1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
2 Ọmọ enia, sọ fun awọn ọmọ enia rẹ, si wi fun wọn pe, Bi emi bá mu idà wá sori ilẹ kan, bi awọn enia ilẹ na bá mu ọkunrin kan ninu ara wọn, ti nwọn si fi ṣe oluṣọ́ wọn:
3 Bi on bá ri ti idà mbọ̀ wá sori ilẹ na ti o bá fun ipè, ti o si kìlọ fun awọn enia na:
4 Nigbana ẹnikẹni ti o bá gbọ́ iró ipè, ti kò si gbà ìkilọ; bi idà ba de, ti o si mu on kuro, ẹjẹ rẹ̀ yio wà lori on tikalarẹ̀.
5 O gbọ́ iró ipè, kò si gbà ìkilọ: ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀. Ṣugbọn ẹniti o gbọ́ ìkilọ yio gbà ọkàn ara rẹ̀ là.
6 Ṣugbọn bi oluṣọ́ na bá ri ti idà mbọ̀, ti kò si fun ipè, ti a kò si kìlọ fun awọn enia; bi idà ba de, ti o ba si mu ẹnikẹni lãrin wọn, a mu u kuro nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere lọwọ oluṣọ́ na.
7 Bẹ̃ni, iwọ ọmọ enia, emi ti fi ọ ṣe oluṣọ́ fun ile Israeli; nitorina iwọ o gbọ́ ọ̀rọ li ẹnu mi, iwọ o si kìlọ fun wọn lati ọdọ mi.
8 Nigbati emi ba wi fun enia buburu pe, Iwọ enia buburu, kikú ni iwọ o kú, bi iwọ kò bá sọ̀rọ lati kìlọ fun enia buburu na ki o kuro li ọ̀na rẹ̀, enia buburu na yio kú nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ.
9 Ṣugbọn, bi iwọ ba kìlọ fun enia buburu na niti ọ̀na rẹ̀ lati pada kuro ninu rẹ̀, bi on kò ba yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀, on o kù nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn iwọ ti gbà ọkàn rẹ là.
10 Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun ile Israeli; pe, Bayi li ẹnyin nwi, pe, Bi irekọja ati ẹ̀ṣẹ wa ba wà lori wa, ti awa si njoró ninu wọn, bawo li a o ti ṣe le wà lãye.
11 Sọ fun wọn pe, Bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, emi kò ni inu-didun ni ikú enia buburu, ṣugbọn ki enia buburu yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀ ki o si yè: ẹ yipada, ẹ yipada kuro ninu ọ̀na buburu nyin; nitori kini ẹnyin o ṣe kú, Ile Israeli?
12 Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun awọn ọmọ enia rẹ, ododo olododo kì yio gbà a là li ọjọ irekọja rẹ̀: bi o ṣe ti ìwa buburu enia buburu, on kì yio ti ipa rẹ̀ ṣubu li ọjọ ti o yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀: bẹ̃ni olododo kì yio là nipa ododo rẹ̀ li ọjọ ti o dẹṣẹ.
13 Nigbati emi o wi fun olododo pe, yiyè ni yio yè, bi o ba gbẹkẹle ododo ara rẹ̀, ti o si ṣe aiṣedẽde, gbogbo ododo rẹ̀ li a kì yio ranti mọ, ṣugbọn nitori aiṣedẽde ti o ti ṣe, on o ti itori rẹ̀ kú.
14 Ẹ̀wẹ, nigbati emi wi fun enia buburu pe, Kikú ni iwọ o kú; bi on ba yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o si ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ;
15 Bi enia buburu ba mu ògo padà, ti o si san ohun ti o ti jí padà, ti o si nrin ni ilana ìye, li aiṣe aiṣedẽde; yiyè ni yio yè, on kì o kú.
16 A kì yio ṣe iranti gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ndá fun u: on ti ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ; on o yè nitõtọ.
17 Sibẹ awọn ọmọ enia rẹ wipe, Ọ̀na Oluwa kò dọgba: ṣugbọn bi o ṣe ti wọn ni, ọ̀na wọn kò dọgba.
18 Nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀ ti o si ṣe aiṣedẽde, on o ti ipa rẹ̀ kú.
19 Ṣugbọn bi enia buburu bá yipada kuro ninu buburu rẹ̀, ti o si ṣe eyiti o tọ ti o si yẹ̀, on o ti ipa rẹ̀ wà lãye.
20 Sibẹ ẹnyin wi pe, Ọ̀na Oluwa kò dọgba, Ẹnyin ile Israeli, emi o dá olukuluku nyin li ẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀.
21 O si ṣe li ọdun ikejila ikolọ wa, li oṣu kẹwa, li ọjọ karun oṣu, ẹnikan ti o ti salà jade ni Jerusalemu tọ̀ mi wá, o wipe, A kọlù ilu na.
22 Ọwọ́ Oluwa si wà lara mi li àṣalẹ, ki ẹniti o salà na to de; o si ti ṣi ẹnu mi, titi on fi wá sọdọ mi li owurọ; ẹnu mi si ṣi, emi kò si yadi mọ.
23 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
24 Ọmọ enia, awọn ti ngbe ahoro ile Israeli wọnni sọ, wipe, Abrahamu jẹ ẹnikan, on si jogun ilẹ na: ṣugbọn awa pọ̀, a fi ilẹ na fun wa ni ini.
25 Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, ẹnyin njẹ ẹ̀jẹ mọ ẹran, ẹ si gbe oju nyin soke si awọn oriṣa nyin, ẹ si ta ẹjẹ silẹ, ẹnyin o ha ni ilẹ na?
26 Ẹnyin gbẹkẹle idà nyin, ẹ ṣe irira, olukuluku nyin bà obinrin aladugbò rẹ̀ jẹ́: ẹnyin o ha ni ilẹ na?
27 Iwọ wi bayi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Bi emi ti wà, nitõtọ, awọn ti o wà ninu ahoro na yio ti ipa idà ṣubu, ẹniti o si wà ni gbangba oko li emi o si fi fun ẹranko lati pajẹ, awọn ti o si wà ninu odi ati ninu ihò okuta yio ti ipa ajakalẹ-àrun kú.
28 Nitoriti emi o sọ ilẹ na di ahoro patapata, ọ̀ṣọ nla agbara rẹ̀ kì yio si mọ, awọn oke Israeli yio si di ahoro, ti ẹnikan kì yio le là a kọja.
29 Nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo ba ti sọ ilẹ na di ahoro patapata, nitori gbogbo irira ti nwọn ti ṣe.
30 Iwọ ọmọ enia, sibẹ awọn ọmọ enia rẹ nsọ̀rọ si ọ lẹba ogiri ati lẹba ilẹkun ile, ẹnikini si sọ fun ẹnikeji, olukuluku fun arakunrin rẹ̀ wipe, Wá, emi bẹ̀ ọ si gbọ́ ọ̀rọ ti o ti ọdọ Oluwa jade wá.
31 Nwọn si tọ̀ ọ wá, bi enia ti iwá, nwọn si joko niwaju rẹ bi enia mi, nwọn si gbọ́ ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn nwọn kì yio ṣe wọn: nitori ẹnu wọn ni nwọn fi nfi ifẹ pupọ hàn, ṣugbọn ọkàn wọn tẹ̀le ojukokoro wọn.
32 Si kiyesi i, iwọ jẹ orin ti o dùn pupọ fun wọn, ti ẹnikan ti o ni ohùn daradara, ti o si le fún ohun-elò orin daradara: nitori nwọn gbọ́ ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn nwọn kò ṣe wọn.
33 Ati nigbati eyi bá ṣẹ, (kiyesi i, yio de,) nigbana ni nwọn o mọ̀ pe wolĩ kan ti wà lãrin wọn.