Esek 24 YCE

1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, li ọdun kẹsan, li oṣu kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣu, wipe,

2 Ọmọ enia, iwọ kọ orukọ ọjọ na, ani ọjọ kanna yi: ọba Babiloni doju kọ Jerusalemu li ọjọ kanna yi:

3 Si pa owe si ọlọtẹ ilẹ na, si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Gbe ìkoko ka iná, gbe e kà a, si dà omi sinu rẹ̀ pẹlu:

4 Kó aján na jọ sinu rẹ̀, olukuluku aján ti o tobi, itan, ati apá, fi egungun ti o jọju kún inu rẹ̀.

5 Mu ninu agbo-ẹran ti o jọju, ko awọn egungun sabẹ rẹ̀, si jẹ ki o hó dãdã, si jẹ ki nwọn bọ̀ egungun rẹ̀ ninu rẹ̀.

6 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Egbé ni fun ilu ẹlẹjẹ na, fun ìkoko ti ifõfo rẹ̀ wà ninu rẹ̀, ti ifõfo rẹ̀ kò dá loju rẹ̀: mu u jade li aján li aján; máṣe dìbo nitori rẹ̀.

7 Nitori ẹjẹ rẹ̀ wà lãrin rẹ̀, o gbé e kà ori apata kan, kò tú u dà sori ilẹ, lati fi erupẹ bò o.

8 Ki o ba lè jẹ ki irúnu ki o de, lati gbẹsan; mo ti gbe ẹjẹ rẹ̀ kà ori apata kan, ki a má ba le bò o.

9 Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Egbe ni fun ilu ẹlẹjẹ na! Emi o tilẹ jẹ ki òkiti iná na tobi.

10 Ko igi jọ si i, ko iná jọ, jo ẹran na, fi turari dùn u; si jẹ ki egungun na jona.

11 Si gbe e kà ori ẹyín iná na lasan, ki idẹ rẹ̀ le gbona, ki o le pọ́n, ati ki ẽri rẹ̀ le di yiyọ́ ninu rẹ̀, ki ifõfo rẹ̀ le run.

12 On ti fi eke dá ara rẹ̀ lagara, ifõfo nla rẹ̀ kò si jade kuro lara rẹ̀ ifõfo rẹ̀ yio wà ninu iná.

13 Ninu ẽri rẹ̀ ni iwà ifẹkufẹ wà: nitori mo ti wẹ̀ ọ, iwọ kò si mọ́, a kì yio si tun wẹ̀ ọ kuro ninu ẽri rẹ mọ, titi emi o fi jẹ ki irúnu mi ba le ọ lori.

14 Emi Oluwa li o ti sọ ọ, yio si ṣẹ, emi o si ṣe e: emi kì yio pada sẹhìn, bẹ̃ni emi kì yio dasi, bẹ̃ni emi kì yio ronupiwada; gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, ati gẹgẹ bi iṣe rẹ ni nwọn o da ọ lẹjọ, li Oluwa Ọlọrun wi.

15 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

16 Ọmọ enia, kiye si i, mo mu ifẹ oju rẹ kuro lọdọ rẹ, nipa lilù kan: ṣugbọn iwọ kò gbọdọ gbãwẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọkun, bẹ̃ni omije rẹ kò gbọdọ ṣan silẹ.

17 Máṣe sọkun, máṣe gbãwẹ fun okú, wé lawàni sori rẹ, si bọ̀ bata rẹ si ẹsẹ rẹ, máṣe bò ète rẹ, máṣe jẹ onjẹ enia.

18 Bẹ̃ni mo sọ fun awọn enia li owurọ: li aṣálẹ obinrin mi si kú, mo si ṣe li owurọ bi a ti pá a li aṣẹ fun mi.

19 Awọn enia si sọ fun mi wipe, Iwọ kì yio ha sọ fun wa ohun ti nkan wọnyi jasi fun wa, ti iwọ ṣe bayi?

20 Mo si da wọn lohùn pe, Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,

21 Sọ fun ile Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, kiyesi i emi o sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, titayọ agbara nyin, ifẹ oju nyin, ikãnu ọkàn nyin, ati ọmọ nyin ọkunrin ati ọmọ nyin obinrin, ti ẹnyin ti fi silẹ, yio ti ipa idà ṣubu.

22 Ẹnyin o si ṣe bi emi ti ṣe: ẹnyin kò ni bò ète nyin, bẹ̃ni ẹ kò ni jẹ onjẹ enia.

23 Lawani nyin yio si wà li ori nyin, ati bàta nyin li ẹsẹ nyin: ẹnyin kò ni gbãwẹ, bẹ̃ni ẹ kò ni sọkun: ṣugbọn ẹnyin o ma joro nitori aiṣedẽde nyin, ẹ o si ma ṣọ̀fọ ẹnikan si ẹnikeji.

24 Bayi ni Esekieli jẹ àmi fun nyin: gẹgẹ bi gbogbo ohun ti o ṣe, li ẹ o si ṣe nigbati eyi bá si de, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun:

25 Pẹlupẹlu, iwọ ọmọ enia, kì yio ha ṣe pe, ni ijọ na nigbati mo ba gbà agbara wọn, ayọ̀ ogo wọn, ifẹ oju wọn, ati eyiti nwọn gbe ọkàn wọn le, ọmọ wọn ọkunrin, ati ọmọ wọn obinrin, kuro lọdọ wọn,

26 Ti ẹniti ti o ba sálà nijọ na, yio tọ̀ ọ wá, lati jẹ ki iwọ ki o fi eti ara rẹ gbọ́?

27 Li ọjọ na li ẹnu rẹ yio ṣi si ẹni ti o sala, iwọ o si sọ̀rọ, iwọ kì yio si yadi mọ: iwọ o si jẹ àmi fun wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.