1 AWỌN kan ninu awọn àgba Israeli si wá sọdọ mi, nwọn si joko niwaju mi.
2 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
3 Ọmọ enia, awọn ọkunrin wọnyi ti gbe oriṣa wọn si ọkàn wọn, nwọn si fi ohun ìdigbolu aiṣedede wọn siwaju wọn: emi o ha jẹ ki nwọn bere lọwọ mi rara bi?
4 Nitorina sọ fun wọn, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; olukuluku ọkunrin ile Israeli ti o gbe oriṣa rẹ̀ si ọkàn rẹ̀, ti o si fi ohun ìdugbolu aiṣedẽde rẹ̀ siwaju rẹ̀, ti o si wá sọdọ woli; emi Oluwa yio dá ẹniti o wá lohùn gẹgẹ bi ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀.
5 Ki emi ba le mu ile Israeli li ọkàn ara wọn, nitori gbogbo wọn di ajeji si mi nipasẹ oriṣa wọn.
6 Nitorina wi fun ile Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹ ronupiwada, ki ẹ si yipada kuro lọdọ oriṣa nyin, ki ẹ si yi oju nyin kuro ninu ohun ẽri nyin.
7 Nitori olukuluku ninu ile Israeli, tabi ninu alejo ti o ṣe atipo ni Israeli, ti o yà ara rẹ̀ kuro lọdọ mi, ti o si gbe oriṣa rẹ̀ si ọkàn rẹ̀, ti o si fi ohun ìdugbolu aiṣedẽde rẹ̀ siwaju rẹ̀, ti o si tọ̀ wolĩ kan wá lati bere lọwọ rẹ̀ niti emi: Emi Oluwa yio da a lohùn tikalami:
8 Emi o si dojukọ ọkunrin na, emi o si fi i ṣe àmi ati owe, emi o si ké e kuro lãrin awọn enia mi; ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
9 Bi a ba si tan wolĩ na jẹ nigbati o sọ ohun kan, Emi Oluwa ni mo ti tan wolĩ na jẹ, emi o si nawọ mi le e, emi o si run u kuro lãrin Israeli enia mi.
10 Awọn ni yio si rù ìya aiṣedẽde wọn; ìya wolĩ na yio ri gẹgẹ bi ìya ẹniti o bẽre lọdọ rẹ̀.
11 Ki ile Israeli má ba ṣako lọ kuro lọdọ mi mọ, ki nwọn má ba fi gbogbo irekọja wọn bà ara wọn jẹ mọ, ṣugbọn ki nwọn ki o le jẹ enia mi, ki emi si le jẹ Ọlọrun wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.
12 Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe,
13 Ọmọ enia, nigbati ilẹ na ba ṣẹ̀ si mi nipa irekọja buburu, nigbana ni emi o nawọ mi le e, emi o si ṣẹ́ ọpa onjẹ inu rẹ̀, emi o si rán ìyan si i, emi o si ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀:
14 Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi, Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, kiki ẹmi ara wọn ni nwọn o fi ododo wọn gbàla, li Oluwa Ọlọrun wi.
15 Bi mo ba jẹ ki ẹranko buburu kọja lãrin ilẹ na, ti nwọn si bà a jẹ, tobẹ̃ ti o di ahoro, ti ẹnikan kò le là a ja nitori awọn ẹranko na.
16 Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gbà ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là; awọn nikan li a o gbàla, ṣugbọn ilẹ na yio di ahoro.
17 Tabi bi mo mu idà wá sori ilẹ na, ti mo si wipe, Idà, la ilẹ na ja; tobẹ̃ ti mo ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀:
18 Bi awọn ọkunrin mẹta yi tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là, ṣugbọn awọn tikara wọn nikan li a o gbàla.
19 Tabi bi mo rán ajàkalẹ arùn si ilẹ na, ti mo si da irúnu mi le e ni ẹjẹ, lati ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀:
20 Bi Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là; kìki ọkàn ara wọn ni awọn o fi ododo wọn gbàla.
21 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Melomelo ni nigbati mo ba rán awọn idajọ kikan mi mẹrẹrin sori Jerusalemu, idà, ati iyàn, ati ẹranko buburu, ati ajakalẹ àrun, lati ké enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀?
22 Ṣugbọn kiye si i, ninu rẹ̀ li a o kù awọn ti a o yọ silẹ, ti a o mu jade wá, ati ọmọkunrin, ati ọmọbinrin, kiye si i, nwọn o jade tọ̀ nyin wá, ẹnyin o si ri ọ̀na wọn ati iṣe wọn, a o si tù nyin ninu niti ibi ti emi ti mu wá sori Jerusalemu, ani niti gbogbo ohun ti mo ti mu wá sori rẹ̀.
23 Nwọn o si tù nyin ninu, nigbati ẹnyin ba ri ọ̀na wọn ati iṣe wọn: ẹnyin o si mọ̀ pe emi kò ṣe gbogbo ohun ti mo ti ṣe ninu rẹ̀ li ainidi, ni Oluwa Ọlọrun wi.