Esek 44 YCE

1 O si mu mi pada lọna ẹnu-ọ̀na ibi mimọ́ ti ode ti o kọju si ila-õrun; o si tì.

2 Oluwa si wi fun mi pe; Ẹnu-ọ̀na yi yio wà ni titì, a kì yio ṣi i, ẹnikan kì yio si gbà a wọ inu rẹ̀; nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti gbà a wọ inu rẹ̀, yio si wà ni titì.

3 Fun ọmọ-alade ni; ọmọ-alade, on ni yio joko ninu rẹ̀ lati jẹ akara niwaju Oluwa; yio wọ̀ ọ lati ọ̀na iloro ẹnu-ọ̀na na, yio si jade lati ọ̀na rẹ̀ na lọ.

4 O si mu mi wá ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa siwaju ile na; mo si wò, si kiyesi i, ogo Oluwa kun ile Oluwa: mo si doju mi bolẹ.

5 Oluwa si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi iyè rẹ si i, si fi oju rẹ wò, si fi eti rẹ gbọ́ ohun gbogbo ti emi ti sọ fun ọ niti gbogbo aṣẹ ile Oluwa, ati ti gbogbo ofin rẹ̀; si fi iyè rẹ si iwọ̀nu ile nì, pẹlu gbogbo ijadelọ ibi-mimọ́ na.

6 Iwọ o si wi fun awọn ọlọ̀tẹ, ani fun ile Israeli, pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; ki gbogbo ohun-irira nyin to fun nyin, ile Israeli,

7 Niti pe ẹ mu ọmọ-ajèji, alaikọla aiya, ati alaikọla ara wa, lati wà ni ibi-mimọ́ mi, lati sọ ọ di alailọ̀wọ, ani ile mi, nigbati ẹ rú akara mi, ọ̀ra ati ẹjẹ, nwọn si bà majẹmu mi jẹ nipa gbogbo ohun-irira nyin.

8 Ẹ kò si pa ibi-iṣọ́ ohun-mimọ́ mi mọ́: ṣugbọn ẹ ti yàn oluṣọ́ ibi-iṣọ́ inu ibi-mimọ́ mi fun ara nyin.

9 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Gbogbo ọmọ àjeji, alaikọla aiya, tabi alaikọla ara kì yio wọ̀ inu ibi mimọ́ mi, ninu gbogbo ọmọ àjeji ti o wà lãrin awọn ọmọ Israeli.

10 Ṣugbọn awọn Lefi ti o ti lọ jina kuro lọdọ mi, ni ìṣina Israeli, ti nwọn ṣìna kuro lọdọ mi lẹhin oriṣa wọn: yio si rù aiṣedede wọn.

11 Nwọn o si jẹ iranṣẹ ni ibi mimọ́ mi, oluṣọ́ ẹnu-ọ̀na ile, nwọn o si ma ṣe iranṣẹ ni ile: awọn ni yio pa ọrẹ-ẹbọ sisun ati ẹbọ fun awọn enia, nwọn o si duro niwaju wọn lati ṣe iranṣẹ fun wọn.

12 Nitori ti nwọn ṣe iranṣẹ fun wọn niwaju òriṣa wọn, nwọn si jẹ ohun ìdugbolu aiṣedede fun ile Israeli: nitorina ni mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi, nwọn o si rù aiṣedede wọn.

13 Nwọn kì yio si sunmọ ọdọ mi, lati ṣiṣẹ alufa fun mi, tabi lati sunmọ gbogbo ohun-mimọ́ mi, ni ibi mimọ́ julọ: nwọn o si rù itijú wọn, ati ohun-irira wọn ti nwọn ti ṣe.

14 Emi o si ṣe wọn ni oluṣọ́ ibi-iṣọ́ ile, fun gbogbo iṣẹ rẹ̀, ati fun ohun gbogbo ti a o ṣe ninu rẹ̀.

15 Ṣugbọn awọn alufa awọn Lefi, awọn ọmọ Sadoku, ti o pa ibi-iṣọ ibi mimọ́ mi mọ, nigbati awọn ọmọ Israeli ṣìna kuro lọdọ mi, awọn ni yio sunmọ ọdọ mi lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si duro niwaju mi lati rú ọrá ati ẹjẹ si mi, ni Oluwa Ọlọrun wi:

16 Awọn ni yio wá si ibi-mimọ́ mi, awọn ni o si sunmọ tabili mi, lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si pa ibi-iṣọ́ mi mọ́.

17 Yio si ṣe pe, nigbati nwọn ba wá si ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, nwọn o wọ̀ ẹ̀wu ọ̀gbọ; irun agutan kì yio bọ́ si ara wọn, nigbati nwọn ba nṣe iranṣẹ ni ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, ati ninu ile.

18 Nwọn o si ni filà ọ̀gbọ li ori wọn, ṣòkoto ọ̀gbọ ni nwọn o si wọ̀ ni idí wọn; nwọn kì o si fi ohun ti imuni lãgùn dì amurè.

19 Nigbati nwọn ba si lọ si agbalá ode, ani si agbalá ode sọdọ awọn enia, nwọn o bọ́ ẹ̀wu wọn ti wọn ifi ṣe iranṣẹ, nwọn o si fi wọn si awọn yará mimọ́, nwọn o si wọ̀ ẹ̀wu miran; nwọn kì yio si fi ẹ̀wu wọn sọ awọn enia di mimọ́.

20 Nwọn kì o si fá ori wọn, bẹ̃ni nwọn kì yio jẹ ki irun wọn gbọ̀; ni rirẹ nwọn o rẹ irun ori wọn.

21 Alufa gbogbo kì yio mu ọti-waini, nigbati nwọn ba wá si agbalá ti inu.

22 Nwọn kì yio si fẹ́ opo, tabi ẹniti a tì jade fun aya wọn: ṣugbọn nwọn o fẹ́ wundia lati iru-ọmọ ile Israeli, tabi opo ti o ti ni alufa ri.

23 Nwọn o si kọ́ awọn enia mi ni iyàtọ ti o wà lãrin mimọ́ ati ailọ̀wọ, nwọn o si mu wọn mọ̀ eyiti o wà lãrin aimọ́ ati mimọ́.

24 Ati ni ija, awọn ni yio duro lati ṣe idajọ; nwọn o si dá a ni idajọ mi: nwọn o si pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́ ni gbogbo apejọ mi; nwọn o si yà awọn ọjọ isimi mi si mimọ́.

25 Nwọn kì yio si wá sọdọ okú enia lati sọ ara wọn di aimọ́, ṣugbọn fun baba, tabi fun iya, tabi fun ọmọkunrin, tabi fun ọmọbinrin, fun arakunrin, tabi fun arabinrin ti kò ti ni ọkọ, nwọn le sọ ara wọn di aimọ́.

26 Ati lẹhin iwẹnumọ́ rẹ̀, nwọn o si ká ọjọ meje fun u.

27 Ati li ọjọ ti yio lọ si ibi-mimọ́, si agbalá ti inu, lati ṣe iranṣẹ ni ibi-mimọ́, on o rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ni Oluwa Ọlọrun wi.

28 Ati ogún ni yio jẹ fun wọn: emi ni ogún wọn: ẹ kì yio si fun wọn ni ini ni Israeli: emi ni ini wọn.

29 Awọn ni yio jẹ ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; ati gbogbo ohun-egún ni Israeli, yio jẹ́ ti wọn.

30 Ati ikini ninu gbogbo akọ́so nkan gbogbo, olukuluku ọrẹ gbogbo, ninu gbogbo ọrẹ nyin, yio jẹ ti awọn alufa: ẹ o si fi akọ́po iyẹfun nyin fun alufa, ki ibukun le bà le ile rẹ.

31 Gbogbo okú nkan, ati ohun ti a fà ya ninu ẹiyẹ tabi ninu ẹranko, ni awọn alufa kì yio jẹ.