Esek 7 YCE

Òpin ti dé Tán fún Israẹli

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

2 Iwọ ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi pẹlu si ile Israeli; Opin, opin de sori igun mẹrẹrin ilẹ.

3 Opin de si ọ wayi, emi o si rán ibinu mi sori rẹ, emi o si da ọ lẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ; emi o si san gbogbo irira rẹ pada si ọ lori.

4 Oju mi kì yio si dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: ṣugbọn emi o san ọ̀na rẹ pada si ọ lori, ati irira rẹ yio wà li ãrin rẹ: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.

5 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; ibi kan, ibi kanṣoṣo, kiye si i, o de.

6 Opin de, opin de: o jí si ọ; kiye si i, o de.

7 Ilẹ mọ́ ọ, iwọ ẹniti ngbe ilẹ na: akokò na de, ọjọ wahala sunmọ tosí; kì isi ṣe ariwo awọn oke-nla.

8 Nisisiyi li emi o dà ikannu mi si ọ lori, emi o si mu ibinu mi ṣẹ si ọ lori: emi o si dá ọ lẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, emi o si san fun ọ nitori gbogbo irira rẹ.

9 Oju mi kì yio si dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: emi o si san fun ọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, ati irira rẹ ti mbẹ lãrin rẹ; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa ti nkọlu.

10 Kiye si i ọjọ na, kiyesi i, o de: ilẹ ti mọ́; ọpá ti tanná, irera ti rudi.

11 Iwa-ipa ti dide di ọpa ìwa buburu: ọkan ninu wọn kì yio kù, tabi ninu ọ̀pọlọpọ wọn, tabi ninu ohun kan wọn, bẹ̃ni kì yio si ipohùnreré ẹkun fun wọn.

12 Akoko na de, ọjọ na sunmọ itosi: ki olùra máṣe yọ̀, bẹ̃ni ki olùta máṣe gbãwẹ: nitori ibinu de ba gbogbo wọn.

13 Nitori olùta kì yio pada si eyi ti a tà, bi wọn tilẹ wà lãye: nitori iran na kàn gbogbo enia ibẹ̀, ti kì yio pada; bẹ̃ni kò si ẹniti yio mu ara rẹ̀ le ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

14 Nwọn ti fọn ipè, lati jẹ ki gbogbo wọn mura; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o lọ si ogun: nitori ibinu mi wà lori gbogbo wọn.

15 Idà mbẹ lode, ajakálẹ àrun ati iyàn si mbẹ ninu: ẹniti o wà li oko yio kú nipa idà; ẹniti o wà ninu ilu, iyàn ati ajakálẹ àrun ni yio si jẹ ẹ run.

16 Ṣugbọn awọn ti o bọ́ ninu wọn yio salà, nwọn o si wà lori oke bi adabà afonifoji, gbogbo nwọn o ma gbãwẹ, olukuluku nitori aiṣedede rẹ̀.

17 Gbogbo ọwọ́ ni yio rọ, gbogbo ẽkun ni yio si di ailera bi omi.

18 Aṣọ ọ̀fọ ni nwọn o fi gbajá pẹlu; ìbẹru ikú yio si bò wọn mọlẹ; itiju yio si wà loju gbogbo wọn, ẽpá yio si wà li ori gbogbo wọn.

19 Nwọn o sọ fadaka wọn si igboro, wura wọn li a o si mu kuro; fadaka wọn ati wura wọn kì yio si le gbà wọn là li ọjọ ibinu Oluwa: nwọn kì yio tẹ́ ọkàn wọn lọrùn, bẹ̃ni nwọn kì yio kún inu wọn; nitori on ni idùgbolu aiṣedede wọn.

20 Bi o ṣe ti ẹwà ohun ọṣọ́ rẹ̀ ni, o gbe e ka ibi ọlanla: ṣugbọn nwọn yá ere irira wọn ati ohun ikorira wọn ninu rẹ̀: nitorina li emi ṣe mu u jina si wọn.

21 Emi o si fi i si ọwọ́ awọn alejo fun ijẹ, ati fun enia buburu aiye fun ikogun: nwọn o si bà a jẹ.

22 Oju mi pẹlu li emi o yipada kuro lọdọ wọn, nwọn o si ba ibi ikọkọ mi jẹ; nitori awọn ọlọṣà yio wọ inu rẹ̀, nwọn o si bà a jẹ.

23 Rọ ẹ̀wọn kan; nitori ilẹ na kún fun ẹ̀ṣẹ ẹjẹ, ilu-nla na si kún fun iwa ipa.

24 Nitorina li emi o mu awọn keferi ti o burujulọ, nwọn o si jogun ile wọn: emi o si mu ọṣọ-nla awọn alagbara tán pẹlu, ibi mimọ́ wọn li a o si bajẹ.

25 Iparun mbọ̀ wá, nwọn o si wá alafia, kì yio si si.

26 Tulasì yio gori tulasi, irọkẹ̀kẹ yio si gori irọkẹ̀kẹ; nigbana ni nwọn o bere lọdọ woli; ṣugbọn ofin yio ṣegbé kuro lọdọ alufa, ati imọ̀ kuro lọdọ awọn agbà.

27 Ọba yio ṣọ̀fọ, a o si fi idahoro wọ̀ ọmọ-alade, ọwọ́ awọn enia ilẹ na li a o wahala, emi o ṣe si wọn gẹgẹ bi ọ̀na wọn, ati gẹgẹ bi ẹjọ wọn ti ri li emi o dá a fun wọn: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.