Esek 45 YCE

1 PẸLUPẸLU nigbati ẹnyin ba fi ibo pín ilẹ li ogún, ẹ o gbé ọrẹ wá fun Oluwa, eyiti o mọ́ lati ilẹ na wá: gigùn na yio jẹ ẹgbã le ẹgbẹrun ije ni gigùn, ati ẹgbãrun ni ibú. Eyi yio jẹ́ mimọ́ ni gbogbo àgbegbe rẹ̀ yika.

2 Lati inu eyi, ẹ̃dẹgbẹta yio jẹ ti ibi-mimọ́ ni gigùn, pẹlu ẹ̃dẹgbẹta ni ibú, ni igun mẹrẹrin yika; ati adọta igbọnwọ fun igbangba rẹ̀ yika.

3 Ati ninu ìwọn yi ni iwọ o wọ̀n ẹgbã mejila le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbarun ni ibú; ati ninu rẹ̀ ni ibi-mimọ́ yio wà, ibi-mimọ́ julọ.

4 Eyi ti o mọ́ ninu ilẹ na yio jẹ ti awọn alufa, awọn iranṣẹ ibi-mimọ́, ti yio sunmọ lati ṣe iránṣẹ fun Oluwa: yio si jẹ àye fun ile wọn, ati ibi-mimọ́ fun ibi-mimọ́.

5 Ati ẹgbã mejila le ẹgbẹrun ni gigun, ati ti ẹgbãrun ni ibú, ni awọn Lefi, pẹlu awọn iranṣẹ ile na, ni ogún yará, fun ara wọn, ni ini.

6 Ati ini ilu na li ẹnyin o yàn ẹgbarun ni ibú, ati ẹgba mejila le ẹgbẹrun ni gigùn, lẹba ọrẹ ipín mimọ́ na: yio jẹ ti gbogbo ile Israeli.

7 Ati ipín kan yio jẹ ti olori nihà kan ati niha keji ọrẹ ipin mimọ́, ati ti ini ilu, ti o kọju si ọrẹ ipín mimọ́, ti o si kọju si iní ti ilu, lati iha iwọ-õrun si iwọ-õrun, ati lati ihà ila-õrun si ila-õrun: gigùn rẹ̀ yio gbe ọkan ninu awọn ipín, lati eti iwọ-õrun de eti ila-õrun.

8 Ni ilẹ na ni iní rẹ̀ yio wà ni Israeli: awọn olori mi kì yio si ni awọn enia mi lara mọ́; ati ilẹ iyokù ni nwọn o fi fun ile Israeli gẹgẹ bi ẹyà wọn.

9 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ki o to fun nyin, ẹnyin olori Israeli: ẹ mu ìwa ipa irẹ́jẹ kuro, ki ẹ si mu idajọ ati ododo ṣẹ, mu ilọ́nilọwọgbà nyin kuro lọdọ awọn enia mi, ni Oluwa Ọlọrun wi.

10 Ki ẹnyin ki o ni ìwọn títọ, ati efà títọ, ati bati títọ.

11 Efa ati bati yio jẹ ìwọn kanna, ki bati ba le gbà ìdamẹwa homeri, ati efa idamẹwa homeri: iwọ̀n rẹ̀ yio jẹ gẹgẹ bi ti homeri.

12 Ṣekeli yio si jẹ́ ogún gera: ogún ṣekeli, ṣekeli mẹdọgbọ̀n, ṣekeli mẹdogun, ni manẹ nyin yio jẹ.

13 Eyi ni ọrẹ ti ẹ o rú; idamẹfa efa homeri alikama kan, ẹ o si mu idamẹfa efa homeri barle kan wá.

14 Niti aṣẹ oróro, bati oróro, idamẹwa bati kan, lati inu kori wá, ti o jẹ homeri onibati mẹwa; nitori bati mẹwa ni homeri kan:

15 Ati ọdọ-agutan kan lati inu agbo, lati inu igba, lati inu pápa tutù Israeli; fun ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati fun ọrẹ ẹbọ sisun, fun ọrẹ ẹbọ idupẹ, lati fi ṣe ètutu fun wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.

16 Gbogbo enia ilẹ na ni yio mu ẹbọ yi wá fun olori ni Israeli.

17 Ti ọmọ-alade yio jẹ́ ọrẹ ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ mimu, ninu asè gbogbo, ati ni oṣù titun, ati ni awọn ọjọ isimi, ni gbogbo ajọ ile Israeli: on o pèse ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ idupẹ, lati ṣe etùtu fun ile Israeli.

18 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; li oṣù ekini, li ọjọ ekini oṣù, iwọ o mu ẹgbọ̀rọ akọ malu alailabawọn, iwọ o si fi sọ ibi mimọ́ di mimọ́:

19 Alufa yio si mu ninu ẹjẹ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, yio si fi si opó ile, ati si igun mẹrẹrin ijoko pẹpẹ, ati si opó ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu ile.

20 Bayi ni iwọ o si ṣe li ọjọ keje oṣù fun olukuluku ẹniti o ṣina, ati fun òpe: ẹ o si ṣe etùtu ilẹ na.

21 Li oṣù ekini, li ọjọ ẹkẹrinla oṣù, ẹnyin o ni irekọja, asè ọjọ meje: akara aiwú ni jijẹ.

22 Ati li ọjọ na ni ọmọ-alade yio pèse ẹgbọ̀rọ akọ malu fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ara rẹ̀ ati fun gbogbo enia ilẹ na.

23 Ati ọjọ meje àse na ni yio pèse ọrẹ ẹbọ sisun fun Oluwa, ẹgbọ̀rọ akọ malu meje ati àgbo meje alailabawọ́n lojojumọ fun ọjọ meje na; ati ọmọ ewurẹ kan lojojumọ fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ.

24 Yio si pèse ọrẹ ẹbọ jijẹ ti efa kan fun ẹgbọ̀rọ akọ malu kan, ati efa kan fun àgbo kan, ati hini ororo kan fun efa kan.

25 Li oṣù keje, li ọjọ kẹ̃dogun oṣù, ni yio ṣe gẹgẹ bi wọnyi ni àse ọjọ meje, gẹgẹ bi ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, gẹgẹ bi ọrẹ ẹbọ sisun, ati gẹgẹ bi ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati gẹgẹ bi oróro.