idamẹfa oṣuwọ̀n hini kan: lati akoko de akoko ni iwọ o mu u.

12 Iwọ o si jẹ ẹ bi akara ọka bàba, iwọ o si fi igbẹ́ enia din i, li oju wọn.

13 Oluwa si wipe, Bayi li awọn ọmọ Israeli yio jẹ akara aimọ́ wọn larin awọn keferi, nibiti emi o le wọn lọ.

14 Nigbana ni mo wipe, A, Oluwa Ọlọrun! kiye si i, a kò ti sọ ọkàn mi di aimọ́: nitori lati igba ewe mi wá titi di isisiyi, emi kò ti ijẹ ninu ohun ti o kú fun ara rẹ̀, tabi ti a faya pẹrẹpẹrẹ, bẹ̃ni ẹran ẽwọ̀ kò iti iwọ̀ mi li ẹnu ri.

15 Nigbana ni o wi fun mi pe, Wõ, mo ti fi ẹlẹbọtọ fun ọ dipò igbẹ́ enia, iwọ o si fi ṣe akara rẹ.

16 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, kiye si i, emi o ṣẹ ọpá onjẹ ni Jerusalemu: nwọn o si jẹ akara nipa ìwọn, ati pẹlu itọju; nwọn o si mu omi nipa ìwọn ati pẹlu iyanu.

17 Ki nwọn ki o le ṣe alaini akara ati omi, ki olukuluku wọn ki o le yanu si ọmọ-nikeji rẹ̀, ki nwọn si run nitori ẹ̀ṣẹ wọn.